20/20: A Ti Rí. A Ti Yàn. A Ti Rán. Nípasẹ̀ Christine Caine Àpẹrẹ

20/20: Seen. Chosen. Sent. By Christine Caine

Ọjọ́ 2 nínú 7

ỌLỌ́RUN TI YÀN Ọ́

“Olùbùkún ni Ọlọ́run àti Baba Jésù Krístì Olúwa wa, ẹnití Ó ti fi gbogbo ìbùkún ẹ̀mí nínú àwọn ọ̀run bùkún wa nínú Krístì. Àní gẹ́gẹ́bí ó ti yàn wá nínú Rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, kí àwa kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú Rẹ̀ nínú ìfẹ́. Ẹnití Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jésù Krístì fún ara Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú ìfẹ́ Rẹ̀, fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀, èyítí Ó dà lù wá nínú Ayanfẹ nì.” -Éfésù 1:3-6 YBCV

“Kristínìì?” Ìyá mi bèèrè. “Bí ó ti jẹ́ pé òtítọ́ ni à ń sọ lọ́wọ́ báyìí, ṣé o fẹ́ mọ gbogbo òtítọ́?”

Mo jẹ́ ọmọ ọdún 33 nígbà náà, mo sì mọ̀ pé bí ìyá mi ṣe bèèrè ìbéèrè yẹn túmọ̀sí ohun kan ṣoṣo.

Mò ti sáré lọ sí ilé wọn kí n lè dásí ohun tí mo mọ̀ pé kò lè jẹ́ òtítọ́. Arákùnrin mi, Jọ́ọ̀jì, gba lẹ́tà kan tó sọ pé a gbà a tọ́ ni. Mo rìn dé ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ìyá mi gẹ́lẹ́ bí Jọ́ọ̀jì ṣe ń fì lẹ́tà náà lé wọn lọ́wọ̀.

Mi ò ní gbàgbé láí bí ọwọ́ wọn ṣe bẹ̀rẹ̀ síí gbọ̀n. Ìbẹ̀rù bo ojú wọn. Ọ̀rọ̀ sálọ lórí ahọ́n wọn. Omijé sì bẹ̀rẹ̀síí dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú gbogbo wa.

Nígbàtí ohùn ìyá mi yíó là, mò ń gbọ́ bí ọkàn wọn ṣe gb'ọgbẹ́ tó. “Mo túúbá pé báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe hàn sí ọ Jọ́ọ̀jì. A kò níi l'ọ́kàn láti bà ọ́ l'ọ́kàn jẹ́. Bàbá rẹ fẹ́ràn rẹ. Èmi náà fẹ́ràn rẹ. Mi ò lè fẹ́ràn rẹ ju báyìí lọ gan an bó jẹ́ pé èmi gan an ni mo bí ọ fúnraà mi.”

Mo rántí pé mo k'ọrí sí ilé-ìdáná, tí mo sì kún orí tábìlì pẹ́lú oùnjẹ, nítorípé ọ̀nà kan tí àwọn ẹbí Gírìkì ńgbà láti yanjú gbogbo wàhálá ni kí: á jẹun.

Ìgbà tí mo na'wọ́ gàn baklava ni ìyá mi bèèrè ìbéèrè atúniláṣìrí yẹn, lẹ́nu kan ṣáá, mo mọ̀. Mo kàn mọ̀ náà ni. Mo ń wò wọ́n lójú fún ìdáhùn, mo sì ń dàníyàn pé kí ìdàhùn náà kó má jẹ́ ohun tí mo ní lérò, mo rí ara mi tí mò ń bá wọ́n dáhùn pé: 'ṣe lẹ gba èmí náà tọ́.”

Lẹ́hìn ìṣéjú díẹ̀, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ tó dára jùlọ fún mi. Ọ̀rọ̀ tó mú ìwòsàn wá. Wọ́n tún tún un sọ fún mi ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀lé e…

“Mo fẹ́ràn rẹ kí n tóó mọ̀ ọ́ rárá.”

Títí di òní, mo káràmásìkí ọ̀rọ̀ yẹn. Wọ́n dúró fún ọkàn ìyá tó jẹ́ kí n mọ̀ pé wọ́n ti ń pòǹgbẹ fún mi, ṣàfẹ́rí mi, àti yàn mí, kódà kí wọ́n tóó f'ojú kàn mi rárá.

Bí mo bá ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mi ò le ṣe kí n má gbọ́ ọkàn Bàbá mi l'ọ́run, Ẹni tó fi ìgbà gbogbo fẹ́ mí bákannáà. Ẹni tó ti kọ́ yàn mí tipẹ́ kí ìyá mi tóó ṣe bẹ́ẹ̀.

Ẹnikan náà tó yàn ọ́.

ÀDÚRÀ

Ọlọ́run, O ṣeun nítorípé O yàn mí ní ọmọbìrin Rẹ, àti bíi ẹni tí yíó gbé ọmọkùrin Rẹ, Jésù, wá sínú ayé mi. Mo gbàdúrà pé kí O fún mi ní okun àti ìgboyà làti má rí àwọn ẹlòmíràn bí O ṣe rí wọn nìkan, ṣùgbọ́n kí ń gbé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ̀, kí n sì kàn sí wọn pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ. Láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé O yàn wọn. Àmín.

Àdàkọ láti inú 20/20: Seen.Chosen.Sent láti ọwọ́ Christine Caine. Copyright © 2019 by Christine Caine. Àtúntẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Lifeway Women. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni tiwa.

Day 1Day 3

Nípa Ìpèsè yìí

20/20: Seen. Chosen. Sent. By Christine Caine

Ǹjẹ́ o le fi ojú inú wòó bí yíò ṣe rí kí Ọlọ́run rí ọ lọ́nà tí ó jẹ́ wípé ìwo gan ò lè má ṣe aláìrì àwọn ẹlòmíràn? Ṣé o le fi ojú inú wòó wípé lójoojúmọ́, kí ìgbésí ayé rẹ̀ máa ní ipa tí ó ṣe pàtàkì nípa ìyè ayérayé? Ìfọkànsí ọlọ́jọ́ méje yìí, tí a kọ láti ọwọ́ Christine Caine yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Ọlọ́run ṣe rí o, tí ó yàn ọ́, àti bí Ó ṣe rán ọ láti rí àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wón le rí ara wọn bí Ọlọ́run ṣe rí wọn- pẹ̀lú ìríran 20/20.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christine Caine - A21, Propel, CCM fún ìpèsè ètò yìí. Tó bá fẹ́ mọ̀ sí, lọ sí http://www.christinecaine.com/2020study