20/20: A Ti Rí. A Ti Yàn. A Ti Rán. Nípasẹ̀ Christine Caine Àpẹrẹ

ÌWỌ́ JẸ́ IYỌ̀ ÀTI ÌMÓLẸ̀
Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. Matiu 5:13-15
Mo jẹ́ ọmọ ilé-ìwé gíga nígbàtí mo pàdé Ọ̀rẹ́ kan tó hàn pé ó ní ohun gbogbo — ẹwà, ipò, àwọn àṣeyọrí, ọrọ̀. Gbogbo ohun tí mo rò pé èmí kò ní. Síbẹ̀, a túbọ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Nítorínáà, nígbàtí mi ò ríi fún ọjọ́ mẹ́ta tí kò sì dáhùn àwọn ìpè mi, ẹ̀rú bà mí. Nígbà tí ó dé ní ọjọ́ kẹta, mo gbọ́ pé ó ti wà níbi àríyá kan níbi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wà níbẹ̀ ti lo oògùn olóró láti wà lójúfò. Ó sọ pé, “Ìfẹ́ wà púpọ̀. Ayọ̀ pọ́ púpọ̀. Àlàáfíà pọ̀ débi pé ó jẹ́ ìyàlẹ́nu.” Nígbànáà, ó fa òdòdó kékeré kan jáde. “Mo n'ífẹ́ rẹ púpọ̀, Chris, tí èmi kò fẹ́ kí o pàdánù ìrírí tí mo ní, nítorínáà mo mú ìdajì tábúlẹ́tì oògùn wá fún ọ”
Mo fi inú rere kọ ìpèsè rẹ, sùgbọ́n ó kan mí lômi nú. Mo ti fi ayé mi fún Jésù ní kikùn, ní ọdún méjì sẹ́yìn, mo wá ròó Ọmọbìnrin yìí n'ífẹ́ rẹ púpọ̀, kò fẹ́ kí o pàdánù ìfẹ́ àti ayọ̀ àti àlàáfíà tí oògùn fún un. Ìwọ, Christine, ní Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run ti ńgbé inú rẹ, ẹnití ó jẹ́ orisun ìfẹ́ àti ayọ̀ àti àlàáfíà. Christine, ojú ntì ọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, nítorí o rò pé kò nílò rẹ̀, nígbà tí ó jẹ́ wípé ohùn kan tí ó nílò jù lọ ni Ọlọ́run.
Lẹ́yìn náà, mo sunkún. Mo ṣe ìlérí fún Ọlọ́run èmi kì yóò jẹ́ kí ìfẹ́ enikéni nípa ohunkóhun — òògùn, owó, àṣeyọrí tàbí pàápàá ìdí kan — jẹ́ ìtara ju ìfẹ́ mi fún u àti ìfẹ́ mi láti lọ sọ fún àwọn ènìyàn nípa ẹni tí ó jẹ́.
Kí nìdí tó fàá tí ó fi rọrùn fún wa láti wo àwọn èèyàn tí ìgbésí ayé wọn dàrú bí ìgbàtí àwọn ni wọ́n nílò láti rí Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n kùnà láti mọ̀ pé àwọn tó dà bíi pé wọ́n ní gbogbo rẹ̀ pàápàá ti pàdánù pẹ̀lú? Ṣe Ọlọ́run kò fẹ́ kí á lóyè pé àwon ènìyàn tí ó sọnù dàbí gbogbo ènìyàn bí?
Láti ọjọ́ náà, èmi kò gbàgbé rárá pé àyé tí ó nílò ìrísí Ọlọ́run wà nínú gbogbo ọkàn ènìyàn tí Jésù nìkan le kún, àti pé gbogbo ènìyàn nílò láti gbọ́ nípa rẹ̀.
ÀDÚRÀ
Ọlọ́run, ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀ níbi gbogbo tí mó ńlọ́, sí gbogbo ènìyàn tí mo bá pàdé. Ràn mí lọ́wọ́ láti wò àti láti ríi…àwọn oníbìnújẹ́ ọkàn àti àwọn tí ó sọnù… láìbìkítà bí wọ́n ṣe rí. Ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìtara àánú àti ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ àti fa ẹnìkan súnmọ́ lónì. Ní orúkọ Jésù, mo gbàdúrà, àmín.
Ayọọ́ láti20/20: Seen.Chosen.Sent láti ọwọ́ Christine Caine. Àṣẹ-lórí-ara © 2019 láti ọwọ́ Christine Caine. Tún un tẹ̀ jáde pẹ̀lú ìgbaniláàyè ti Lifeway Women. Gbogbo àwọn ètò wà ní ìpamọ́.
Nípa Ìpèsè yìí

Ǹjẹ́ o le fi ojú inú wòó bí yíò ṣe rí kí Ọlọ́run rí ọ lọ́nà tí ó jẹ́ wípé ìwo gan ò lè má ṣe aláìrì àwọn ẹlòmíràn? Ṣé o le fi ojú inú wòó wípé lójoojúmọ́, kí ìgbésí ayé rẹ̀ máa ní ipa tí ó ṣe pàtàkì nípa ìyè ayérayé? Ìfọkànsí ọlọ́jọ́ méje yìí, tí a kọ láti ọwọ́ Christine Caine yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Ọlọ́run ṣe rí o, tí ó yàn ọ́, àti bí Ó ṣe rán ọ láti rí àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wón le rí ara wọn bí Ọlọ́run ṣe rí wọn- pẹ̀lú ìríran 20/20.
More