20/20: A Ti Rí. A Ti Yàn. A Ti Rán. Nípasẹ̀ Christine Caine Àpẹrẹ

20/20: Seen. Chosen. Sent. By Christine Caine

Ọjọ́ 5 nínú 7

Ẹ JẸ́ KÍ Á NÍFÈ̩Ẹ́ ÀWỌN ỌMỌNÌKEJÌ WA

Nígbà náà ni amòfin àgbà kan dìde láti dán an [Jésù] wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?” Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.” Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?” -Luku 10:25-29 YCE

Ìtàn ará Samáríà Rere náà jẹ́ àkàwé kan tí Jésù sọ nípa ọkùnrin kan tí ó wà ní ibi tí kò tọ́ ní àkókò tí kò tọ́, tí àwọn ọlọ́ṣà ṣe léṣe tí wọ́n sì gbé jù sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run.

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ti lọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti èkejì tí ó dé bá ọkùnrin náà jẹ́ àwọn onísìn—àlùfáà Júù kan àti ọmọ Léfì—tí wọ́n mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ní ipò ọlá àti àṣẹ nínú sínágọ́gù. Àwọn méjèèjì kọjá rẹ̀. Ọkùnrin kẹta, tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ọmọ ìlú Samáríà, ní àánú rẹ̀ ṣe. Ó lọ bá a.  

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ló jẹ́ pé wọ́n wà lójú ọ̀nà ìrìn àjò sí ibòmíràn, ṣùgbọ́n ọ̀kan ṣoṣo ló ṣetán láti pa ètò t'ara tirẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ kan ná. Ẹnìkan ṣoṣo yìí ló fi àkókò àti ọrọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ó jẹ́ ará Samáríà—ọkùnrin kan láti ẹ̀yà àti àṣà àwọn ènìyàn tí àwọn Júù kẹ́gàn. Ọkùnrin yìí nífẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́, nípa èyí ó fọ́ gbogbo agbára ìdènà ẹ̀tanú àti ìyàsọ́tọ̀. Ó fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. 

Lẹ́yìn tí Jésù sọ ìtàn yìí, ó fúnni ní ìtọ́ni pé:“Lọ, kí o sì ṣe bákan náà” (Luku 10:37).

Nígbà tí mo kọ́kọ́ ní òye nípa fífi èèyàn ṣòwò, Ọlọ́run lo ìtàn yìí láti darí mi sí ọjọ́ ọ̀la mi. Ó tẹnu mọ́ kókó kan fún mi: “Ó kọjá lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀” (Luku 10:34).

Mo jẹ́ obìnrin tí ọwọ́ re dí, ìyàwó, ìyá ọmọ méjì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan láti ṣe, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fẹ́ dá ìgbésí ayé àti ètò mi dúró fún ète rẹ̀. Ọlọ́run fẹ́ kí n sọdá ojú ọ̀nà fún àwọn ènìyàn tí n kò rí rí tí n kò sì mọ̀ rí. Ó fẹ́ kí n lọ ṣàwárí àwọn ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé tí wọ́n sọnù sínú oko ẹrú òde òní. 

Tani ọmọnìkejì rẹ?

Ní tèmi, àwọn t'ó lùgbàdì fífi ọmọ ènìyàn ṣòwò ni ọmọnìkejì mi. Ọmọnìkejì mi ni àwọn tí mò ń bá pàdé ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ọmọnìkejì mi ni obìnrin t'ó ń gbé níwájú ilé mi. Ọmọnìkejì mi ni aláìrílégbé tí mo ń bá pàdé. Ẹnikẹ́ni t'ó nílò nnkan kan tí mo ní tí mo sì lè fún un ni ọmọnìkejì mi.

Tí a bá fẹ ní ipa ní gbogbo àgbáyé, a ní láti rí gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọmọnìkejì wa. Olúkúlùkù ènìyàn l'ó yẹ ká nífẹẹ́ láìká ìgbàgbọ, ìṣe tàbí ìwà wọn si, nítórí pé Ọlọ́run rí wọn bí ẹni tí ó yẹ fún ìfẹ́ àti ìràpadà nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ́. 

ÀDÚRÀ

Ọlọ́run, mo yàn láti sọdá ní òpópónà láti lọ ran ọmọnìkejì mi lọ́wọ́, láti fẹ wọn bí mo ti fẹ́ràn ara mi. O ṣeun fún dídarí mi nígbà gbogbo, àti rírànlọwọ mí láti máa rántí pé, Ọwọ́ mi kò dí jù fún wọn. Ní orúkọ Jésù ni mo gbàdúrà, àmín.

Adapted from 20/20: Seen.Chosen.Sent by Christine Caine. Copyright © 2019 by Christine Caine. Reprinted with permission of Lifeway Women. All rights reserved.

Day 4Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

20/20: Seen. Chosen. Sent. By Christine Caine

Ǹjẹ́ o le fi ojú inú wòó bí yíò ṣe rí kí Ọlọ́run rí ọ lọ́nà tí ó jẹ́ wípé ìwo gan ò lè má ṣe aláìrì àwọn ẹlòmíràn? Ṣé o le fi ojú inú wòó wípé lójoojúmọ́, kí ìgbésí ayé rẹ̀ máa ní ipa tí ó ṣe pàtàkì nípa ìyè ayérayé? Ìfọkànsí ọlọ́jọ́ méje yìí, tí a kọ láti ọwọ́ Christine Caine yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Ọlọ́run ṣe rí o, tí ó yàn ọ́, àti bí Ó ṣe rán ọ láti rí àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wón le rí ara wọn bí Ọlọ́run ṣe rí wọn- pẹ̀lú ìríran 20/20.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Christine Caine - A21, Propel, CCM fún ìpèsè ètò yìí. Tó bá fẹ́ mọ̀ sí, lọ sí http://www.christinecaine.com/2020study