ẼKÀN kan yio si jade lati inu kùkute Jesse wá, ẹka kan yio si hù jade lati inu gbòngbo rẹ̀: Ẹmi Oluwa yio si bà le e, ẹmi ọgbọ́n ati oye, ẹmi igbimọ̀ ati agbara, ẹmi imọ̀ran ati ibẹ̀ru Oluwa. Õrùn-didùn rẹ̀ si wà ni ibẹ̀ru Oluwa, on ki yio si dajọ nipa ìri oju rẹ̀, bẹ̃ni ki yio dajọ nipa gbigbọ́ eti rẹ̀; Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutù aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ̀ lu aiye, on o si fi ẽmi ète rẹ̀ lu awọn enia buburu pa. Ododo yio si jẹ amure ẹgbẹ́ rẹ̀, ati iṣotitọ amure inu rẹ̀.
Kà Isa 11
Feti si Isa 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 11:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò