Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ

Finding Peace

Ọjọ́ 5 nínú 17

Bí Èrò Ọkàn Rẹ̀ ti ń Kóbá Ìbàlẹ̀ Ọkàn Rẹ̀

Tí a bá máa bárawa sọ òdodo ọ̀rọ̀, ọ̀pọ̀ nínú wa ni kìí ṣe ohun tí a lérò wípé a jẹ́. Èrò ọkàn wa, máa ń mẹ́hẹ lọ́pọ̀ ìgbà, àti wípé, ó nílò àtúnṣe.

O lè fẹ́ bèrè bóyá ǹkan yìí dá mi lójú? Yàtọ̀ sí ìrírí mi gẹ́gẹ́bí olùṣọ́ àgùntàn fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pèwá láti ṣe “ìsọdọ̀tun” sí ọkàn wa. Èyí túmọ̀ sí gbígba èróńgbà titun, èrò, ìgbàgbọ́, àti ìhùwàsí ọ̀tún láàyè, èyí tí Ọlọ́run ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, dípò àwọn àmúyẹ àtijọ́ tí ń bẹ nínú wa. Irúfẹ́ ìdáhùn tí máa dún Ọlọ́run nínú yìí ni a lè rí gbà nípasẹ̀ kíka Bíbélì lóòrè lóòrè àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tí a kà. A rọ àwọn ọmọ lẹ́yìn Krístì láti yẹra fún “dídarapọ̀ mọ́ ayé, ṣùgbọ́n kí wọ́n paradà nípa ìsọdọ̀tun ọkàn, kí wọ́n lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé” (Rom. 12:2).

Látinú ìsọdọ̀tun èrò wa ni ìyípadà yóò ti dé bá ìsọ̀rọ̀sí pẹ̀lú ìwà wa. Bí ọ̀rọ̀ àti ìwà wa ti ń ní ìsọdọ̀tun, ní ìbárẹ́ wá pẹ̀lú àwọn tó yí wa ká yóò ní ìsọdọ̀tun. Bí a ti ń sọ ìbárẹ́ wá dọ̀tun, ní agbègbè wá yóò ní ìsọdọ̀tun pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ jẹyọ wá látinú ọkàn nípasẹ̀ àwọn ohun tí a yàn láti ṣe àṣàrò lé lórí.

O ní agbára láti kó èrò rẹ ní ìjánu. Nígbàkúùgbà, ní o lè ṣe àtúntò ọkàn rẹ, láti fi èrò dídára, tí ó sì wúlò dípò èyí tó fẹ́ gba Ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ tó sì fẹ́ mú ọ dẹ́ṣẹ̀. O ní ipá láti sọ wípé, “mo yàn láti rọ̀ mọ́ Ọlọ́run,” nínú ohunkóhun tí o lè máa làkọjá.

Ní àfikún, ọmọ Ọlọ́run tí ó bá ní ìpinnu láti mú èrò-kérò kúrò lọ́kàn rẹ̀ ni yóò rí ọ̀nà àbáyọ ní irúfẹ́ àsìkò yí. Ọlọ́run yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi àfojúsùn rẹ sì àwọn ǹkan tí ó suwọ̀n ju ìpèníjà tàbí èrò búburú náà lọ níwọ̀n gbà to bá ti tẹ̀lé ìṣísẹ̀ Rẹ̀. 

Nígbà to bá pa ọkàn rẹ mọ́, ìbàlẹ̀ ọkàn rẹ lo pamọ́ yìí. Nígbà to bá gbàdúrà s'Ọ́lọ́run pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìdúpẹ́—ohunkóhun tí olè máa làkọjá—ni yóò ti fún ọkàn rẹ ní ìsinmi (Fílípì 4:6-7). Bí o sì ti ń ronú nípa àwọn ǹkan dídára, tó lọ́lá, tí ó mọ́, tí ó sì mú ọpẹ́ dání, ní ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ọlọ́run yóò tubọ̀ múlẹ̀ si. 

Gbogbo ìgbésí ayéè rẹ kò tó láti ṣe ìjíròrò lórí títóbi àti bí Ọlọ́run ti dára tó. Pinu láti dáhùn sí ìyè bí Jésù ti ṣe. Pa àkókò àdúrà rẹ mọ́. Pa èrò rẹ mọ́. Ṣe àwárí Baba àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣèlérí wípé nígbà tí o bá fi ọkàn rẹ ṣe kìkìdá ohun dídára, “Ọlọ́run àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú rẹ” (Fílípì 4:9).

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Finding Peace

Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò: https://intouch.cc/peace-yv