Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Ǹkan Márùn-ún tí yóò fún ọ ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn
Tí o bá jẹ́ Krìstẹ́nì, Ọlọ́run nìkan ni yóò darí ayéè rẹ. Òhun ni àbò rẹ. Kòsì já ìṣẹ̀dá rẹ̀ kankan kulẹ̀ rí láti ìgbà ìfilọ́lẹ̀ ayé. Kò fìgbà kankan pàdánù ipá tàbí agbára Rẹ̀. Ó jẹ́ ohun gbogbo nínú ohun gbogbo, iná ìfẹ́ Rẹ̀ kò sì jó àjórẹ̀yìn rí.
Ìṣe Rẹ̀ lè má yéwa lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà tí àwọn ọ̀nà Rẹ̀ bá yéwa ni a ó tó mọ̀ wípé gbogbo ìṣe Rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ìbùkún ayérayé àwọn ọmọ Rẹ̀. Nínú ìrìn àjò ayéè mi, a ti múmi rí àwọn ǹkan márùn-ún tó ṣe pàtàkì fún ìbàlẹ̀ ọkàn. Mo pè ọ́ níjà láti, ro àrò-jinlẹ̀ nípa àwọn ìgbàgbọ́ tí o ní nínú Ọlọ́run. Bí ìgbàgbọ́ rẹ tí jinlẹ̀ tó ni yóò jẹ́ gbèdéke Ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ.
Ìgbàgbọ́ Kínní: Ọlọ́run borí ohun gbogbo.
Láti ni Ìfọ̀kànbalẹ̀ a nílò láti mọ̀ kí a sì gbà wípé Ọlọ́run borí ohun gbogbo. Èyí túmọ̀ sí wípé kò sí ohun tó jẹ́ tìrẹ tí kò sí ní ìkápá Rẹ̀. (Kólósè 1:17)
Ìgbàgbọ́ kejì: Ọlọ́run ni Olùpèsè rẹ.
Láti páálí kan sì èkejì, ní Bíbélì ti fi lélẹ̀ wípé Ọlọ́run ní Ẹni náà tó ń bá gbogbo àìní wa pàdé. Kòsí àìní kan tó tóbi jù, tàbí tó kọjá agbára Jésù láti bá pàdé. Bíbélì fi yéwa, “Àwọn tó ń ṣe àwárí Olúwa kí yóò ṣe àìní ohun dídára kankan” (Ps. 34:10).
Ìgbàgbọ́ kẹ́ta: Ó ní ìdí tí Ọlọ́run fi dá ọ bí ó tiwà.
Ọ̀pọ̀ ǹkan nípa ayéè rẹ ni o kò ní àkóso lé lórí. Gba àwọn ǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi ètò Ọlọ́run fún ìṣẹ̀dá rẹ. Àwọ̀, àṣà, èdè, ìlúù rẹ, àti àwọn àmúyẹ tí a lè fojú rí lára rẹ ni ó wà bí Ọlọ́run ti “ṣètò” rẹ̀. Ó tún fún ọ ní àwọn ẹ̀bùn, òye, ọgbọ́n, ìwà, pẹ̀lú ẹ̀bùn èmi tó jẹ́ wípé, tí a bá kó wọn pọ̀, yóò sọ ọ́ di èèyàn tó dá yàtọ̀ láti mú ìpinnu Rẹ̀ fún ayéè rẹ. (Orin Dáfídì 139:13-16)
Ìgbàgbọ́ kẹ́rin: Ọlọ́run ní àyè kan tó pèsè fún ìwọ nìkan ṣoṣo.
Ọlọ́run dá ọ kí o ba le máa jọ́sìn pẹ̀lú Rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn bíi tìrẹ. Jẹ́rìí Rẹ̀ láti fà ọ́ mọ́ra àti láti ṣètò “ẹbí” onígbàgbọ́ bíi tìrẹ tí olè darapọ̀ mọ́. Lẹ́yìn èyí, bí ó ti ń dàgbà nínú Rẹ̀, gbìyànjú láti mú àwọn mìíràn wà sọ́dọ̀ Rẹ̀. (Pétérù Kínní 2:9).
Ìgbàgbọ́ karùn-ún: Ọlọ́run ní ètò fún àṣeyege rẹ.
Fún Ìfọ̀kànbalẹ̀ tòótọ́, ènìyàn nílò ìdánilójú wípé ǹkan gbòógì wà tí ohun wúlò fún. Ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìtẹ́lọ́rùn tó máa ń tẹ̀lé mímọ̀ wípé o tó gbangba-sùn-lọ́yẹ́ nídìí iṣẹ́ kan. (Éfésù 2:10)
Nígbà tí obá gba àwọn ǹkan márùn-ún yìí gbọ́ ni oókan-àyà rẹ tóo sì jẹ́rìí wípé Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ nínú rẹ àti fún ọ, Ìfọ̀kànbalẹ̀ ti di tìrẹ ni tòótọ́.
Nípa Ìpèsè yìí
Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.
More