Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Bíborí Ìbẹ̀rù
Ọ̀pọ̀ èèyàn ní máa ń rò wípé ìdàkejì ẹ̀rù ni ìrètí, ìgboyà, tàbí ipá. Àmọ́ ojúlówó ìdàkejì ẹ̀rù ni ìgbàgbọ́. Nígbà tí ẹ̀rù bá ká wa lọ́wọ́ kò, ó máa ń mú ìfọ̀kànbalẹ̀ wa kúrò, tí yóò sì dojú ìjà kọ ìpìlẹ̀ ìfọ̀kànbalẹ̀ náà—èyí tíí ṣe, ìgbàgbọ́ wa. Nígbàtí ẹ̀rù bá wọlé ṣeni ó máa ń lé ìfọ̀kànbalẹ̀ síta.
Lọ́pọ̀ ìgbà ni ẹ̀rù máa ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ni ìgbà tí iyèméjì bá dé, iyèméjì wípé Ọlọ́run yóò dìde, ṣe ìdájọ́ tàbí ìrànlọ́wọ́, tàbí ní ipá láti kojú wàhálà tó ń bá wa fíra. Ìgbàgbọ́ á sọ wípé, “Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run wà níhìn-ín. Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run yóò pèsè. Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run lè ṣe ohun gbogbo!”
Lọ́pọ̀ ìgbà ni ẹ̀rù máa ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìhàlẹ̀—nígbà míràn nínú ọ̀rọ̀, tàbí ìwà ìhàlẹ̀. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ sọ wípé, “Ìrọ́kẹ́kẹ́ kan kì yóò dáyà jámi. Èmi yóò wùwà bíi ọlọ́gbọ́n, ẹ̀rù yóò sì jìnà sími. Mo ní ìgbàgbọ́ wípé Ọlọ́run yóò dáwọ́ ìrọ́kẹ́kẹ́ náà dúró. Bí ìhàlẹ̀ náà bá padà ṣẹlẹ̀, mo ní ìgbàgbọ́ wípé Ọlọ́run yóò ràn mí lọ́wọ́ láti borí ohunkóhun tó lè dojú kọ mí.”
Nígbàtí Sọ́ọ̀lù, ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, ríi wípé ọwọ́ àmì òróró àti ìbùkún Ọlọ́run ti fi òhun ṣílẹ̀ (nítorí ìgbéraga àti àìgbọràn rẹ̀) tí ó sì ti bàlé ọ̀dọ́mọ kùnrin nì, Dáfídì, inú rẹ̀ ru lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lépa Dáfídì láti pa—láti mú ìdíwọ́ yìí, tí í ṣe Dáfídì, kúrò lọ́nà rẹ̀ (Sámúẹ́lì Kínní 19). Ní ìdàkejì, Dáfídì rí àwọn ọmọ-ogun Sólómọ́nì bíi ìrọ́kẹ́kẹ́ ìjọ̀gbọ̀n àti wípé ó bẹ̀rù fún ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n Bíbélì fi yé wa wípé a mú àyà Dáfídì le pẹ̀lú ìlérí Ọlọ́run láti dáàbò bò ó àti wípé a ó fi jọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ kan.
Lóde òní, a máa ń kà nípa àwọn èèyàn tó tẹra mọ́ àfojúsùn wọn, láì fi tí onírúurú ìdojúkọ ṣe—tí wọ́n sì rí ìjákulẹ̀, ìkọ̀sílẹ̀, àti nígbà míràn àṣeyọrí. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn eléré ìje, òjíṣẹ́ Ọlọ́run, oníṣòwò, àti àwọn tí máa ńṣe ìtọrẹ àánú ló ní irúfẹ́ ọ̀rọ̀-ẹ̀rí yìí. Nítorí náà kò yẹ kí ìrọ́kẹ́kẹ́ tàbí ìhàlẹ̀ ká wa lọ́wọ́ kò.
Ìpèníjà wa nígbàtí a ní ìdojúkọ kìí ṣe fífi ǹkan tó lè di òtítọ́ ṣe àfojúsùn, bí kò ṣe, láti fi ohun tí a mọ̀ dájú gẹ́gẹ́bí òtítọ́ ṣe àfojúsùn wa.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbé nínú òjìji dúdú, tí ìhàlẹ̀ mú wọnú ayée wọn. Àwọn kan ń kojú ìhàlẹ̀ àìsàn, àwọn míràn ń kojú ìhàlẹ̀ ìpalára sí ọmọ wọn, àwọn míràn sì ń gbọ́ ìhàlẹ̀ nípa àdánù iṣẹ́.
Ìdáhùn sí àwọn oríṣiríṣi ìhàlẹ̀ yí ni ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a mọ̀ wípé ó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ àti ìtọ́jú Rẹ̀ àti ipá Rẹ̀ láti pèsè fún gbogbo àìní wa—ní pàápàá ìfọ̀kànbalẹ̀ Rẹ̀, tó lè mú wa borí ohunkóhun.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.
More