Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ

Finding Peace

Ọjọ́ 10 nínú 17

Kíkọ́ Láti gbé Ìgbé-ayé Ìtẹ́lọ́rùn

Láti gbé pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, Jésù Kristi Olúwa máa ní láti jẹ́ àfojúsùn ayéè rẹ. 

Àwọn àkókò kúkúrú kan wà láyé mí tí ìṣòro tí mú mi ṣe àìsùn tipátipá, tí n ó sì máa yí kiri lórí ibùsùn. Mo ti kọ́ wípé ohun tó sàn láti ṣe ní irú àsìkò yí ni, láti dìde kúrò lórí ibùsùn, lọ lórí eékún mi, kí nsì képe Ọlọ́run wípé: “Jọ̀wọ́ mú mi la èyí já. Ràn mí lọ́wọ́ láti fi Ìwọ nìkan ṣe àfojúsùn mi.”

Orun máa ń wá pẹ̀lú ìrọ̀rùn nígbà tí mo bá fi Olúwa àti ìhà tí Ó fẹ́ kí n kọ sí ìpèníjà ṣe àfojúsùn. Orun máa ń jìnà sí mi nígbà tí mo bá fi ǹkan tí àwọn míràn sọ lòdì ṣe àfojúsùn, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nípa àwọn ǹkan tó lè ṣẹlẹ̀, tàbí ìdojúkọ ìpèníjà ọjọ́ iwájú. Àti yan ààyò rẹ kòní le rárá—ṣáá máa ronú nípa Ọlọ́run àti ìpèsè Rẹ̀, ìdáàbòbò, àti ìfẹ́, tàbí olè yàn láti ronú nípa àwọn ènìyàn tàbí ìdojúkọ tó fẹ́ gba àwọn ohun tí Ó ti pèsè lọ, tó fẹ́ ba ayéè rẹ jẹ́, tàbí da ìkórìíra sí ọ ní agbada.

Ẹni tí ń sábà ronú nípa Olúwa yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ìrònú nípa ohun mìíràn máa ń kọ lẹ́tà ránṣẹ́ sì àníyàn, ẹ̀rù, tàbí ìdààmú. 

Nígbà tobá fi Olúwa ṣe àfojúsùn, ó ṣe pàtàkì fún ọ láti rí i gẹ́gẹ́bí akọni lójú ìjà, ní àkókò náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ní máa lérò wípé Ọlọ́run jìnà réré. Wọn kò rí Ọlọ́run bíi ẹni tí ó lè gbà wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, Ó wà nítòsí fún gbogbo ìṣẹ́jú ayéè wa.

Mo rántí ìlú kan tí ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ̀ kò láfiwé—Òkun Gálílì. Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, mo dúró sí ibìkan lẹ́bàá òkun yìí tí a lè fi ṣe àpèjúwe ìtura-aláìlábàwọ́n. Ṣùgbọ́n, ní ayé òde òní, ṣàṣà lẹni tó ma gbà wípé àlàáfíà wà níbi tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Máìlì díẹ̀ ló wà láti ibẹ̀ sí ìlú Síríà àti Lẹ́bánónì. Ìrísí àwọn ènìyàn nípa Ísírẹ́lì ní wípé ìlu rògbòdìyàn níí ṣe, ibi tí àlàáfíà tí sáfẹ́rẹ́.

Ṣùgbọ́n ní ibi tí à ń sọ yìí ni mo ti ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Èéṣe? Nítorí mo kófìrí Olúwa níbẹ̀. Mo ní ìmọ̀lára ìwàláàyè Rẹ̀.

Ó rọrùn fúnmi láti di ojú àti láti rí bí Olúwa ti ń bá mi rìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ lẹ́bàá Òkun Gálílì. Ó sì jẹ́ àǹfààní tó rọrùn fúnmi láti ríran nípa ìrìn Olúwa lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi ní ibikíbi tí mo bá wà lórílẹ̀ àgbáyé.

Kìí ṣe àwọn ohun tó yí mi ká ló ń mú ìfọ̀kànbalẹ̀ wá. Àkíyèsí ìwàláàyè Ọlọ́run tí mo ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní àwọn àyíká wọ̀nyí ní máa mú ìfọ̀kànbalẹ̀ wá. Ìmọ̀lára yìí wípé “Ọlọ́run ńbẹ pẹ̀lú mi” ló ṣe pàtàkì fúnmi láti ṣe àtúntò, láti wo àyíká pẹ̀lú ojú ẹ̀mí, nígbà tí ìdààmú bá ṣubú lu ayéè mi.

Ọ̀rẹ́, ibikíbi tó wù kí o wà lákòókò yí, Jésù ni orísun ìtẹ́lọ́rùn fún ọ. Wo bí Olúwa ti ń bá ọ rìn nínú àlàáfíà. Kíyèsí ìmọ̀lára ìwàláàyè Rẹ̀. Ṣe àkíyèsí agbára ńlá àti àṣẹ Rẹ̀ lórí ayéè rẹ. Nígbà tobá wọnú ìbárẹ́ pẹ̀lú Kristi nípa ìgbàgbọ́, pẹ̀lú ìdánilójú ìwàláàyè àti ìpèsè Rẹ̀ nínú ayéè rẹ, mọ̀ dájú wípé o máa ní ìrírí ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀.


Tí o bá ń kojú wàhálà nínú ayéè-kòyémi yìí, tẹ here láti kọ́ síi bí o tilè gbé ní ìfọ̀kànbalẹ̀.

­

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 9Ọjọ́ 11

Nípa Ìpèsè yìí

Finding Peace

Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò: https://intouch.cc/peace-yv