Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Gbígbé ní Àlàáfíà Pẹ̀lú àwọn Mìíràn
Ìpèníjà tí gbogbo wa máa ń kojú lóòrè kóòrè lèyí: Báwo lati lè gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti bí àti lè mú àlàáfíà bọ̀sípò nígbà tí àríyànjiyàn bá wáyé?
Òdodo ibẹ̀ ni wípé, ìfẹ́ Ọlọ́run ni fúnwa láti gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tó wà ní àyíká wa. Ó sì mọ̀ wípé àríyànjiyàn yóò wáyé lẹ́ẹ̀kànkan. Ìjà sì lè bẹ́ sílè. Nígbà míràn, ìjà kìí rọrùn láti parí. Kódà, àwọn ìjà kan wà tí kò ṣeé parí. Síbẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.
Àwa ọmọlẹ́yìn Krístì mọ̀ wípé tí Ọlọ́run kò bá ti darí ayéè wa, bíi aláìgbàgbọ́ paraku ni a ṣe máa hùwà. Ìgbàlà ọkàn wa kò ní mú owú, ìkórìíra, tàbí ìbínú kúrò láyé wa lójijì. Àfi nígbà tí a bá tó jọ̀wọ́ ayéè wa fún Ẹ̀mí Mímọ́, àti bí a tií kọbiara sí ìtọ́ni Rẹ̀, àti bí a tií gbìyànjú láti jẹ́ agbẹnusọ Rẹ̀ nínú gbogbo ìbárẹ́ wa laó tó lè bọ́ lọ́wọ́ ìgbéraga tí a ó sì bọ sínú àwọn ìwà tí yóò mú àlàáfíà jọba.
Báwo lati lè yanjú ìjà tí àlàáfíà yóò sì jọba?
Àkọ́kọ́, mọ ìdiwọ̀n ìbárẹ́ náà. Tí o bá máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú ẹlòmíràn, o ní láti pinnu, “Ṣé ìbárẹ́ yìí ṣe pàtàkì débi tí mo máa nílò láti múu bọ̀ sípò? Ṣé mo ṣe tán láti ní ìyípadà díẹ̀ nítorí ìbárẹ́ yìí?” Mo ní ìgbàgbọ́ wípé fún àwọn tí a ti gbàlà, àti ní ìbárẹ́ nínú àlàáfíà kìí ṣe ohun tó ṣòro.
Èkejì, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ … kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ síi . Nígbà tí ènìyàn méjì bá ń sọ̀rọ̀—tí wọ́n sì ṣetán láti máa tẹ́tí sí ẹni kejì—àti fòpin sí ìjà pẹ̀lú ìbárẹ́ àlàáfíà kò jìnà sì àwọn méjèèjì.
Ìkẹta, má fi nkankan pamọ́. O kò lè ní ohun ìkọ̀kọ̀ tàbí ìpinnu ẹ̀tànjẹ kí o sì máa retí láti ni ìbárẹ́ àlàáfíà. Nígbà tí ìjà bá dé ìṣòótọ́ máa mú kí ìlàjà rọrùn nínú ìbárẹ́.
Lákòótán, lọ sí ibi gbòǹgbò ìṣòro náà. Bí o ti ń bá àwọn míràn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan, tí o sì fi ọkàn òtítọ́ wo ọ̀dádá ìjà náà, yóò wà rọrùn láti kojú ìpèníjà pẹ̀lú fífi ẹsẹ̀ àlàáfíà múlẹ̀.
Bí o ti ń gbìyànjú láti gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, mọ̀ dájú wípé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ. Yóò mú kí gbogbo ìdojúkọ àti ìpọ́njú mú èrè wá fún ọ ní ìkẹyìn. Yóò múu ìdàgbàsókè nípa ẹ̀mí bá ọ, pẹ̀lú agbára ìforítì fún ọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.
More