Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ

Finding Peace

Ọjọ́ 7 nínú 17

Kíkọ Àníyàn Sílẹ̀

Àníyàn jẹ́ ìpèníjà tí gbogbo wa máa ń kojú nígbà kan tàbí òmíràn. Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù wípé: 

Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fún yín pé kí ẹ má máa ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ tàbí kí ni ẹ óo mu, tàbí pé kí ni ẹ óo fi bora. Mo ṣebí ẹ̀mí yín ju oúnjẹ lọ; àti pé ara yín ju aṣọ lọ. Ẹ wo àwọn ẹyẹ lójú ọ̀run. Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó nǹkan oko jọ sinu abà. Síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Mo ṣebí ẹ̀yin sàn ju àwọn ẹyẹ lọ! (Mátíù 6:25-26)

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a ṣe ògbùfọ̀ rẹ sì “àníyàn” nínú ẹsẹ̀ Bíbélì yìí túmọ̀ sí “àìní àfojúsùn.” Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń tọ́ka sí iyèméjì. Ohun tí àníyàn máa ń fà lọ́kàn nìyí. Ó máa ń fi èrò náà sí ọkàn wa wípé, Kí lọ́kàn? Bíi èrò tí yóò wà sọ́kàn, ni ìṣẹ́jú-àáyá tó ṣáájú ìṣubú fẹ́ni tó kosẹ̀.

Ọ̀rọ̀ yí “àníyàn” ni wọ́n tún ṣe ògbùfọ̀ rẹ sí “ìyọnu” nínú Bíbélì. Fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìyọnu tidi bárakú. Tí àpèjúwe yìí bá bá ìgbésí ayéè rẹ mu, mo máa rọ̀ ọ́ láti ka ọ̀rọ̀ Jésù l'ẹ́ẹ̀kan si. Ọ̀rọ̀ yí kò wá bíi àbá—àṣẹ ni wọ́n jẹ́.

Ó ṣeéṣe kóo fèsì wípé, “Kòsí ọgbọ́n tí mo lè dá, àníyàn ni ṣáá lójojúmọ́.” Mo ti gbọ́ tí àwọn èèyàn ń sọ ǹkan tójọ èyí lọ́pọ̀ ìgbà. Èsì mi fún wọn ni, “O lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn.”

Kòsí ǹkankan nípa ìdojúkọ tó lè mú àníyàn wáyé lójijì. Ìhà tí a kosí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló ma ń fa àníyàn. Ara àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi fúnwa ni ore-ọ̀fẹ́ láti yan ohun tí a fẹ́. O lè yan ìhà to máa kọ sí ìdojúkọ tó bá dé bá ọ. O lè yan ohun tí o máa gbà rò, o sì lè yan ìhà to máa kosí ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá dé bá ọ. Ó dájú wípé kìí ṣe ètò Ọlọ́run fún ọ láti máa ṣe àníyàn—àwọn ìdojúkọ ayéè rẹ kìí ṣe fún ìpẹ̀gàn rẹ. Baba le gba ìdojúkọ láàyè láti mú ìgbàgbọ́ rẹ jinlẹ̀ si, láti dàgbà nínú èmi, tàbí láti mú ìwà búburú kan kúrò. Ṣùgbọ́n àníyàn kìí ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run fún ọ. Ìgbìyànjú Rẹ̀ lójojúmọ́ ni láti mú ọ dé ipele tí ó máa ti jẹ́rìí Rẹ̀ síi, tubọ̀ ṣe ìgbọràn, àti tẹ́wọ́ gba ìbùkún síi.

O le máa yíràá nínú kòtò àníyàn. Tàbí gba ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run láti sọ wípé, “Baba, mo gbé èyí tọ̀ Ọ́ wá. Ó kọjá agbára mi. Nkò mọ ibi tí máa bá yàrá já, ṣùgbọ́n O lágbára láti yí ìgbà mi padà. O fẹ́ràn mi tọkàn-tọkàn, mo sì jẹ́rìí wípé Ìwọ yóò yanjú ọ̀rọ̀ mi lọ́nà tó tọ́. Momọ̀ wípé gbogbo ètò rẹ fún mi dáradára ni. Mo ṣe tán láti ni ìrírí ìfẹ́, ọgbọ́n, àti agbára Rẹ̀ ni gbogbo ọ̀nà tó lérò pé ó tọ́ láti fi wọ́n hàn sí mi.”

Ọ̀rẹ́, ọ̀nà tó lọ sí ìlú Ìfọ̀kànbalẹ̀ nìyí—òpópó tó jáde kúrò ní ìlú àníyàn àti ìyọnu.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6Ọjọ́ 8

Nípa Ìpèsè yìí

Finding Peace

Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò: https://intouch.cc/peace-yv