Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ

Finding Peace

Ọjọ́ 6 nínú 17

Ìgbésí-ayé tí Kòní Àbámọ̀

Mo rántí bí mo ti míkanlẹ̀ ni ọjọ́ náà lẹ́yìn tí mo gbà ìpè orí-ago, “O tí ṣẹlẹ̀!” 

Ní òdì-kejì ilà ìpè náà ni mo tí ń gbọ́ ohun agbejọ́rò kan, bí ó ti ń fi tó mi létí nípa ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí aya mí mú lọ sílé ẹjọ́ . 

Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni mo ti ń fòyà pé ọjọ́ yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. Síbẹ̀, ìròyìn ọ̀hún ṣì bá mi lójijì. 

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, oríṣiríṣi èrò ló ń ṣubú lura l'oókan àyà mi. Nkò fẹ́ kọ aya mi sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni nkò mọ ìgbésẹ́ tó kàn látìgbé. Nkò mọ ẹni tí mo lè fi ọ̀rọ̀ náà lọ̀, tàbí bí n ó ti ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Ó tún wá hàn sí mi wípé mo máa ní láti sọ fún ìjọ tí mò ń darí gẹ́gẹ́bí olùṣọ́àgùntàn, àti wípé n kò mọ bí àwọn ìgbìmọ̀ ìjọ àti ọmọ lẹ́yìn wọn yóò ti gba ọ̀rọ̀ náà. Ohun kàn tí ó dájú ni ìgbáradì láti ṣe ìwàásù ọjọ́ ìsìn tó ń bọ̀.

Pẹ̀lú bí ọkàn mi ti ń sáré bí ẹ̀rọ alùpùpù, mo ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú àwọn òtítọ́ wọ̀nyí: 

· Ohun tí mo ń làkọjá kò jẹ́ ìyàlẹ́nu fún Ọlọ́run.
· Ọlọ́run wà lójú àkóso ayé mí—Ó gba èyí láti ṣẹlẹ̀ sí mi gẹ́gẹ́bí ara ètò rẹ̀ fún mi.
· Ó ti ṣe ìlérí nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ láti má kọ̀mí tàbí fi mí sílẹ̀. Ó ti ṣèlérí àti bámi rìn títí d'ópin; fún ìdí èyí, ohun gbogbo ni yóò padà yọrí sí rere níwọ̀n gbà tí mo bá tẹ̀síwájú nínú ìjẹ́rìí Rẹ̀ ní kíkún.

Àwọn ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò náà fà ìpòrúru ọkàn. Òtítọ́ Ọlọ́run tí kìí yí padà mú Ìfọ̀kànbalẹ̀ wá.

Lẹ́yìn bíi ọdún mẹ́jọ tí agbejọ́rò ọjọ́ náà pè mí, ni aya mi tó ṣe àṣeyọrí lóríi ìkọ̀sílẹ̀ tó fẹ́ gbàṣe rẹ̀.

Lẹ́yìn ìgbà yí ni àwọn ènìyàn a máa sọ fún mi wípé: “Ódájú wípé o kábàmọ́ọ̀ fún ìgbéyàwó rẹ tó fìdí rẹmi … wípé gbogbo ìgbìyànjú rẹ láti mú ìgbéyàwó yìí bọ̀sípò jásí asán.”

Èsì mi lọ́pọ̀ ìgbà sì irú ọ̀rọ̀ báyìí ni láti dákẹ́. Ṣùgbọ́n, nínú kọ̀rọ̀ ọkàn èsì tí mo máa ń fi ni, mo lè ní ìbànújẹ́ ní tòótọ́. Ṣùgbọ́n tóbá jẹ́ àbámọ̀, kámári. 

Lóòótọ́ ni mo banújẹ́ wípé ìgbéyàwó mi jásí ìkọ̀sílẹ̀, ṣùgbọ́n nkò ni àbámọ̀ kankan. Kíló fàá? Nítorí àbámọ̀ máa ń ṣú yọ látinú ìdálẹ́bi tí a kò yanjú. Mo ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, fún ìdí èyí nkò ni àbámọ̀ tàbí ìdálẹ́bi.

A ti fi yé mi wípé ọ̀nà tó dára jù láti fi sáfún àbámọ̀ ni láti gbé ìgbé-ayé àìlẹ́bi. Tiraka láti sa gbogbo ipá rẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àti ìbárẹ́ tí o bá ti bára rẹ, sísa gbogbo ipá rẹ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. Pinu láti jẹ́rìí Ọlọ́run nínú gbogbo ìpéle ayéè rẹ—kìí ṣe ni àwọn ibi tí óti rọrùn nìkan. Pinu láti gbọ́ràn àti láti tẹ́lẹ̀ àwọn ìlànà rẹ. Pinu láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ ọ́ tọkàn-tọkàn. O sì nílò láti tẹ̀lé àwọn àlàálẹ̀ tí Ọlọ́run bá fi hàn sí ọ.

Lóòótọ́ kòsí ẹni t'ólè ṣe gbogbo ǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú ipá ẹran ara, ṣùgbọ́n pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń gbé nínú wa, a lè kọ ẹ̀yìn sì gbogbo ìdánwò kí a sì lépa àlàáfíà pẹ̀lú arawa àti ọmọ làkejì wa—pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú nínú ìṣe rere tí Ọlọ́run fi lèwa lọ́wọ́. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Finding Peace

Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò: https://intouch.cc/peace-yv