Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Ìdí tí A fi Máa ń Pàdánù Ìfọ̀kànbalẹ̀
Ọ̀nà kan ṣoṣo ló wà tí a lè fi ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó borí onírúurú ìpèníjà—nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. Ìgbàgbọ́ jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé Ìfọ̀kànbalẹ̀ ti Ọlọ́run—Ìjẹ́rìí ìyè, tí ó ní ìdánilójú nípa ìwàláàyè àti agbára Rẹ̀ fún ìmúdúró àti ìtùnú, nínú gbogbo ǹkan tí ìwọ lè làkọjá. Ṣùgbọ́n, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míràn wà, tó lè mú kí ìfọ̀kànbalẹ̀ wa ṣáko lọ. Ẹ jẹ́ kí a gbé mélòó kan yẹ̀wò nínú rẹ̀:
1. Ìpayà Òjijì—Àwọn ènìyàn wà tó jẹ́ wípé wọn kò lérò wípé ìhà míràn wà tí a lè kọ sí rúkè-rúdò ju ìpayà. Ìyípadà díè ti tó fún wọn láti ni ìpòrúru ọkàn.
2. Ọ̀tá—Ọ̀tá wa Èṣù, le dojú ìjà kọ wá, ní orísirísi ọ̀nà láti lè mú wá ṣe iyèméjì àti láti pàdánù ìgbàgbọ́ wá nínú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n a ní láti dìde ìjà síi. Bíbélì rọ̀wá láti dojú ìjà kọ èṣù, tí a bá sì ṣe èyí, yóò sá kúrò ní sàkání wa (Jákọ́bù 4:7).
3. Ẹ̀ṣẹ̀ —Ìfọ̀kànbalẹ̀ àti oríkukun ò lè kọ́wọ̀ọ́rìn. Àbájáde kan tí ó wà ni láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wá fún Ọlọ́run, jọ̀wọ́ ara wa fún-un, àti ìbèrè fún ìrànwọ́ Rẹ̀ láti le yẹ̀bá fún ìdánwò. Nígbà náà, ní ìfọ̀kànbalẹ̀ Ọlọ́run tó lè jọba.
4. Kíkọ Ìfọ̀kànbalẹ̀ Sílẹ̀—Ní àkókò rògbòdìyàn, nígbà míràn la máa ń pa ìfọ̀kànbalẹ̀ wa tì sí ẹ̀gbẹ́ kan. A máa fi sílẹ̀. Jọ̀wọ́ rẹ̀. Paátì. Ṣùgbọ́n rántí wípé kòsí ẹni tíó lè gba ìfọ̀kànbalẹ̀ wa lọ; bíkòṣe pé a jọ̀wọ́ rẹ̀. Èyí tó túmọ̀ sí wípé, àwa la lè gbà á padà.
5. Ìpàdánù Àfojúsùn—Àwọn ìròyìn ìbànújẹ́ tí à ń rí lójojúmọ́ lè jẹ́kí a pàdánù àfojúsùn wa tí a bá fàyè gbà wọ́n. Dípò ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run fún ìwàláàyè àti ìfọ̀kànbalẹ̀ Rẹ̀, ṣeni a máa ń gba àwọn ìròyìn àti ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ wọ̀nyí láàyè láti darí ọkàn wa.
Nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa, a kò ní láti soríkọ́, lúwẹ̀ẹ́, tàbí fìdí jálẹ̀ nítorí àwọn ìdojúkọ wa. A lè kojú, dojú ìjà kọ, lù mọ́lẹ̀, àti borí gbogbo rẹ̀ nípa agbára àgbélébùú. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ wípé onírúurú wàhálà ló ń kọjá lọ lákòókò tirẹ̀ … àti fún ìdí kan. Nítorí náà “ẹ má ṣe fòyà” (Jòhánù 14:27). Dìrọ̀mọ́ ìfọ̀kànbalẹ̀ tí Ọlọ́run fi fúnni, pẹ̀lú ìdánilójú wípé Ó ń ṣọ́wa, darí, àti ṣe ìtọ́jú àwọn tó jẹ́rìí Rẹ̀ tí wọ́n sì gbàágbọ́.
Nípa Ìpèsè yìí
Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.
More