Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ
Ìfọ̀kànbalẹ̀ tí Ọlọ́run Fifúnni
Tí ìwọ bá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó dá mi lójú wípé o ti máa ṣe àkíyèsí wípé àwọn àfiwé pọ̀ jọjọ nínú Ọ̀rọ̀o Ọlọ́run. Fún àpẹrẹ, Ó máa ńṣe àfiwé láàárín ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ọlọ́gbọ́n àti omùgọ̀, òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀, nípa kókó ọ̀rọ̀ tí à ń gbé yẹ̀wò, ìfọ̀kànbalẹ̀ tí Ọlọ́run ní àfiwé pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ ti ayé yìí. Jésù sọ wípé, “Àlàáfíà mi ni mo fun yín; Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ní …” (Jòhánù 14:27).
Bí a ti ríi kedegbe, Olùkọ́ni ń fi ìdí rẹ múlẹ̀ wípé ìfọ̀kànbalẹ̀ tí òhun fifún àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ yàtọ̀ sí ti ayé yìí. Nípa “ayé” tí Jésù mẹ́nu bà, ìkórajọpọ̀ àwọn ènìyàn àti àṣà ni èyí túmọ̀ sí.
Ǹjẹ́ o ti wà lójú agbami rí? Mo ti ní ìrírí ìjì lórí agbamin lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá sì máa sọ òótọ́, nkò ní ìfẹ́ láti ní irú ìrírí yìí mọ́! Ní ojú agbami, afẹ́fẹ́ lè máa sáré níwọ̀n máhílì ogójì sí ọgọ́rùn-ún láàárín wákàtí kan, nígbà míì pẹ̀lú òjò, àrá, àti òkùnkùn birimù. Ìrú-omi lè ga níwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà ogún, tàbí àádọ́ta nígbà míì. Nínú irú ìjì báyìí ni àwọn ọkọ̀ ńlá yóò ti máa gbá kiri bí èyí tí a fi ewé kọ́. Ó rọrùn fún àwọn ọkọ̀ ńlá tí ń ná orí òkun láti ṣègbé nínú irú ìjì báyìí. Ṣùgbọ́n lábẹ́ omi tí ìjì tíì ń jà yìí, ní bíi ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà ọgọ́rùn-ún sí ìsàlẹ̀, ni kò ti sí ìjì kankan. Níbẹ̀ ni ohun gbogbo yóò sì palọ́lọ́. Kò ní sí ìró-ohùn. Kò ní sí rògbòdìyàn. Kódà kò ní sí ìrú-omi bó ti wù kómọ.
Àwọn ìrírí wọ̀nyí máa ń múmi ronú nípa ìfọ̀kànbalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó máa ń fún mi ní ìrísí nípa irúfẹ́ ìfọ̀kànbalẹ̀ tí Olúwa ṣèlérí láti fún àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀. Ó sọ fún wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Rẹ̀, wípé wọn yóò kojú wàhálà nínú ayé. Kódà, Ó wípé a óò pọ́n ọpọ nínú wọn lójú torí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Rẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù gbogbo rẹ̀, Ó ṣèlérí ìpamọ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀, àti wípé ìwàláàyè Rẹ̀ ni yóò jẹ́ ipa ọ̀nà sí ìfọ̀kànbalẹ̀ àtọ̀runwá.
Nígbà tí ìfòyà, àníyàn, àti ìdààmú bá bẹ̀rẹ̀ nínú ayéè rẹ, ṣe àwárí àwọn àmì ìfọ̀kànbalẹ̀ Ọlọ́run wọ̀nyí nítorí ó …
· Borí ohun tí a lè máa làkọjá. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìfọ̀kànbalẹ̀ máa ń túbọ̀ jẹyọ lákòókò ìdánwò àti ìdààmú. Ṣùgbọ́n láìfi gbogbo ǹkan wọ̀nyí ṣe, mọ èyí dájú wípé: Ọlọ́run ni àlàáfíà rẹ. Ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀.
· Kọjá òye. Ìfọ̀kànbalẹ̀ àtọ̀runwá kìí ṣe ohun tí a lè máa wádìí rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n ó ń ṣiṣẹ́, ó sì ńbẹ nínú wa—ó sì kọjá òye ẹ̀dá.
· Tọ́sí gbogbo ọmọlẹ́yìn Rẹ̀. Ìfọ̀kànbalẹ̀ àtọ̀runwá tọ́sí gbogbo ènìyàn tó gba Jésù gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà, kọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ṣílẹ̀, tí wọ́n sì ń lépa Ìgbésí-ayé ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti sí Ẹ̀mí Mímọ́.
· Jẹ́ ipele ìwàláàyè tó wà títí. Nígbà tí a bá ń la àwọn àkókò tó nira kọjá, Ẹ̀mí Mímọ́ wà níbẹ̀ láti rànwá lọ́wọ́. Ìfọ̀kànbalẹ̀—ìjìnlẹ̀, òtítọ́, tí Ọlọ́run fi fúnni—lè jẹ́ “ìpín” rẹ lójojúmọ́.
Bí ó ti ń tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò ayéè rẹ, ní ìjẹ́rìí àti ìgbàgbọ́ wípé ìfọ̀kànbalẹ̀ ojojúmọ́ ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún ọ—ìfọ̀kànbalẹ̀ tó ní ayọ̀ àti èrèdí ni gbogbo ipele ayéè rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e, o ñ pèsè àwon èròjà fún o láti yanjú àbámọ̀ atijo, dojú ko àwon àníyàn ísinsìnyi, àti máratu o látówo ìdààmú nípa òjo ìwájú.
More