Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ - Ọgbọ́nÀpẹrẹ

Seeking Daily The Heart Of God - Wisdom

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ọgbọ́n Tí Mbẹ́ Nínú Ìwà Ìrẹ̀lẹ̀

Ọgbọ́n ní àkópọ̀ pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Ó jẹ́ apá kan ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó rú ní lójú. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ní ìdíyelé àkọ́ọ́nú tí ó tóbi tí kò láfiwé. Lóòótọ́, ọgbọ́n jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn orísun tí ó ga láti gbé gẹ́gẹ́. Ti o bá fẹ́ ọgbọ́n, ìwọ yíò gbé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wọ ọkàn rẹ̀. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ a máà gbé ọgbọ́n jáde bí awakọ̀ ṣé máà ń gbé oníbàrà rẹ̀ lọ sí ibi tí ó fẹ́. Ọgbọ́n a máà rìn papọ̀ pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ nínú ìrìn-àjò wọ́n. Ní àwọn ọ̀nà miran, ọgbọ́n a máà mú ipò ẹ̀hìn sí ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní òye ohun tí wọn nílò fún ọgbọ́n Ọlọ́run. Ìdíbọ́n pé ẹnìkan wá tí ó sọ ara rẹ̀ di ọlọ́gbọ́n tí ó mọ ohun gbogbo tí kọjá lọ. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ń kán tí ó hàn kedere nínú ìwúlò rẹ̀ fún bí èrò ọkàn Kristi ṣé jẹ́ ìkòríta òye Rẹ̀. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ já fáfá láti jẹ́wọ́ ohun tí kò mọ̀. 

Ìgbè ayé tó wọ́pọ̀ kọjá òye ẹ̀dá. Ó yẹ kí ohun tí ó tayọ òye ènìyàn wá. A kò ní èròǹgbà tí ó péye tó láti yàn ohun tí ó dára jù pẹ̀lú òye wá tí kò tó ńkan. A nílò ọgbọ́n Ọlọ́run láti ṣe àfọ̀mọ́ èrò ọkàn wa àti kí a fí ìyókù òdodo Rẹ̀ silẹ́ fún. Ìrẹ̀lẹ̀ fí wá sí ipò láti kọ́ ọgbọ́n lọdọ Ọlọ́run àti ẹlòmíràn pẹ̀lú. Ó jẹ́ ìlànà ìdàgbàsókè. Jésù pàápàá dàgbà ní ọgbọ́n. (Lúùkù 2:52).

Ìgbéraga ń tí wá kúrò ní ọ̀nà tí a lè fí ní ọgbọ́n ni. O dabi olùgbá bọ́ọ̀lù akọkọ ni ọwọ òsì àwọn tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́ gbà ní orí pápá. Ko si ẹnikan ti o wa lori ipilẹ akọkọ láti retí bọ́ọ̀lù. Ó tí kúrò ni ipo ni kete ti o ba fọwọ́ kán bọ́ọ̀lù. Láìsí ìrẹ̀lẹ̀, kò sì ọ̀nà àbáyọ fún ọ láti ní ọgbọ́n. Ó lè nífẹ́ láti ní ọgbọ́n, ṣùgbọ́n láìsí ìrẹ̀lẹ̀, ìwọ yíò dì onírora aláìní nínú àwọn ìtọ́sọ́nà tí ọrùn. Ó sọ̀wọ́n kí Ọlọ́run tó fún agbéraga ènìyàn ní ọgbọ́n tírẹ̀ nítorí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ṣeé fí ọkàn tán. Kíni ìdí tí a níláti gbé ohun tó níye lórí bàyi lè ọwọ ẹniti yíò ló ní ìlòkulò tàbí ló gbogbo rẹ̀ fún ara rẹ̀ nìkan? Ọlọ̀run mọ́ wípé ònírẹ̀lẹ̀ ọkàn yíò jẹ́ ìríjú rere tí ó kún fún ọgbọ́n. Lóòtọ́, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ a máà mú kí ọkàn pòùngbẹ ọgbọ́n. Ó ń rú ìkúdùn òkèlè ọgbọ́n sókè. 

Ní kété tí ó bá ṣe àtúnṣe oúnjẹ Ẹ̀mì rẹ̀, ìwọ kò ní padà lọ láti jẹ ìjẹkújẹ oúnjẹ ọgbọ́n ayé.(Kọ́ríńtì kíni 1:20-30). A gbé ọgbọ́n ayé kalẹ̀ nínú ìgbéraga. Ó jẹ́ ìjàkadì agbára lórí ẹni tí ó jẹ ọlọ́gbọ́n julọ àti ẹni tí ó lè yàrá láti jáfáfá jú alátakò wọ́n. Ohun gbogbo ní ó jẹ èrè ìje sí àwọn agbéraga. A máà ṣe bí asiwèrè ènìyàn a sì máà jìjàdù ipò nípa agbára rẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn, ní ìdàkéjì, a máà fí sùúrù dúró dé Ọlọ́run. Ìjìnlẹ̀ kán wá tí àìsèmẹ́lẹ́ àti ìpinnu tí ó ńrinpọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n tí a rí gbá pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti àgbẹ́kẹ̀lé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìtìjú jẹ́ alábarìn ìgbéraga ní ìrìn àjò. Ìgbéraga lè fún ọ ní nǹkan tí ó fẹ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìtanijí ìtìjú nínú dígí láti ẹhin.

Ó sán láti jẹ ónirẹ̀lẹ̀ kí a sì tẹ̀ sì ọ̀nà ọgbọ́n. Ọgbọ́n ń fún ní láyè láti sinmi dáradára; ọgbọ́n ń fún ní nì óòre-ọ̀fẹ́; ọgbọ́n sì ń mú àbájáde wá láì kábámọ̀. Nitorina, fi ìrẹ̀lẹ̀ pè kí ó sì kí ká àbọ̀ sínú óòre-ọ̀fẹ́ ọgbọ́n Ọlọ́run.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Seeking Daily The Heart Of God - Wisdom

Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ jẹ́ ètò ẹ̀kọ́ kíkà ọlọ́jọ́ 5 tí a ṣètò rẹ̀ láti ru 'ni sóké, pe'ni níjà àti láti ràn wá lọ́wọ́ lójú ọ̀nà ìgbé-ayé ojoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí Boyd Bailey ṣe sọ, " Wá A kódà nígbàtí kò wù ọ́ ṣe, tàbí nígbàtí ọwọ́ rẹ kún fún iṣẹ́, Òun yíó sí san ọ l'ẹ́san ìjẹ́ olódodo rẹ." Bíbélì sọ pé, "Ìbùkún ni fún àwọn tí ńpa ẹ̀rí Rẹ̀ mọ́, tí sì ńwá A kiri tinú-tinú gbogbo." Sáàmù 119:2

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Boyd Bailey pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Wisdom Hunters fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.wisdomhunters.com/