Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ - Ọgbọ́nÀpẹrẹ
Ìbẹ̀rù Ọlọ́gbọ́n
Àwọn ìbẹ̀rù ka n wà tí ó dára. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan nínú wọn. Èyí tí ó jé ìpìnlẹ̀. Tí ó jé gbòǹgbò fún àwọn ìbẹ̀rù ̣míràn tí ó dára. Ọlọ́gbọ́n ni ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó fi bíbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ìgbàgbọ́ rẹ íbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ oun tí ó gbóná. Èyí ni ipele ìgbà ìmọra lẹ́yìn ìgbéyàwó pẹ̀lú Kristi. Ó kò mọn ohun tí ó dára làti ṣe nígbà náà ju èyí tí o ní láti ṣe. Àmọ́ tí kò bá sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ó ma mú kí o di ẹni tí ó ṣe àìgbọràn (Psalm 36:1). Bí àwọn ìgbàgbọ́ tàbí ìmọ̀ míràn, bíbẹ̀rù ̣ Ọlọ́run ní ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn. Ìbẹ̀rù ̣Ọlọ́run á sọ ẹ di ènìyàn tí ó ní òtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ àti pẹ̀lú ara rẹ. Òhun ní ìbẹ̀rẹ̀ láti lè ma mú ara rẹ ṣe ojúṣe tí ó yẹ. Ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run-láìsí ìbẹ̀rù Ọlọ́run-je ohun tí kí ṣe òtító. Kò le sí ore ọ̀fẹ́ láìsí ìbẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìbẹ̀rù láìsí ore ọ̀fẹ́. Asiwèrè ni ẹni tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run. Èso àìní ìbẹ̀rù ní inú Ọlọ́run ni ṣíṣe ìpinnu tí kò dára ati gbígbé ìgbésí ayé tí kò dára.
Ní ìtàsí-iwájú, àṣeyọrí Jẹ́ ọ̀tá sí ibẹru Ọlọrun. Iye ìwọ̀n gbà tí ó bá ṣe àṣeyọrí bẹẹni ó ma yára láti má ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Àmọ́, ní ìdà kejì ó yẹ kí ó jé òtítọ́. Bí gbádùn àṣeyọrí rẹ bá ṣe pọ̀ sí bẹẹni o ní lò láti ní ìbẹ̀rù nínú Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù àwọn ipa èrè èsẹ̀. Àṣeyọrí, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, máa fún ọ ní òmìnira. Ìgbà yíì ní àsìkò tí o yẹ láti ṣe ìṣirò ara rẹ. Sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ fún ara rẹ. O le ṣe olùdarí òmìnira rẹ laáyì ṣe ìṣirò ara rẹ. Dáfídì kò le sé, ó sì jẹ́ ẹni bí ọkàn Ọlọ́run(Acts 13:22). Òmìnira láìsí ànfàní láti ṣe ìṣirò bí o ṣé wu ìwà máa yọrí sí oríṣiríṣi ìpinnu tí kò dára, èyí tí ó le mú ìgbé ayé ìwà tí kò mọ́n nígbà tí kò bá sí àyẹ̀wò. Kò sí ẹni tí ó gaju òfin bẹẹni kò sí ẹni tí ó gaju máa ṣe ìṣirò ìwà.
Ọlọgbón ni aṣáájú tí ó ṣe àgbérò ìṣirò sínú ìgbàgbó rẹ̀, ètò ìnáwó, ẹbí, iṣẹ́, àti ìsinmi. Àwọn tí kò rò pé wọ́n nílò rẹ̀ ni wọ́n nílò rẹ̀ jùlọ. Bóyá o bẹ̀rẹ̀ nípa gbígba èni tí ẹ jọ jẹ́ abo kàn náà sí iṣẹ́ láti jé olùràn lọ́wọ́ tí ó máa wà pẹ̀lú rẹ ní ibi iṣẹ́ àti láti rin àwọn ìrìn àjò tó jọ mọn iṣẹ́. Èyí máà fún ọ ní ànfàní láti jẹ́ olùtọ́jú àti olùdarí ẹni náà, tí ó maa jẹ́ adarí lọ́jọ́ ọ̀la, ati pe o jẹ anfani fún obìnrin tàbí ọkùnrin náà láti mú ọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó máa ṣe ìṣirò fún. Gbogbo wa máa ṣe dáradára jùlọ nígbàtí àwọn ẹlòmíràn bá wò wá. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run máa jẹ́ kí o mọ́lẹ̀ (Exodus 20:20). Gba ìṣirò láti ọ̀dọ̀ ìyàwó tàbí ọkọ rẹ, Ìgbìmọ̀, ọ̀gá àti ẹgbẹ́ rẹ. Jẹ́ olóòótọ́ ní ibi iṣẹ́ tàbí fún ara rẹ nínú ètò ìnáwó. Sọ fún ọkọ tàbí aya rẹ nígbà tí ọkàn rẹ bá fẹ́ràn ẹlòmíì. Jẹ́ olódodo sí ara rẹ nígbà tí ìwọ nìkan bá dá wà. Àìṣiṣẹ́ mọ́ ń yọrí sí oríṣiríṣi èrò. O jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ̣ nígbà tí o bá tọ́jú ìdánìkanwà fún Olùgbàlà rẹ, ọkọ tàbí aya rẹ, àti àwọn ọ̀rẹ́ àkànṣe. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ọ̀rẹ́ rẹ. Ìbẹ̀rù àwọn èrè ti ẹṣẹ leè mú wá jẹ́ eni ọlọgbón. Ìbẹ̀rù láti jé eni tí kò le ṣe ìṣirò jẹ́ ọlọgbọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run máa tú ni sílè. Nítorí náà, bẹ̀rù Ọlọ́run, kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.
Fún irú àwọn ẹ̀kọ́ báyìí siwíwá ọkàn Ọlọ́run lójoojúmọ́,Lọ sí:
Nípa Ìpèsè yìí
Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ jẹ́ ètò ẹ̀kọ́ kíkà ọlọ́jọ́ 5 tí a ṣètò rẹ̀ láti ru 'ni sóké, pe'ni níjà àti láti ràn wá lọ́wọ́ lójú ọ̀nà ìgbé-ayé ojoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí Boyd Bailey ṣe sọ, " Wá A kódà nígbàtí kò wù ọ́ ṣe, tàbí nígbàtí ọwọ́ rẹ kún fún iṣẹ́, Òun yíó sí san ọ l'ẹ́san ìjẹ́ olódodo rẹ." Bíbélì sọ pé, "Ìbùkún ni fún àwọn tí ńpa ẹ̀rí Rẹ̀ mọ́, tí sì ńwá A kiri tinú-tinú gbogbo." Sáàmù 119:2
More