Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ - Ọgbọ́nÀpẹrẹ

Seeking Daily The Heart Of God - Wisdom

Ọjọ́ 1 nínú 5

Àwọn tí ń wá Ọgbọ́n

Ọgbọ́n jẹ́ ohun tó ṣe iyebíye. Àwọn ènìyàn maá ń fà sí ibi tí ọgbọ́n wà. Ó jẹ́ ohun tí ó fa ni mọ́ra tí ó sì wuyì púpọ̀. Ọgbọ́n dúró bíi ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí náà iye rẹ̀ kọjá sísọ. Ọgbọ́n jẹ́ ìdí kan tí a fi ń lọ sí ilé ìjọ́sìn, t'ẹ́tí sí ẹ̀kọ́ Bíbélì tó yanrantí, àti tàkurọ̀sọ pẹ̀lú atọ́nisọ́nà ẹni. A ní láti wá ọgbọ́n kí á sì bèèrè fún un. Kìí wá fúnrarẹ̀, ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Ọgbọ́n ṣ'ọ̀wọ́n, ó sì ṣe iyebíye. Ó jẹ́ ẹ̀bùn tí ń pa ni mọ́ lọ́wọ́ àwọn ìpinnu tí o lè máa fòòró ẹni títí ayé, ó sì tún fún wa ní ìgboyà láti tẹ̀síwájú tàbí d'áwọ́ dúró. Ọgbọ́n jẹ́ ohun ìjà tí Ọlọ́run ńlò fún àwọn jagunjagun Rẹ̀. Ọgbọ́n á mú ìpòrúurù ọkàn kúrò, à sì fi òye kooro dípò rẹ. Ó máa ń sọ ìpinnu di àṣeyọrí. Ó máa ń kìlọ̀ ibi tí ń bọ̀.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọlọgbọ́n, kò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọgbọ́n ọkúnrin tàbí obìnrin gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ń jínhìn - ní sàn-án sàn-án. Lóòtọ́, ọlọgbọ́n a máa jìn s'ọ́fìn ìgbéraga (Jeremáyà 9:23). Ọkàn ọgbọ́n tó kún fún ìgbéraga a máa rò pé òun lè ga jú àkóso lọ. Èyí lè má farahàn ní ìbẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n gbòǹgbò rẹ̀ nínú lóhùnún á bẹ̀rẹ̀ síí rinlẹ̀ bíi ìpìlẹ ilé tí ikàn mú. Bí a kò bá dá ìgbéraga lọ́wọ́ kọ́, yíó sọ ọgbọ́n di àfojúdi. Ìbànújẹ́ ló jẹ́ pé ọlọgbọ́n adarí kan nígbà kan rí jẹ́ kí ìgbéraga t'ẹrí ìbẹ̀rù Ọlọ́run bá nínú òun. Ọgbọ́n ni ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ń gbé ètò Ọlọ́run lárugẹ. Bí a bá lò ó fún ara wa, á di ohun àdánìkànjọpọ́n.

Nítorí náà wá ọlọgbọ́n tòótọ́ tí ìlépa rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run nìkan. Ọgbọ́n àdábọwọ́ ń kùnà níti ohun tí ẹ̀mí ṣùgbọ́n ọgbọ́n mímọ́ a máa fúnni ní ìyè tí ẹ̀mí. Ọgbọn—pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgbọnràn sí Ọlọ́run—ní ń pèsè wa sílẹ̀ láti ṣe àṣeyege. Ọgbọ́n tó jẹ́ ojúlówó ló dára fún gbogbo ìgbà. Wá a rí nínú Bíbélì, ìwé, ènìyàn, ipòkípò, eré-ìtàgé, ìrírí-ayé, àti ẹ̀dá. Lọ́gán tí o bá ti rí, má fi ṣ'eré rárá. Dúpẹ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àṣeyọrí rere. Lòó fún ògo Rẹ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀. Jẹ́ kí ọgbọ́n kún ọ fún ìrẹ̀lẹ̀ dípò kí ó mú ọ gbéraga. Gbogbo wa ni à ń wá ọgbọ́n Ọlọ́run. A ó máa wá a títí a ó fi dé ọ̀run ni.

Ọgbọ́n n'ítara, ó wà láàyè, ó sí níílò ìmísí ọ̀tun l'átọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Lo àdúrà gẹ́gẹ́ bíi àtẹ̀gùn sí ọgbọ́n Ọlọ́run. Bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ ní gbogbo ìgbà fún ìwòyè àti ọkàn Rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. Gba ọgbọ́n láàyè láti fà ọ́ súnmọ́ Bàbá rẹ tí ń bẹ l'ọ́run nínú ìjọsìn àti ìgbáralé E. L'ọ́pọ̀ ìgbá máa fí àwọn èròǹgbà rẹ jìn fún Un. Fi Bàbá rẹ tí ń bẹ l'ọ́run ṣe olùdámọ̀ràn fún ìpinnu ọlọgbọ́n.

Jẹ́ ẹni tí ọgbọ́n ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde sí àwọn ẹlòmíràn, fi ààyè sílẹ̀ fún ènìyàn láti mọ inú rẹ, kí o sì ní òye ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ti fi sí ojú ọ̀nà ìgbàgbọ́ rẹ. Gbogbo wa ni a ní ọgbọ́n tí a lè fi fún ẹlòmíràn. Kàn wá ààyè láti t'ẹ́tí sí ẹ̀dùn ọkàn elòmíràn. Ohun tí "ó jẹ wọ́n l'ógún jù" níílò àmójútó. Wà níbẹ̀ láti t'ẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ pẹ̀lú òye, àti nínú ìwàpẹ̀lẹ́, wa, kí o sì wá ojútùú sí i fún won. Ọgbọ́n ní ìwà tútù. Á fi ìdáhùn sí ohun gbogbo pẹ̀lú ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ bí a bá bèèrè bí i ẹni tí ń wa ọgbọn pẹ̀lú.

Wá ọgbọ́n, kí o sì fúnni ní ọgbọ́n—ọgbọ́n tí a ru s'ókè nípa ìṣépáṣẹ́sẹ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ fún Ọlọ́run.

Fún àwọn ètò ìjọsìn síi láti Seeking Daily the Heart of God, kàn sí: https://www.wisdomhunters.com/

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Seeking Daily The Heart Of God - Wisdom

Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ jẹ́ ètò ẹ̀kọ́ kíkà ọlọ́jọ́ 5 tí a ṣètò rẹ̀ láti ru 'ni sóké, pe'ni níjà àti láti ràn wá lọ́wọ́ lójú ọ̀nà ìgbé-ayé ojoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí Boyd Bailey ṣe sọ, " Wá A kódà nígbàtí kò wù ọ́ ṣe, tàbí nígbàtí ọwọ́ rẹ kún fún iṣẹ́, Òun yíó sí san ọ l'ẹ́san ìjẹ́ olódodo rẹ." Bíbélì sọ pé, "Ìbùkún ni fún àwọn tí ńpa ẹ̀rí Rẹ̀ mọ́, tí sì ńwá A kiri tinú-tinú gbogbo." Sáàmù 119:2

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Boyd Bailey pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Wisdom Hunters fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.wisdomhunters.com/