Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ - Ọgbọ́nÀpẹrẹ
Ipe fún Ọgbọ́n
"Èyí nílò ọgbọ́n" (Ìfihàn 13:18a). Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a nílò ọgbọ́n ju bí a ṣe rò lọ. Ọgbọ́n máa ń jẹ́ kí ènìyàn mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹni, àti láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. “Kíló bá ọgbọ́n mu láti ṣe?” jẹ́ ìbéèrè tó ṣe kókó ni nígbàtí a bá wà ní ìkòríta ìpinnu. “Kí ló dára jù lọ fún ìdáwọ́lé náà?” jẹ́ ìbéèrè ọlóọgbọ́n tí a lè béèrè nípa iṣẹ́-ajé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run ma ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ owó níní tàbí àìní owó lọ́wọ́. Nítorí náà, bí owó kò bá tó nǹkan, a gbọ́dọ̀ fọgbọ́n lo èyí tó wà. Ọgbọ́n máa kọ́ wa láti dín ìnáwó kù, kí a má sì náwó ju bó ṣe yẹ lọ. Ní ìkòríta yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àìní-ìgbàgbọ́. Ohun tó à ńsọ ni wípé kí o jẹ́ ìríjú ọlọgbọ́n pẹ̀lú àwọn ǹkan tó wà ní ìṣàkóso rẹ, kí a tó lè jẹ́rìí rẹ pẹ̀lú ọrọ̀ díẹ̀ si. Àwọn tó lawọ́ nípa ìfifúnni a máa fà súnmọ́ àwọn ìríjú ọlọgbọ́n.
Àwọn ọlọ́gbọ́n kì í ṣe aláìnísùúrù tàbí aláìnírètí. Ọgbọ́n a máa múni ṣọ́ ẹsẹ̀ gbé, a sì múni farabalẹ̀ ṣe àgbéyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí a tó ṣe ohunkóhun. Ǹjẹ́ o máa ń wá ọgbọ́n nígbà gbogbo? Tá a bá ní ìmọ̀ àti ìrírí, tá a sì ní òye àti ìfòyemọ̀, wọ́n máa jẹ́ kí a ní ọgbọ́n. Ọgbọ́n nííṣe pẹ̀lú ìgbìyànjú wa láti mọ ìrísí Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Ìdí lèyí tí ọgbọ́n tí a fà yọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wúlò gidigan fún ìgbésí ayé wa.
Bíbélì jẹ́ ìṣúra ọgbọ́n tó ń dúró de ẹni tó bá ń wá ọgbọ́n. Nítorí náà, má kàn gbàdúrà, kà tàbí ṣe àṣàrò lórí Bíbélì lásán, àmọ́ pẹ̀lú pẹ̀lú rẹ̀ wá ọgbọ́n (Mátíù 12:42).Wá àwọn tó ní irun funfun, àwọn tó ní ìhùwàsí ọgbọ́n. Àwọn ọlọ́gbọ́n yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ìwúlò àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí o ti rí gbà mú lákòókò àṣàrò Ìwé Mímọ́. Máa ka ìwé, kó o sì máa gbọ́ àwọn ìwàásù àti ọ̀rọ̀ ìyànjú tó ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n. Tí o bá ń bá ọgbọ́n rìn fún ìgbà pípẹ́, ó máa padà ràn mọ́ ọ. Máa lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti wá ọgbọ́n. Máa fi ọgbọ́n bá àwọn èèyàn lò. Máa fọgbọ́n ṣe àmúlò owó àti àkókò rẹ. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, ọgbọ́n rẹ á ti mú kí àwọn tó ńṣe ìpòǹgbẹ fún ọgbọ́n bíi tìrẹ fà súnmọ́ ọ.
Yàtọ̀ síyẹn, ìbẹ̀rù Olúwa ni ohun iyebíye tó dé ọgbọ́n l'ádé. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n àwọn arìndìn tẹ́ńbẹ́lú ọgbọ́n àti ìbáwí (Òwe 1:7). Ìbẹ̀rù Ọlọ́run á jẹ́ kí o ní ọgbọ́n. Bí o kò bá bẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn túmọ̀ sí pé o kò ní ọgbọ́n. Abájọ tí ayé yìí fi kún fún àwọn òpònú. A ò bẹ̀rù Ọlọ́run mọ́, ọgbọ́n sì ti rìn jìnà sí wa. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ ibi tí ọgbọ́n ti ń dàgbà. Ọlọ́run a máa bu omi ọgbọ́n rin àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀.
Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ bẹ̀rù Rẹ̀. Jọ́sìn sí Ọlọ́run, àmọ́ bẹ̀rù Rẹ̀. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, àmọ́ bẹ̀rù Rẹ̀. Ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run, àmọ́ bẹ̀rù Rẹ̀.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí o ní ló mú ọ pójú òṣùwọ̀n fún ọgbọ́n. Má ṣe súnmọ́ Ọlọ́run débi pé o kòní bẹ̀rù Rẹ̀ mọ́. Èyí jẹ́ àìmọye èyí tí máa ń yọrí sí ìwà òmùgọ̀. Ọgbọ́n ń retí ìgbà tí o ma wa kórè rẹ̀. Ká a kí o sì jẹ̀gbádùn rẹ̀, bí èso aládùn tó ti pọ́n, tó sì fani mọ́ra nígbà ẹ̀rùn. Tọ́ ọ wò, kí o sì ríi wípé ọgbọ́n dára. Kò sẹ́ni tó ti ṣàròyé rí wípé òun ní ọgbọ́n àpọ̀jù. Lépa ọgbọ́n lóòrè-kóòrè. Se àwárí àwọn ọlọ́gbọ́n, kí o sì béèrè ọgbọ́n lọ́wọ́ wọn àti lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Èyí ni ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe.
Nípa Ìpèsè yìí
Wíwá Ọkàn Ọlọ́run Lójoojúmọ́ jẹ́ ètò ẹ̀kọ́ kíkà ọlọ́jọ́ 5 tí a ṣètò rẹ̀ láti ru 'ni sóké, pe'ni níjà àti láti ràn wá lọ́wọ́ lójú ọ̀nà ìgbé-ayé ojoojúmọ́. Gẹ́gẹ́ bí Boyd Bailey ṣe sọ, " Wá A kódà nígbàtí kò wù ọ́ ṣe, tàbí nígbàtí ọwọ́ rẹ kún fún iṣẹ́, Òun yíó sí san ọ l'ẹ́san ìjẹ́ olódodo rẹ." Bíbélì sọ pé, "Ìbùkún ni fún àwọn tí ńpa ẹ̀rí Rẹ̀ mọ́, tí sì ńwá A kiri tinú-tinú gbogbo." Sáàmù 119:2
More