Ọlọ́gbọn na ha da? akọwe na ha da? ojiyan aiye yi na ha da? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n aiye yi di wère? Nitoripe ninu ọgbọ́n Ọlọrun niwọnbi aiye kò ti mọ̀ nitori ọgbọ́n, o wù Ọlọrun nipa wère iwasu lati gbà awọn ti o gbagbọ́ là. Nitoripe awọn Ju mbère àmi, awọn Hellene si nṣafẹri ọgbọ́n: Ṣugbọn awa nwasu Kristi ti a kàn mọ agbelebu, ikọsẹ̀ fun awọn Ju, ati wère fun awọn Hellene, Ṣugbọn fun awọn ti a pè, ati Ju ati Hellene, Kristi li agbara Ọlọrun, ati ọgbọ́n Ọlọrun. Nitoripe wère Ọlọrun gbọ́n jù enia lọ; ati ailera Ọlọrun li agbara jù enia lọ. Ẹ sa wo ìpè nyin, ará, bi o ti ṣepe kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọ́gbọn enia nipa ti ara, kì iṣe ọ̀pọ awọn alagbara, kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọlá li a pè: Ṣugbọn Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọ́n; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara; Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan: Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀. Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa
Kà I. Kor 1
Feti si I. Kor 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 1:20-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò