Gbígba Ayọ̀ Rẹ PadàÀpẹrẹ

Recovering Your Joy

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ìgbọràn ni Àṣírí Ayọ̀

Ka Ẹkùn Jeremáyà 3:40.

Ayọ̀ jẹ́ nǹkan tó rọrùn láti sọnù, ṣùgbọ́n bákannáà ó rọrùn láti gbà padà. Lẹ́yìn tí o ti gbà pé o ti sọ ayọ̀ rẹ nù, o nílò láti ṣe àyẹ̀wò kí ló fa sábàbí. O nílò láti wo ayé rẹ kí o sì bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ, “Báwo ni mo ṣe sọ ayọ̀ mi nù? Kíni o ń jà mí lólè ayọ̀ mi?”

Bíbélì sọ fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà kí á yẹ ayé wa wò. Ẹkùn Jeremáyà 3:40 sọpé, “Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ.” (NLT).

Ogunlọ́gọ̀ abaniláyọ̀jẹ́ ló wà láyé, ṣùgbọ́n méjì tó wọ́pọ̀ jùlọ tí mo rí nínú àwọn ènìyàn ni àìní òdiwọ̀n tó tọ́ fún ètò ìgbòkègbodò àti àìṣe-àmúlò ẹ̀bùn abímọ́. O ní lò láti ṣe ọgba láàrín ìsinmi àti iṣẹ́, oun tí ò ń fi jìn àti oun tí ó ń jáde. O sì nílò láti lo ẹ̀bùn abímọ́, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó ta ẹ́ yọ, bíbẹ́ẹ̀kọ́ oó yíò dàbí pé ẹmí fẹ́ pin. Mú iye ìdá nínú ọgọ́rùn-ún ẹ̀bùn abímọ́ rẹ tí o kò lò lẹ́nu iṣẹ́ fi ṣe iṣẹ́ ìsìn. Tí o bá ń ṣiṣẹ́ tí kò lo ìdá méèdógbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ẹ̀bùn rẹ, kúrò ní bi iṣẹ́ náà.

Ní kété tí o bá ti mọ bí o ṣe sọ ayọ̀ rẹ nù, o nílò láti ṣe àtúnṣe oun tí bà jẹ́.

Ǹjẹ́ o mọ oun tí yóò jà ọ́ lólè ayọ̀ rẹ ní kíákíá ju ohunkóhun lọ? Nígbàtí o bá mọ oun tó tọ́ láti ṣe tí o kò ṣe é.

Bíbélì sọ nínú ìwé Jákọ́bù 4:17, “Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.”

Jẹ́ kí n bi ọ́: Kíni o nílò láti máa ṣe tí o kò ṣe? Kíni oun tí Ọlọ́run sọ fún ọ láti ṣe tí o kò ì tíì máa ṣe?

Àṣírí sí ayọ̀ yanturu tí kò lópin ni ìgbọràn. Ó túmọ̀sí ṣiṣẹ́ oun tí Ọlọ́run sọ fún ọ láti ṣe. Gbogbo ìgbà tí o bá ṣe oun tí, ayé rẹ yóò kún fún ayọ̀.

Oó kún fún ayọ̀ pẹ̀lú nígbàtí o bá ronú àwọn oun tí o dára ní ayé rẹ. Dáfídì sọpé nínú Orin-Dáfídì 126:3, “Oluwa ti ṣe oun ńlá fún wa, nítorí náà àwa ayọ̀ ” (BYO). Bí o bá ṣe ń tẹ pẹlẹ mọ́ oun tí Ọlọ́run ti ṣe fún ọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ayọ̀ tí o òní ní ayé rẹ. Kílódé? Nítorí tí óún ṣe okùnfà ìmọ̀ore. Àti pé irú fẹ́ ọkàn tó mọ ore ni o jẹ́ ọ̀kan to wa ní alafia jùlọ.

Tí o bá fẹ́ gba ayọ̀ rẹ padà, àkọ́kọ́ o nílò láti gbà pé ó ti lọ, lẹ́yìn èyí ṣe àyẹ̀wò kí ló fa sábàbí. Lẹ́yìn náà, ṣe àtúnṣe oun tí dẹnu kọlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀wù ìmọ̀ore wọ̀. Ni ẹ̀kọ́ tó tẹ̀lé èyí, aó sọ nípa ìpele mẹ́ta tó kù láti gba ayọ̀ rẹ padà.
Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Recovering Your Joy

Tí o bá ún fẹ́ ayọ̀ ní ayé rẹ́, o nílò láti wá àyè ọgba lóríi ètò ìgbòkègbodò rẹ. Olùṣọ́-àgùntàn Rick bá wa pín bí a ti ṣe le ṣe àtúntò oun tí à ń fi jìn àti oun tí ó ń jáde kí ififún rẹ àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ lè ràn ọ lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ rẹ padà dípò kí o sọ ọ́ nù.

More

A kọ ètò ìfọkànsìn yí © 2014 látọwọ́ Rick Warren. Òfin sì de ṣíṣe àmúlò rẹ̀. O ní láti tọrọ gáfárà kí o tó lò ó.