Gbígba Ayọ̀ Rẹ PadàÀpẹrẹ

Recovering Your Joy

Ọjọ́ 2 nínú 5

Ayọ̀ Oun Tó Wù Kó Dé

Ka Fílípì 4:6.

O ní ìdí tó ṣe kókó fún ayọ̀ ní ayé rẹ. Ayé tí kò ní ayọ̀ a máa wọni lọ́rùn, di ẹrù pani, a máa ni ni lára. Ìwádìí fi hàn dájú pé bí ayọ̀ bá ṣe kún inú ẹni sí ni ènìyàn fi ń ṣe àṣeyọrí síi. Mo ka àkọsílẹ̀ kan ninu ìwé ìròhìn "US News and World Report" (Ìròhìn Ìlú Amẹ́ríkà ati Orílẹ̀ Ayé) tó sọpé àwọn ilé iṣẹ́ ńlá ma ń gbà àwọn "olùdámọ́ràn ayọ̀" láti rú ayọ̀ sókè nínú àwọn òṣìṣẹ́ kí wọ́n baà lè ṣiṣẹ́ gaara ga síi. Òtítọ́ ni pé ènìyàn kún fún okun síi, ọgbọ́n àti dá nǹkan síi, àti ṣíṣe àṣeyọrí síi tí ayọ̀ bá wà nínú ènìyàn.

Nínú ìwé ṣókí sí àwọn ará Fílípì — orí mẹ́rin péré lóní — Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ “ayọ̀” ní ìgbà mẹ́rindínlógún. Oun tí ó yani lẹ́nu nipé, Pọ́ọ̀lù kò kọ ìwé yìí nígbàtí óún jẹ̀gbádùn ìsinmi ní ìlú Caribbean. Inú túbú ní Róòmù lówa, tí óún dúró de ìdájọ́ ikú. Nígbàtí ayé rẹ̀ ṣókùnkùn, nígbà náà ni ó kọ ìwé tí ó dáni lójú jùlọ nínú Bíbélì.

Nínú Fílípì, Pọ́ọ̀lù fún wa ní ohun mẹ́fà tí ó ń rú ayọ̀ sókè tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti paná ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tí yóò sì gbé ọkàn tó tẹ̀ ba sókè. Láti lè rántí àwọn ohun mẹ́fà yí, a mu gbólóhùn ní èdè Gẹ̀ẹ́sì lò — JOYFUL (Aláyọ̀). A ó wo mẹ́ta nínú rẹ̀ báyìí.

J: Gbàgbé gbogbo àwọn àbámọ àtẹ̀yìnwá.
“Jettison” ní èdè Gẹ̀ẹ́sì túmọ̀sí “kí ènìyàn da ohun tí kò níye lórí nù, kí ènìyàn paárẹ́, kí ènìyàn má ni oun ṣe pẹ̀lú rẹ̀.” Pọ́ọ̀lù sọpé tí o bá fẹ́ gbádùn ayé rẹ, àwọn nkan wà tí o nílò láti mú kúrò nítorí wọ́n ń rìn ọ́ mọ́lẹ̀ wọn á di ẹrù pa ayé rẹ. Bíbélì sọ pé kí o gbàgbé àwọn àbá mọ̀, nítorí oun tí Ọlọ́run Ńṣe nìyẹn that's what — Ó yàn láti dárí àṣìṣe rẹ jìn tí ó bá jẹ́wọ́ wọn. Ibi ìbẹ̀rẹ̀ ayọ̀ ni kí á fi oun àtijọ́ sílẹ̀. Fílípì 3:13 sọpé, “Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú.” (BYO).

O: Yọ àwọn àníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la sílẹ̀.
Tí o bá fẹ́ gbádùn ìsinsìnyí, o gbọ́dọ̀ yọ àwọn àníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la sílẹ̀. Àníyàn, láì jiyàn, ni olórí oun tó ún pa ayọ̀ jùlọ. O lè jẹ́ aláyọ̀ bákan náà kí o tún kún fún àníyàn ṣíṣe. Aporó Pọ́ọ̀lù ni ẹsẹ̀ Bíbélì yí: “Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. ” (Fílípì 4:6 BYO). O le è máa ṣàníyàn tàbí kí o gbàdúrà.

Y: Fi ara rẹ jìn sí Ifè Ọlọ́run.
Tí o bá ti ń yà bàrà, tí o bá mọ ibi tí o ti wá tàbí ibi tí òún lọ tàbí ìdí tí o fi wà níbí, láì ṣiyèméjì o kò lè ní ayọ̀ ní ayé rẹ. Gbogbo wa ló nílò oun kan gbógì tí ó jù wá lọ tí à ń gbé ayé fún. Èyí ló mú ayọ̀ wá fún wa. Gbígbé ayé fún ara wa kò lè mú ayọ̀ wá.

Pọ́ọ̀lù pàápàá nígbàtí o jọ pé ó ti sọ oun gbogbo nù, oun kan wà tí a kò le gbà lọ́wọ́ rẹ̀ — èrèdí rẹ̀láyé. Pọ́ọ̀lù sọpé nínú Fílípì 1:21, “Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi.” (BYO).

Tí o bá ń fẹ́ ìgbé ayé tó kún fún ayọ̀, o nílò láti to ayé rẹ dọ́gba pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run fún ayé rẹ. Nígbàtí o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ayé ní ìlànà ète tí a fi dá ọ, ayé yóò túbọ̀ ní ìtumọ̀, ayọ̀ yóò wá bọ́ ṣí àrọwọ́tó.
Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Recovering Your Joy

Tí o bá ún fẹ́ ayọ̀ ní ayé rẹ́, o nílò láti wá àyè ọgba lóríi ètò ìgbòkègbodò rẹ. Olùṣọ́-àgùntàn Rick bá wa pín bí a ti ṣe le ṣe àtúntò oun tí à ń fi jìn àti oun tí ó ń jáde kí ififún rẹ àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ lè ràn ọ lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ rẹ padà dípò kí o sọ ọ́ nù.

More

A kọ ètò ìfọkànsìn yí © 2014 látọwọ́ Rick Warren. Òfin sì de ṣíṣe àmúlò rẹ̀. O ní láti tọrọ gáfárà kí o tó lò ó.