Gbígba Ayọ̀ Rẹ PadàÀpẹrẹ

Recovering Your Joy

Ọjọ́ 5 nínú 5

Pín Ayọ̀ Ìgbàlà Rẹ

Ka Éfésù 2:10.

Tí o bá fẹ́ gba ayọ̀ rẹ padà, o nílò láti 1) gbàpéótilọ, lẹ́yìn náà 2) ṣàwárí kíló fàá. Lẹ́yìnnáà, 3) ṣàtúnṣeoun tódé, paríparí 4) gbé ẹ̀wù ìmọ̀ore wọ̀.

Ó ku ìgbésẹ̀ mẹ́ta síi tí a ó wò nínú ẹ̀kọ́ yìí lóríi gbígba ayọ̀ rẹ padà.

Àkọ́kọ́, o nílò láti lo àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run lojojúmọ́.

Ó ṣòro láti rò wípé Ọlọ́run Ń fẹ́ láti lo àkókò pẹ̀lú rẹ. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan tó ń lọ lọ́wọ́, à bí bẹ́ẹ̀ kọ́? Káàkiri inú Ìwé Mímọ́, Ọlọ́run pè wá kí á wá sí ọ̀dọ̀ Òhun. Ayọ̀ kán ń bẹ tí a bá lo àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run ní àkókò ìdákẹ́jẹ́ ojojúmọ́, nítorí aó kọ́ bí a ti ún gbọ́ ohùn Rẹ̀ aó sì mọ oun tí Ó fẹ́ ká fi ayé wa ṣe. Bí àkókò tí ò un lò pẹ̀lú Ọlọ́run bá ṣe pọ̀ sí, bẹẹ̀ni ìdọ̀rẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀ yóò ṣe jinlẹ̀ si.

Ìkejì, o nílò láti wá ọ̀nà làti fi fúnni padà. Bíbélì sọ nínú Éfésù 2:10: “Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe” (BYO). Ní àkókò tó nira, ó rọrùn dáadáa láti jẹ́ alánìkànjọpọ́n. Ṣùgbọ́n òtítọ́ nipé, bí o bá ṣe ń kọjú sí ti ará rẹ nìkan sí ní ayọ̀ rẹ yóò máa nù ọ́.

Mo ti rin ìrìn àjò káàkiri gbogbo ayé, mo sì ti dé àwọn ìlú tí kò gba àlejò tí wọ́n sì ń ṣe àtakò sì àwọn tó fi ìgbàgbọ́ wọn sínú Jésù Kríístì. Ǹjẹ́ o mọ oun tí mo ti ṣàwárí? Àwọn onígbàgbọ́ tí à ń ṣe àtakò sí ní ó ní ayọ̀ jùlọ láyé. Kínìdí? Nítorí pé ó ní ìtumọ̀ sí wọn. Wọn kò kín ṣe onígbàgbọ́ ṣáá, onígbàgbọ́, “gbáà tàbí Júù sílẹ̀.” Ẹ̀tọ́ láti sìn àti òmìnira nínú Kríístì ní ìtumọ̀ sí wọn. Wọ́n sì ní ayọ̀ tó kún.

O nílò láti wá ọ̀nà làti fi fúnni padà. Ní kété tí o bá ti mójú kúrò ní ti ará rẹ nìkan, o rí ayọ̀ rẹ tí ó ún padà.

Ní àkótán, láti gba ayọ̀ rẹ padà, o nílò láti sọ fún ènìyàn kan nípa Jésù.

Kò sí ohun tó lè mú ayọ̀ rẹ padà kíá bíi kí o ní ẹ̀dùn ọkàn fún ìgbàlà ọ̀rẹ́ kan. Bíbélì sọ pé gbogbo ìgbà tí ẹnikẹ́ni bá gba Olúwa, wọ́n ń ṣe àjọyọ̀ ní Ọ̀run. Ǹjẹ́ o mọ èyí? Lúùkù 15:7 sọpé, “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà” (BYO). Ní ọjọ́ tí o fo ìlà kọjá, wọ́n ṣe àpéjọ ní Ọ̀run nítorí rẹ. Pẹ̀lú, ní ọjọ́ tí o bá ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti mọ Olúwa, àjọyọ̀ yóò wá ní ọkàn rẹ. Ayọ̀ náà ń padà bí o ṣe ń pín Pẹ̀lú ẹlòmíràn.

Gba àdúrà yí lónìí: “Bàbá, ràn mí lọ́wọ́ kí ń le fi ìfẹ́ san inúnibíni, ayọ̀ dípò ìbánújẹ́, àti ìkáàánú dípò àìníìtara. Kí ayọ̀ Ọlọ́run fi ara hàn tó bẹ́ẹ̀ lójú mi tí àwọn ènìyàn yóò fi fẹ́ mọ ìdí àti ìrètí tí ó wà nínú mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ràn sí oun tí O ti sọ fún mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti kọjú sí àwọn ìbùkún Rẹ láyé mi kín n ba lè ní ẹ̀mí ìmọ̀ore níti òdodo Rẹ. Dá ayọ̀ ìgbàlà mi padà kín n ba lè pín ayọ̀ yí pẹ̀lú àwọn míràn kín n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá ayọ̀ ti wọn náà nípa àjọṣe pọ̀ pẹ̀lú Rẹ. Ẹ ṣeun pé mo ní ìrètí àti ayọ̀ nínú Jésù Kríístì. Àmín.”

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Recovering Your Joy

Tí o bá ún fẹ́ ayọ̀ ní ayé rẹ́, o nílò láti wá àyè ọgba lóríi ètò ìgbòkègbodò rẹ. Olùṣọ́-àgùntàn Rick bá wa pín bí a ti ṣe le ṣe àtúntò oun tí à ń fi jìn àti oun tí ó ń jáde kí ififún rẹ àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ lè ràn ọ lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ rẹ padà dípò kí o sọ ọ́ nù.

More

A kọ ètò ìfọkànsìn yí © 2014 látọwọ́ Rick Warren. Òfin sì de ṣíṣe àmúlò rẹ̀. O ní láti tọrọ gáfárà kí o tó lò ó.