Gbígba Ayọ̀ Rẹ PadàÀpẹrẹ

Recovering Your Joy

Ọjọ́ 1 nínú 5

Gbádùn Ayé Rẹ

Ka Tímótì Kínní 6:17.

Ó ṣeéṣẹ kí o wà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnira báyìí nítorí bí ọrọ̀ ajé ti rí, síbẹ̀ Ọlọ́run fẹ́ kí o gbádùn ayé rẹ.

Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, o le è gbádùn ayé rẹ nítorí ọkàn rẹ mọ́. O le è gbádùn ayé rẹ nítorí ayé rẹ́ dájú nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. O le è yọ̀ kí o sì rín ẹ̀rín nínú ilẹ̀ ìjọsìn. O le è gbádùn àwọn ọ̀rẹ́ tí kò ní lù ọ́ ní jìbìtì nítorí àwọn náà ńkọ́ láti dàbíi Jésù, èyí sì túmọ̀ sí pé àwọn náà n kó ẹ̀kọ́ láti wá ìfẹ́ ti ọmọnìkejì ṣáájú.

Óṣeniláàánú, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni kò fẹ́ gba Ọlọ́run láàyè nínú ayé wọn nítorí wọ́n bẹ̀rù pé Yíò gba gbogbo ohun ìgbádùn lọ́wọ́ wọn. Wọ́n rò pé láti di Kristẹni túmọ̀sí bí ìgbà tí a wípé àríyá ti parí, wípé láti jẹ́ ẹni ẹ̀mí túmọ̀sí kí á má apa ṣìọ̀ ṣìọ̀.

Àwọn ènìyàn fojú méjèèjì wá oun amúnúdùn kiri, ṣùgbọ́n èyí túmọ̀sí pé wọ́n wà lábẹ́ òfin ìdínkù ìtẹ́lọ́rùn. Wọ́n ńlo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ okun ná fún amárayá tí ó ń kéré síi níye. Wọ́n wá ń bèrè kiri pé, “Ǹjẹ́ a ti ń gbádùnara wa bí?”

Òtítọ́ ni pé, Ọlọ́run “tí ń fún wa ní gbogbo ọrọ̀ fún ìgbádùn wa (Tímótì Kíní 6:17b BM).

Ọlọ́run fẹ́ kí o gbádùn ayé rẹ!

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Recovering Your Joy

Tí o bá ún fẹ́ ayọ̀ ní ayé rẹ́, o nílò láti wá àyè ọgba lóríi ètò ìgbòkègbodò rẹ. Olùṣọ́-àgùntàn Rick bá wa pín bí a ti ṣe le ṣe àtúntò oun tí à ń fi jìn àti oun tí ó ń jáde kí ififún rẹ àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ lè ràn ọ lọ́wọ́...

More

A kọ ètò ìfọkànsìn yí © 2014 látọwọ́ Rick Warren. Òfin sì de ṣíṣe àmúlò rẹ̀. O ní láti tọrọ gáfárà kí o tó lò ó.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa