Gbígba Ayọ̀ Rẹ PadàÀpẹrẹ

Recovering Your Joy

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ṣíṣe Àwárí Ayọ̀ Rẹ Tó Sọnù

Ka Ìwé Rómù 14:17.

Kínni nnkan tí ó maa ń tètè sọnù lọ́wọ́ rẹ? Awó-ojú rẹ? Kọ́kọ́rọ́ rẹ? Àbí iyè rẹ?

Ayọ̀ ènìyàn ló lè tètè máa ń bọ́ sọnù jù. Ìpè lórí fóònù, lẹ́tà ayára-bí-àṣá, tàbí ìtakùrọ̀sọ kan péré lè ba ayọ̀ ènìyàn jẹ́. Wíwo ìpolówó ọjà lásán lórí tẹlifísàn lè ba ayọ̀ ènìyàn jẹ́. Ayọ̀ ló rọrùn jùlọ láyé látì sọnù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló sì ń wá orísìírìsí ọ̀nà láti jà ọ́ lólè rẹ̀.

Nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run kò bá kún fun ayọ̀, á jẹ́ kí ó dàbí pé Ọlọ́run kò dára. Kìí ṣe àpẹẹrẹ rere ni kí Krìstẹ́nì máa kanra. Nítorí pé wọn kìí rẹ́rìnín, wọn á máa wò bí ìgbà tí wọ́n ti rẹ wọ́n sínú ọtí kíkan. Èyí sì máa ń jẹ́ kí ò dàbí pe ẹni bukúrú ni Ọlọ́run.

Kínni èrèdí? Nítorí pé Ọlọ́run fẹ́ kí ìrínisí wa jẹ́ ọ̀nà láti jẹ́rì Òun.

Bíbélì fi yé wa pé a lè ṣe àkópọ̀ ìgbésí ayé Krìstẹ́nì pẹ̀lú ọ̀rọ̀ mẹ́ta péré: oore, àlááfíà àti ayọ̀. Rómù 14:17 sọ pé "Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni.” (BM).

Òtítọ́ t'ó wà níbẹ̀ ni pé o lè sọ ayọ̀ rẹ nù ní wàrànṣeṣà, àimoye ọ̀nà sì ni o lè gbà sọ ọ́ nù. Àìmọye abaniláyọ̀jẹ́ ló wà láyé débi pé èèyàn bíi Jeremáyà, wòólì Ọlọ́run, lè sọ ní Ẹkún Jeremáyà 5:15 pé "Inú wa kò dùn mọ́" (BM).

N kò mọ̀ bóyá irú ipò tí ìwọ náà wà lọ́wọ́lọ́wọ́ nìyí, ṣùgbọ́n tí o bá ń la ìrírí tó dàbíi pé o ti jìnnà sí Ọlọ́run ju ti àtẹ̀hìnwá lọ kọjá, t'ó sì jẹ́ pé níṣe lo kàn ń bá ayé yí lọ, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé à-ti-gba ayọ̀ rẹ padà kò nira rárá.

Báwo lo ṣe lè gba ayọ̀ rẹ padà?

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí o gbà pé o ti sọ ọ́ nù.

B'ojú wẹ̀hìn kí'o sì bi ara rẹ ní ìbéèrè méjì kan: Njẹ́ ìgbà kan wà tí o súnmọ́ Ọlọ́run ju bí ó ṣe rí báyì lọ? Ìgbà kan ha wà nínú ayè rẹ tí ayọ̀ Ọlọ́run kún inú rẹ ju tòní lọ?

Àsìkò láti ṣe àtúnṣe nìyìí. Ṣùgbọ́n o ní láti kọ́kọ́ gbà pé o ti sọ nnkan tí o ti ní látẹ̀hìnwá nù. O lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀: Ó ń dúró láti ràn ọ lọ́wọ́. Dáfídì gbàdúrà ní Orin Dáfídì 51:12 pé "Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi" (BM).
Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Recovering Your Joy

Tí o bá ún fẹ́ ayọ̀ ní ayé rẹ́, o nílò láti wá àyè ọgba lóríi ètò ìgbòkègbodò rẹ. Olùṣọ́-àgùntàn Rick bá wa pín bí a ti ṣe le ṣe àtúntò oun tí à ń fi jìn àti oun tí ó ń jáde kí ififún rẹ àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ lè ràn ọ lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ rẹ padà dípò kí o sọ ọ́ nù.

More

A kọ ètò ìfọkànsìn yí © 2014 látọwọ́ Rick Warren. Òfin sì de ṣíṣe àmúlò rẹ̀. O ní láti tọrọ gáfárà kí o tó lò ó.