Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ìjàkadì Ti Ìmọ̀lára
Njẹ́ o ti ní ìmọ̀lára rí bí ẹni pé ìrẹ̀wẹ̀sì ńlá ti ṣubú lu ẹ̀mí rẹ? Ìgbà míràn ohun gbogbo ń lọ déédé, àmọ́ nígbà tí ǹkan bá dojú rú, ó rọrùn láti rò pé kò já sí nkan kan mọ́ láti tún ayé rẹ tò. Ìbànújẹ́, ìbínú, àìnírètí, àti ẹ̀rù jẹ́ ìmọ̀lára tí àwọn Krìstẹ́nì tí ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ gan an pàápàá máa ń ní ìrírí rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro. Ìwọ kàn wo Dáfídì tàbí àwọn gbajúgbajà onígbàgbọ́ mìíràn.
Ọ̀pọ̀ ìgbà, ẹ̀rù máa ń bà wá láti gbà pé tòótọ̀ ni àwọn èrò ara báwọ̀n yìí. Ṣúgbọ́n ó ṣe pàtàkì kí á kojú gbogbo àwọn èrò ara--pàápàá àwọn tí kò dára--ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Ní ìgbà tí a bá gbé ìbínú àti ìbànújẹ́ wa yẹ̀ wò nínú ìmọ́lẹ́ ti òtítọ́ Ọlọ́run, a lè rì ìtùnú gbà dípò kí á máa tan ara wa pé kò si níbẹ̀.
Ní ìgbà tí inú wa kò bá dùn, a lè rí ayọ̀ nínú òtítọ́ pé Ọlọ́run súnmọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn (Orin Dáfídì 34:18). Ní ìgbà tí inú bá ń bí wa, a lè rí àlàáfíà nínú ìlérí pé ìfẹ́ Ọlọ́run kìí kùnà bí ó ti wù kí ìrunú wa pọ̀ tó (Àìsáyà 54:10). Ní ìgbà tí àìnírètí dàbí ẹni pé ó ti borí, a lè kó àníyàn wa lé Olúwa nítorí pé kò ni jẹ̀ kí á ṣubú (Orin Dáfídì 55:22). Àti pé nígbà tí ó bá dàbí pé kí á gbà ẹ̀rù láàyè, a lè di alágbára nítorí pé Ọlọ́run ni ìsádi wa, a sì mọ pé kò lè já wá kulẹ̀ láéláé.
Ọlọ́run ti fún wa ní ìlérí tí ó pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́, àmọ́ eléyì tí ó ń fún wa jù láti ìgbà dé ìgbà ni ìtùnú. Ìjà wa pẹ̀lú èrò ara wa yé E, ó sì ń ṣe àánú fún wa.
Ọlọ́run fẹ́ kí á jọ̀wọ́ àjàgà wa fún Òun kí á sì gbé ara lé Òun pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ní ìgbà tí èrò ara wa bá pọ̀ jù fún wa láti dá kojú.
Ní ìgbà tí ẹ̀mí wa bá rẹ̀wẹ̀sì, Ọlọ́run fi dá wa lójú pé Òun ṣì tó fún wa.
Nítorí náà ní ìgbà mìíràn tí o bá ní ìdánwò bí i pé kí o kọ àwọn èrò ara rẹ̀ tàbí pé kí o dá wọn dojú kọ, níṣe ni kí o fi wọ́n sílẹ́ fún Ọlọ́run. Yoó fún ọ ní ìrètì tí ó ju gbogbo èrò ara tí ò ń bá jà ìjàkadì lọ.
Àdúrà: Ọlọ́run mí, mo dúpẹ́ fún ìdánilójú tí O fún wa nínú Ìwé Mímọ́ nípa ìfẹ́ Rẹ fún wa. Mo mọ̀ pé ní ìgbà gbogbo ìwọ ní agbára ju irú wàhálà tí ó lè d'ojú kọ mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti jọ̀wọ́ àwọn ìjà mi nínú èrò ara mi fún Ọ. O ṣeun fún ìtùnú tí Ò ń fi fún mi ní ìgbà tí mo nílò rẹ̀ jù. Àmín.
Nípa Ìpèsè yìí
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.
More