Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Ọjọ́ 5 nínú 10

Gbígba Agbára Látọ̀dọ̀ Olúwa

Ìbẹ̀rù kì í ṣe ohun tó yẹ kéèyàn fi ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kó fọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Kò jẹ́ kí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ṣe nǹkan ńlá. Ó ti dá àwọn ọmọ ogun dúró. Ó sì tún máa gbìyànjú láti dá ọ dúró, bó o bá gbà á láyè.

Àmọ́ ohun kan wà tó lágbára ju ìbẹ̀rù lọ--ìyẹn ni Ọlọ́run. Ìmọ̀ yẹn ló yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù borí wa, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni ni wá, síbẹ̀ gbogbo ìgbà la máa ń bẹ̀rù.

Bá a sì ṣe ń juwọ́ sílẹ̀ fún ìbẹ̀rù fi hàn pé a ò mọ bí agbára Ọlọ́run wa ṣe tó.

Ẹsẹ Bíbélì tá a kà lónìí nínú Sáàmù kẹrìndínláàádọ́ta jẹ́ ká rí bí ìgbàgbọ́ ṣe lè mú ìbẹ̀rù kúrò. Onísáàmù náà sọ pé nítorí pé Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ òun, òun kì yóò bẹ̀rù - kódà bí ilẹ̀ ayé bá mì tìtì, tí àwọn òkè ńlá sì ṣubú sínú òkun! Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu lèyí!

Tó o bá ti lọ sórí òkè rí, o lè fojú inú wo bí ẹ̀rù á ṣe máa bà ẹ́ tó bí òkè bá bẹ̀rẹ̀ sí í wó lulẹ̀. Àmọ́ onísáàmù náà ò sọ pé àwọn òkè tó ń wó lulẹ̀ kò lè kó jìnnìjìnnì báni. Ohun tó ń sọ ni pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára ju ìbẹ̀rù rẹ̀ lọ.

Ìbẹ̀rù máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé àwa nìkan la wà, pé àwa nìkan la máa dojú kọ àdánwò àti ìnira. Ó máa ń rán wa létí ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí. Ó ń jẹ́ ká mọ àwọn àṣìṣe tiwa fúnra wa. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ń tọ́ka wa sí Ọlọ́run. Ó mú un dá wa lójú pé a ò dá wà láé - Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa nígbà gbogbo! Ìgbàgbọ́ sì fi hàn wá pé àìlera wa wulẹ̀ jẹ́ àǹfààní láti fi agbára Ọlọ́run hàn.

Ìgbésí ayé kún fún ìṣòro àti ayọ̀. Frederick Beuchner sọ nígbà kan pé, "Èyí ni ayé. Àwọn ohun tó fani mọ́ra àti àwọn ohun tó bani nínú jẹ́ yóò ṣẹlẹ̀. Má bẹ̀rù". Ohun tó sọ sì tọ̀nà! Kò sídìí fún wa láti bẹ̀rù. A ní Ọlọ́run kan tó ti ṣẹ́gun ayé.

Àdúrà: Ọlọ́run mi, o ṣeun fún agbára rẹ lórí gbogbo ohun tí mo dojú kọ. Ran mi lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára ju ìbẹ̀rù mi lọ. Lo àìlera mi láti fi agbára Rẹ hàn. Mo dúpẹ́ pé ìfẹ́ rẹ sí mi kò kùnà. Àmín.

Day 4Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Vernon Brewer, Olùdásílẹ̀ àti Olùdarí World Help fún ìpèsè ètò Bíbélì yí. Fún àlàyé síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.worldhelp.net

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ