Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Agbára Àdúrà
Tá a bá ń kojú àdánwò, ó lè dà bíi pé a ò lè gbàdúrà mọ́. "Bí Ọlọ́run ò bá dáhùn àdúrà mi lọ́nà tí mo rò pé ó yẹ kó dáhùn rẹ̀ ńkọ́?" ó lè máa ṣe wá bíi pé ká béèrè ìbéèrè yìí. "Ìgbà wo ni yóò jẹ́ tí kò bá wá gbà mí lọ́wọ́ ìṣòro mi?" Nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro tó le koko jù lọ, ó lè dà bíi pé àdúrà ò wúlò rárá, a sì lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà wa.
Àmọ́ 1 Jòhánù 5:14-15 sọ fún wa pé ó yẹ ká ní ìgbọ́kànlé nígbà tá a bá ń gbàdúrà. Ohun yòówù tí a bá béèrè, Ọlọ́run máa ń gbọ́ wa. Bí a bá sì gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀, a mọ̀ pé yóò dáhùn nítorí ó máa ń ní ire wa lọ́kàn nígbà gbogbo.
Apá tó ṣòro nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn ni pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ láti gbàdúrà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. A kì í mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nígbà gbogbo, nígbà míì a sì máa ń fẹ́ kí a ṣe ohun tí àwa fẹ́. Àmọ́ kì í ṣe ohun tí àdúrà wà fún nìyẹn. Àdúrà ń jẹ́ ká ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní àlàáfíà nípasẹ̀ àjọṣe yẹn. Àdúrà máa ń jẹ́ ká lè fi àwọn ìṣòro wa àti ìnira wa fún Ọlọ́run ká sì sọ pé, "Èyí jẹ́ tìrẹ nísinsìnyí. O lè fara dà á dáadáa ju bí èmi ṣe lè fara dà á lọ."
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa la máa ń retí pé kí Ọlọ́run mú àwọn ìṣòro wa kúrò, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, kódà nígbà tí kò bá tiẹ̀ sí nínú ètò Ọlọ́run láti mú wa lára dá tàbí láti gbà wá lọ́wọ́ ipò kan, àdúrà ṣì ṣe pàtàkì.
Tá a bá ń sọ àwọn ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún Ọlọ́run, tá a sì ń sọ àwọn ohun tá à ń tọrọ fún un, a máa ní àlàáfíà tó ju gbogbo ìrònú lọ, èyí á sì máa ṣọ́ ọkàn wa àti èrò inú wa. Nítorí náà, sọ àwọn ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn àtàwọn ohun tó ò ń fẹ́ fún Ọlọ́run nínú àdúrà lónìí. Kí ẹ sì máa yọ̀ nínú àlàáfíà àti ìrètí tí ó fún yín ní ìdáhùn.
Àdúrà: Ọlọ́run, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ẹ̀bùn àdúrà. Mo dúpẹ́ pé mo lè tọ̀ ọ́ wá nígbàkigbà tí mo bá níṣòro. Mo sì dúpẹ́ fún ìfẹ́ rẹ tí kò lábùlà fún ìgbésí ayé mi. Mo gbàdúrà fún àlàáfíà tí o ṣèlérí láti dáàbò bo ọkàn mi àti èrò inú mi nígbà tí ìbẹ̀rù àti iyèméjì bá wọlé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o máa ń dáàbò bò mí. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.
More