Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Òtítọ́ Nípa Àwọn Ìdánwò
Tí o bá kéré jù láti rántí àwọn fóònù inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti àwọn késẹ́tì orin ayé àtijọ́, o le má mọ ẹni tí Keith Green jẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ tó kọ nínú orin “Àwọn Ìdánwò di Wúrà” ṣe pàtàkì lónìí gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nígbà tó ko ó lọ́dún 1977.
Ìwòye láti ibí kò súnmọ́ ohun tí ó jẹ́ fún Ọlọ́run. Mo gbìyànjú láti rí èrò Rẹ fún mi, ṣùgbọ́n mo kàn ṣe bí ìgbàtí mo mọ̀ ọ́ ni. Olúwa, d'áríjìmí nípa àwọn àkókò tí mo sebí èyítí mo mọ èrò ọkàn Rẹ, nítorí O sọ pé tí èmí bá dúró jẹ́, lẹ́hìn náà ni èmi yóò gbọ́ ohùn Rẹ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ń dojú kọ àwọn àdánwò gidi, tí ó le gan-an lójoojúmọ́. Jíjẹ́ onígbàgbọ kò gbà wá nínú èyí. Ṣùgbọ́n mímọ̀ pé Olùgbàlà wa wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa ó sì mọ ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin gbogbo rẹ̀ láìka àwọn àdánwò tí a dojú kọ sí jẹ́ ìtùnú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí. Ó mú un dá wa lójú pé a kò dá wà nínú ìjì àti ìrora wa. Ó sì ń fún wa ní ojú ìwòye tí ó ga jù lọ nípa àwọn ìṣòro wa—ìmọ̀ pé wọ́n ń ṣe ète tí ó tóbi jù lọ nínú wa àti nínú ayé.
A rán wa létí ète yìí nínú Jákọ́bù 1:2-4 níbi tí Jákọ́bù ti fún wa ní àṣẹ tí ó dà bíi pé kò bọ́gbọ́n mu láti ní ayọ̀ nínú àwọn àdánwò wa.
Ní ayọ̀ nínú ìdánwò? Ó dàbí pé kò ṣeé ṣe! Sùgbọ́n láti ojú-ọnà ti Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe. Àwọn àdánwò wa ń mú wa sún mọ́ ọn, kò sì jẹ́ kí á ṣe aláìní nǹkankan
A le máfẹ̀ ẹ́ láti kojú àwọn ìdánwò nínú ìgbésí ayé wa, àti pé a le má wò wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí ànfàní tàbí pàtàkì. Sùgbọ́n a kò ní irísí Ọlọ́run. Tàbí bí Keith Green ti sọ, "Ìwòye láti ibí kò sí ohun tí ó súnmọ́ ohun tí ó jẹ́ fún Ọlọ́run."
Pàápàá nígbà tí ayé wa bá ńmì, a kò gbọ́dọ̀ Kúrò ní ọwọ́, tàbí èrò, Ọlọ́run.
Àdúrà: Olúwa mi, O ṣeun fún ìrètí tí mo ní nínú Rẹ àní nínú àwọn àdánwò. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti ní irísí Rẹ bí mo ṣe ní ìrírí àwọn ìṣòro ní ìgbésí ayé. Mo gbẹ́kẹ̀lé Ọ láti ṣàṣeyọrí àwọn ohun rere nípasẹ̀ àwọn ìgbìyànjú mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ pé pàápàá nígbà tí ayé mi kò dúró, Mo lè ní ìgboyà nígbà gbogbo nínú Rẹ. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.
More