Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Ọjọ́ 6 nínú 10

Fífi Ìbùkún Tí Ó Wà Lẹ́yìn Ìdánwò Wá Ṣe Àfojúsùn

Nígbà tá a bá wà nínú ìjì, ayé wa sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ sí yí ká ara wa. Kò sì pẹ́ tá a fi máa ń ronú nípa àwọn ìṣòro wa nìkan. Nígbà míì, ìyẹn máa ń jẹ́ ká lè máa wà láàyè nìṣó. A ní láti máa bójú tó ara wa ká lè borí ìṣòro wa. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ẹ̀mí ìfojú-ẹni-wò yìí máa ń pa wá lára.

Ọkàn wa sọ fún wa pé kí a máa ṣọ́ra nítorí pé kò sẹ́ni tó máa ṣe fún wa, àti pé, nígbà tí a bá rẹ̀wẹ̀sì, ó rọrùn láti gba irọ́ yìí gbọ́. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 58:10-11 yàtọ̀. Ó sọ fún wa pé tí a bá gbájú mọ́ ríran àwọn tí ebi ń pa àti àwọn tí wọ́n ń ni lára lọ́wọ́, Ọlọ́run yóò pèsè ohun tí a nílò fún wa. Ó sì fi hàn wá bí ó ti dára tó láti mú àníyàn nípa ìgbésí ayé tiwa kúrò, kí a sì máa bùkún àwọn ẹlòmíràn dípò ìyẹn.

Ẹsẹ Bíbélì tó fani mọ́ra yìí jẹ́ kí a mọ̀ pé ẹ̀bùn ló jẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn! Ẹ̀bùn tó sì ṣe pàtàkì gan-an fún wa láti gbà nígbà tí a bá ń jìyà.

Ìgbà tí àwọn èèyàn bá ń jìyà ló yẹ kí a máa fìfẹ́ hàn sí wọn jù lọ. Bákan náà, bí àwa fúnra wa bá ní ìṣòro, ó máa ń jẹ́ kí a mọ bó ṣe máa ń rí lára àwọn ẹlòmíì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdánwò wọn yàtọ̀ sí tiwa, síbẹ̀ a lè lóye ìrora tí wọ́n ń jẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ díẹ̀ ni a lóye rẹ̀.

Òye ń ràn wá lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn dáadáa! Dípò tí a ó fi máa wo ara wa ní gbogbo ìgbà, a lè máa wá ọ̀nà láti bù kún àwọn ẹlòmíràn.

Tá a bá ń wojú Ọlọ́run, tá a sì ń ronú nípa ohun tó máa ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní dípò ohun tó máa ṣe àwa fúnra wa, a ó lè máa fi ojú tó tọ́ wo nǹkan. A máa ń fi ìrora àti àìlera àwọn ìṣòro wa ṣe pàṣípààrọ̀ fún ayọ̀ àti àṣeyọrí tá a máa ń rí nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Àá sì tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

Àdúrà: Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ojú mi mọ́ kí n lè rí àwọn tó wà láyìíká mi tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Fi ohun tóo fẹ́ kí n ṣe hàn mí ní àárín àdánwò mi láti ran àwọn tó wà nínú irú ipò kan náà lọ́wọ́. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín pé ẹ jẹ́ kí n lè gbádùn ìbùkún sísin àwọn ẹlòmíràn, kódà nígbà tí ìgbésí ayé mi kò bá rọrùn. Àmín.

Day 5Day 7

Nípa Ìpèsè yìí

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Vernon Brewer, Olùdásílẹ̀ àti Olùdarí World Help fún ìpèsè ètò Bíbélì yí. Fún àlàyé síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.worldhelp.net

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ