Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Àlàáfíà, Ìrànlọ́wọ́, àti Ìrètí fún Ọ̀lá
O ti dé ọjọ́ ìkẹhìn tí ikẹkọọ yìí! Ìfọkànsín tí ọjọ òní jẹ́ nípa ohún kan ṣoṣo tí o ṣe pàtàkì jùlọ fún ẹnikẹ́ni láti ní, nígbàti o bá wa nínú ìṣòro - ìrètí.
Ohúnkóhun tí óo bá máa là kọja, Ọlọ́run mọ. Ìfẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ kìí sìí kùnà láé. Ó ń ṣọ́ ọ nísinsìnyí. Nígbàgbogbo ni Ó sì ni ọ̀ ni ọwọ́ Rẹ.
Ohúnkóhun tí o wù kó ṣẹlẹ tàbí ọnà tí ìtàn rẹ gbà, o lè ni ìdánilójú wípe Ọlọ́run Ò dà ọ kúrò nínú eto Rẹ.
Àti wípé o le farabalẹ nípa mímọ wípe Olùgbàlà rẹ kò ní dá fí ọ sílẹ.
Ìfihàn 21:3-5 jẹ́ ìránnilétí ìrètí àgbàyanu tí a ní nítorí Krísti. Ọlọ́run ti ṣèlérí ayè fún wa ní ọ̀run níbi tí kò ti ní sí ìjìyà tàbí ìrora mọ́, àti níbi tí yóò ti nu omijé gbogbo kúrò ní ojú wa. Pàápàá ni bayi o n ṣe àye fún wa níbẹ. Ó ń sọ ohun gbogbo di ọ̀tún!
Nítorí ná, níbikíbi tí o bá wa lóni, mú àkókò díẹ láti faratí Olùgbàlà tí kii yóò fi ọ sílẹ tàbí kọ̀ ọ sílẹ. Gba ìtùnú nípasẹ mímọ wípe Òún nṣiṣẹ́ ohun gbogbo papọ̀ fún rere. Kí o sì ní ìgbàgbọ́ wípé àdánwò yòówù kí o dojú kọ ní ayé yìí, kò to láti fi ́wé ayọ̀ tí ń dúró dè ọ.
Ìjàkadì rẹ ko tóbi jù fún Ọlọ́run. Àti wípe bí o ti wù kí o wà ninú àìnirètí to, ìrètí wa ti o tóbi ju àìnirètí rẹ lọ. Yàn láti gbé nínú òtítọ yẹn lóni.
Àdúrà: Ọlọ́run ọ̀wọ́n, Ẹ ṣeun fún ìmọ̀ tí a ní wípé Ẹ ń ṣiṣẹ́ ohùn gbogbo fún réré. Ẹ ṣeun wípe nígbàti wàhálà ayé yi bá kà mí láyà, wọn kò ṣetúmọ mi. Mo dúpẹ lọwọ́ Yín wípe mo lé rí ìdánimọ̀ mí nínú Yín àti nínú ìṣẹgun tí mo mọ̀ wípe o ńbọ. Ẹ ṣeun fún ẹbùn ìyè àìnípẹkun pẹlú Yín. Ẹ ràn mi lọwọ́ láti ní ìrètí àti ayọ̀ lójojumọ gẹ́gẹ́bi ọmọ Yín. Àmín.
Ìfọkànsìn yìí jẹ́ àkópọ̀ ìwé Kí nì ìdí? Àwọn ìdáhùn sí àti ṣe ìgbésí ayé tí ó borí ìjì ayé. Bí o bá n wá ìwúrí Bibeli díẹ síi láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ ni àkókó adánwò, o le gba ẹya iwe tìrẹ nibi .
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Finding God's Truth In The Storms Of Life](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F12468%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.
More