Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Ọjọ́ 7 nínú 10

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Kọ́

Nínú ìwé rẹ̀, Bíbá Ọlọ́run Rìn Láàárín Ìrora àti Ìjìyà, Tim Keller sọ pé, "O kò lè mọ̀ pé Jésù nìkan ni o nílò, títí di ìgbà tí ó bá jẹ́ Jésù nìkan ló kù ẹ́ kù.".

World Help , ọ̀pọ̀ ìgbà la ti rí i pé òótọ́ lòhun tá à ń sọ yìí bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn kárí ayé. Nígbà tí àwọn alábòójútó ilé àwọn ọmọdé kan ní Nepal rí i pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ti di àwókù nítorí ìsẹ̀lẹ̀ kan, ohun kan ṣoṣo tí wọ́n lè ṣe ni wọ́n ṣe - wọ́n yíjú sí Jésù. Nígbà tí opó kan ní Rwanda ń tiraka láti pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ohun tó kọ́kọ́ ṣe ni pé ó gbàdúrà. A ti gbọ́ ìtàn lẹ́yìn ìtàn nípa àwọn èèyàn tí àwọn àdánwò ti sún wọn sínú ìkáwọ́ Ọlọ́run.

Ìjìyà ń fi hàn wá pé ìgbàgbọ́ wa ṣe pàtàkì. Ó mú ká wà ní ipò tí a kò ti lè gbára lé ara wa. Nínú 2 Kọ́ríńtì orí kẹrin, a rán wa létí pé nígbà tí àwọn nǹkan tá a gbára lé bá kùnà, ẹ̀mí wa á túbọ̀ lágbára sí i. A óò túbọ̀ sún mọ́ Orísun okun tòótọ́, a ó sì kọ́ láti máa wo Òun.

Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò àti ìjìyà, ká rọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́.

Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà fi ìrora wa ṣòfò ni pé ká gbàgbé rẹ̀, ká sì fi àwọn ohun iyebíye tá a ti rí kọ́ nínú rẹ̀ sílẹ̀.

Tó bá pọn dandan kó o ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ìṣòtítọ́ Ọlọ́run máa fara hàn nínú ìgbésí ayé rẹ bó o ṣe ń fara da àdánwò. Ọ̀pọ̀ ère, ìwé àti orin ni wọ́n ti ṣe fún ète yìí. Àmọ́, kò pọn dandan kí ohun tí ìwọ fi ńṣe ìrántí jẹ́ ǹkan tí ó fani mọ́ra. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń lo òkìtì òkúta láti rántí àwọn ìpèsè Ọlọ́run àti láti rán àwọn ọmọ wọn létí. Ohun yòówù tó bá máa rán ẹ létí rèé.

Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jésù ni gbogbo ohun tá a nílò. Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni ayé tó yí wa ká dà bí èyí tó kún fún rúkèrúdò tí kò sì ṣeé fọkàn tán, a ní ìrètí tó dájú. Ẹ jẹ́ ká máa yọ̀ nínú ìyẹn lónìí!

Àdúrà: Ọlọ́run mi, mo mọ̀ pé ìyà tó ń jẹ mí ń mú kí n túbọ̀ sún mọ́ ọ. Ran mi lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ kí ìgbàgbọ́ mi sì máa lágbára sí i nígbà tí mo bá dojú kọ àdánwò nínú ìgbésí ayé yìí. Kó o sì ràn mí lọ́wọ́ láti máa rántí àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn kódà nígbà tí ipò mi bá yí padà. Mo dúpẹ́ fún sùúrù rẹ pẹ̀lú mi bí o ṣe ń bá a lọ láti sọ mí di ẹni tí o fẹ́ kí n jẹ́. Àmín.

Day 6Day 8

Nípa Ìpèsè yìí

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Vernon Brewer, Olùdásílẹ̀ àti Olùdarí World Help fún ìpèsè ètò Bíbélì yí. Fún àlàyé síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.worldhelp.net

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ