Dídúró Dè Ọ́ Níhìn-ín, Ìrìn-Àjò Ìrètí Ìpadàbọ̀Àpẹrẹ

Waiting Here for You, An Advent Journey of Hope

Ọjọ́ 7 nínú 7

ÌWÀ ÌRẸ̀LẸ̀ YẸ́ GBÓGBÓ ÈNÌYÀN

ÌWÒYÉ

Jésù Krístì ni Ọba àwọn ọba, síbẹ̀ Ó wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ t'ónírẹ̀lẹ̀ ọkàn. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ò já sí pé oò já mọ́ nkán kán, ṣùgbọ́n kí o má rántí pé Jésù ni àṣírí titóbi rẹ. Báwo lo ṣe wá lé dàbí Jésù? Báwo lo ṣe lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?

Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ àbáyọrí rírìn pẹ̀lú Jésù. Ẹnikẹ́ni tó bá rìn tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Rẹ̀ kò ní gbé ara rẹ̀ ga jú bí ó ti yẹ lọ́. Oún tí a nílò jùlọ láti gbe ará wa sórí ìwọ̀n tó yẹ ni kí Jésù fẹ́ràn wa, kí á bá a d'ọ́rẹ̀, kí á sì ní ìwà tútù pẹ̀lú oréọ̀fẹ́.

Atí jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ kìí ṣe bíi kí o jẹ́ ojó. Ọlọ́run ti fún ọ ní àmúyẹ tí o nílò láti gbé pẹ̀lú ìgboyà gẹ́gẹ́ bí ọmọ Rẹ̀. Agbéraga kò ní lè yin orúkọ Olúwa ní òtítọ́. Síbẹ̀ Ó gbé onírẹ̀lẹ̀ lọ sí ibi gíga ọ̀tún

ÀṢÀRÒ ÀTI ÀDÚRÀ

Àdúrà Ìpẹ̀ Àdágbà fún Ìwà Ìrẹ̀lẹ̀

Jésù, dá mi ní'dè lọ́wọ́ ìfẹ́ kí wọ́n máa yìn mí
Lọ́wọ́ ìfẹ́ kí wọ́n máa b'ọlá fún mi Jésù dá mi ní'dè.

Lọ́wọ́ ìfẹ́ kí ó jẹ́ èmi nìkan ni wọ́n ń fẹ́, Jésù gbà mí.
. Lọ́wọ́ ìfẹ́ pé èmi nìkan ni kí wọ́n máa fọ̀rọ̀ lọ̀, Jésù, gbà mí.
. Lọ́wọ́ ìfẹ́ pé èmi nìkan ni kí wọ́n yàn láàyò, gbà mí Jésù

Lọ́wọ́ ìfẹ́ ìdẹ̀ra and ìrọ̀rùn tí kò tọ́, gbà mí Jesù.
Lọ́wọ́ ìbẹ̀rù pé ká má fi mí ṣe ẹlẹ́yà, gbà mí, Jésù.
. Lọ́wọ́ ìbẹ̀rù pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa àlébù mi, gbà mí Jésù.
Lọ́wọ́ íbèrù pé kí wọ́n má fò mí kọjá, gbà mí, Jésù
Lọ́wọ́ íbèrù pé kí n má di ẹni ìgbàgbé, gbà mí, Jésù.
Lọ́wọ́ ìbẹ̀rù pé kí n má dá wà, gbà mí Jésù

Lọ́wọ́ àníyàn pé kí á má pa mí lára, gbà mí Jésù
Lọ́wọ́ àníyàn kí n má jìyà, gbà mí Jésù

Kí n fẹ́ ẹlòmíràn jù ara mi lọ
Jésù, fún mi ní oréọ̀fẹ́ láti ní àníyàn yí
Kí á yan ẹlòmíràn ṣíwájú mi
Jésù, fún mi ní oore ọ̀fẹ́ láti ní irú ìfẹ́ yìí
Kí á yin àwon míràn láì ka èmi sí
Jésù, fún mi ní oore ọ̀fẹ́ láti ní ìfẹ́ yìí

Jésù, oníwà tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, jẹ́ kí ọkàn mi dàbíi tìrẹ
Jésù, oníwà tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, ró mi ní agbára pẹ̀lú È̩mí rẹ
Jésù, oníwà tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ

Jésù, oníwà tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn,
ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìjọrà ẹni lójú tì sẹ́gbẹ́ kan
kí n mọ irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn míràn
tí ó ń mú kí ilé Baba kí ó wà lálàáfíà. Àmín.

 

A fàáyọ látinú àdúrà Rafael,
Cardinal Merry Del Val, 1865–1930

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Waiting Here for You, An Advent Journey of Hope

Ìgbà ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò tí à ń wà ní ìrètí àti ìmúrasílẹ̀. Dárápọ̀ mọ́ olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ̀wé Louie Giglio lórí ìrìnàjò Ìpadàbọ̀ yí láti ríi wípé dídúró kò jásí òfò ní àkókò tó bá jẹ́ Olúwa lò ń dúró dè. Ṣe àmúlò àǹfààní yí láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìrètí gbòòrò tí ìrìn-àjò Ìpadàbọ̀ ti ṣètò fún wa. Ní ọjọ́ méje tó ń bọ̀ yí, iwọ́ yíó rí àlàfíà àti ìgbani-níyànjú fún ẹ̀mí rẹ nítorí ìrètí a máa fani súnmọ́ ayẹ́yẹ́!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Louie Giglio, ẹni tó kọ Dídúró Níhìn Dè Ọ́ (Passion Publishing), fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.passionresources.com