Dídúró Dè Ọ́ Níhìn-ín, Ìrìn-Àjò Ìrètí Ìpadàbọ̀Àpẹrẹ
JÉSÙ NI ÀSÈ WA
ÌWÒYE
Jésù kò kàn fún ọ ní ohun tí o nílò; Jésù ni ohun tí o nílò. Oún ló dá ọkàn rẹ́ fún ara Rẹ̀. O lè tiraka láti jèrè gbogbo àgbáyé, ṣùgbọ́n láìsí Jésù, ìwọ kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pátápátá.
Bí àìnítẹ̀lọ́rùn kan bá n rú nínú óókan-àyà rẹ—ébí tí á kòi tí ní ìtẹ́lọ́rùn àwọn ènìyàn, ìgbádùn, àríyá, óún nǹkan ti árá, tàbí àwọn àṣéyọrí—òní ni ọjọ́ áti ṣí ọkàn rẹ sí èrò náà pé Jésù ni a dá ọ fún. Ṣùgbọ́n o ní láti rìn kúrò nnú “díẹ̀,” kí o sì béèrè pé kí Ó di “púpọ̀” rẹ́. Jésù tó fún ọ, Ó sì wà níhìn-ín.
ÀṢÀRÒ
Wá, wá Imánúẹ́lì
Wá, wá Imánúẹ́lì,
Wá tú Israẹli sílẹ̀
Tíì ṣọ̀fọ̀ nínú ìgbèkùn níhìn-ín
Títí Ọmọ Ọlọ́run yíò fara hàn.
Kún f'áyọ́! Kùn f'áyọ́!
Imánúẹ́lì yíò tọ̀ ọ́ wá, Isreali.
Wá, Èká gbòngbò Jésé,
Sí àwọ́n tì Rẹ́ láti gbà wọ́n!
Gbá àwọn ènìyàn Rẹ́ l'ọ́wọ́ àpáàdì,
Sì fún wọ́n ní ìṣẹ́gun lórí ibojì.
Kún f'áyọ́! Kùn f'áyọ́!
Imánúẹ́lì yíò tọ̀ ọ́ wá, Isreali.
Latin, c. 12th century
Psalteriolum Cantionum Catholicarum, Köln, 1710
Tí a t'ọwọ́ John Mason Neale, 1818–1866, ṣe ìtumọ̀ rẹ̀
Ẹsẹ̀ 1 & 4
ÀDÚRÀ
Bàbá, Ìwọ nìkán ní Ó mọ làálà tí mo ti ṣe láti wá ìtẹ́lọ́rùn nínú àwọn ènìyàn àti nkán ti áyé yìí. Ṣùgbọ́n wọ́n kù díẹ̀ kàà tó, àti èmi pẹlú. Ìwọ nìkan lo lè mú ébí ọkàn mi. Ìwọ nìkan ni o ní ìfẹ́ tí kò dàbí òmíràn. Ó kìí yí padà. Lá ojú mi lóní. Fí ọ́rọ̀ àti ògó Rẹ hàn mí. Ràn mí l'ọ́wọ́ láti mọ̀ Ọ si. Jẹ́ kí n rí àsè Rẹ tí a gbé kalẹ̀ níwájú mi, kí èmi lè má yọ̀ nínú Rẹ̀ nìkan. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgbà ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò tí à ń wà ní ìrètí àti ìmúrasílẹ̀. Dárápọ̀ mọ́ olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ̀wé Louie Giglio lórí ìrìnàjò Ìpadàbọ̀ yí láti ríi wípé dídúró kò jásí òfò ní àkókò tó bá jẹ́ Olúwa lò ń dúró dè. Ṣe àmúlò àǹfààní yí láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìrètí gbòòrò tí ìrìn-àjò Ìpadàbọ̀ ti ṣètò fún wa. Ní ọjọ́ méje tó ń bọ̀ yí, iwọ́ yíó rí àlàfíà àti ìgbani-níyànjú fún ẹ̀mí rẹ nítorí ìrètí a máa fani súnmọ́ ayẹ́yẹ́!
More