Dídúró Dè Ọ́ Níhìn-ín, Ìrìn-Àjò Ìrètí Ìpadàbọ̀Àpẹrẹ
NÍ DÉÉDÉÉ ÀSÌKÒ TÓ TỌ́
ÌRÒNÚ JINLẸ̀
A ti ṣe ìlérí Olùgbàlà fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run láti ọjọ́ tó ti pẹ́. Wọ́n f'ojú sọ́nà, wọ́n gbàdúrà fún ìdáǹdè. Lẹ́hìn èyí, l'ọ́jọ́ tó yẹ, ní ibi tó yẹ, ati l'ásìkò tó yẹ, a bí Jésù. Bí Ọlọrun kìí tíì dáhùn lásìkò tí àwá bá yàn, A máa dáhùn ní àsìkò tí ó yẹ.
Gbogbo wa ni à ńretí ohun kan, tí a sì ma ńlérò pé bóyá Ọlórun ti gbàgbé wa. Ní àsìkò ìrètí rẹ, jẹ́ kí ìbí Krístì mú ọ l'ọ́kàn le. Nítorípé Ọlọ́run kòì tíí dé (lérò tìrẹ), kò túmọ̀ sí pé Ó ti kọ̀ ẹ́ sílẹ̀. Ẹgbẹ̀rún ọdún, bí alẹ́ kan lórí lójú Rẹ́. Ní ìṣẹ́jú yìí gan an, Ó ń ṣe ohun gbogbo fún ògo Rẹ̀ àti fún rere rẹ. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ kò jọ bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run yóò dá ọ lóhùn lásìkò tó tọ́, ní mímú àwọn ètò Rẹ̀ tí ó ti là kalẹ̀ fún ọ láti ọjọ́ pípẹ́. Má sọ ìrètí nù kí àsìkò tóó tó.
Ní ìrètí nínú ìbí Jésù kí o sì mọ̀ pé Ọlọ́run tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá lásìkò tó yẹ fún ọ, nífẹ̀ẹ́ rẹ, o sì ṣe iyebíye lójúu Rẹ̀.
ÀṢÀRÒ
Gbọ́ Igbe Ayọ̀
Gbọ́ 'gbe ayọ̀! Olúwa dé,
Jésù táa ṣè'lérí;
Kí gbogbo ọkàn múra dèé,
K'ohùn múra k'orin.
Ó dé láti t'òǹdè sílẹ̀,
L'óko ẹrú ẹ̀sù.
'Lẹ̀kùn idẹ fọ́ ń'wáju Rẹ̀,
Ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ irín dá.
Ó dé ìtùnú f'ọ́kàn ìrora,
Ìtùnú f'ágbọgbẹ́,
Pẹ̀lú ìṣúra oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀
Fún àwọn tálákà.
Hosanna, Oba Àlááfìa,
Aó kére bíbọ̀ Rẹ,
Gbogbo ọ̀run yíò máa k'ọrin
Orúkọ táa fẹ́ràn.
Philip Doddridge, 1702–1751
ÀDÚRÀ
Baba, bá mi pàdé ní ààlà ibi tí mo tí ń retí, ní ibi tí mo ti ń f'ojú sọ́nà fún ohun tí kò ì tíì farahàn kedere. Mú kí ọkàn mí parọ́rọ́ kí O sì fún mí ní agbára láti mọ̀ pé O wà nítòsí. Mo gbàgbọ́ pé ètò Rẹ dára. Mo rí èyí nínú ìbí Ọmọ Rẹ kanṣoṣo.
Àmọ́ nígbà míràn mo máa ń tiraka láti rí ju ìkuùkù tó yí mí ká lọ. Fún mí ní ìgboyà titun bí mo ti ń gb'ójú sókè wò Ọ́. Yin Ara Rẹ l'ógo nínú ayé mí ní sáà ìfojúsọ́nà yìí. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgbà ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò tí à ń wà ní ìrètí àti ìmúrasílẹ̀. Dárápọ̀ mọ́ olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ̀wé Louie Giglio lórí ìrìnàjò Ìpadàbọ̀ yí láti ríi wípé dídúró kò jásí òfò ní àkókò tó bá jẹ́ Olúwa lò ń dúró dè. Ṣe àmúlò àǹfààní yí láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìrètí gbòòrò tí ìrìn-àjò Ìpadàbọ̀ ti ṣètò fún wa. Ní ọjọ́ méje tó ń bọ̀ yí, iwọ́ yíó rí àlàfíà àti ìgbani-níyànjú fún ẹ̀mí rẹ nítorí ìrètí a máa fani súnmọ́ ayẹ́yẹ́!
More