Dídúró Dè Ọ́ Níhìn-ín, Ìrìn-Àjò Ìrètí Ìpadàbọ̀Àpẹrẹ
TANI ÈMI YÓÒ BẸ̀RÙ?
ÌWÒYE
Ni aarin ìjàkadì àti ibinu, tẹ ojú rẹ mọ Jésù. O ń jà fún ọ. Èmánuẹ́lì wá ní tosi. Bí ẹ̀sùn tilẹ̀ ń lọ kakiri, tí ọ̀tá dojú ìjà kọ èrò rẹ, bi àwọn ènìyàn bá gbìyànjú láti ké ọ lulẹ̀ kí wọn lé wọ́ orúkọ rẹ ninú ẹrẹ̀, bi a ba gbé ètò kankan dìde tí ìdánwò sì ń bù ramúramù, bi ẹran àrà rẹ bá kùnà tí ó sì ń ké fún ẹ̀san- ìrètí rẹ ń bẹ nínú Ẹni tí ó nja fún ọ. O wa ni ailewu nínú ìfẹ́ Ọlọ́run àti agbára tó ń bẹ nínú orúkọ ńlá rẹ̀.
ÀṢÀRÒ
Ma fòyà láti gbẹ́kẹ̀lé mi nínú ìjì
Ma fòyà láti gbẹ́kẹ̀lé mi nínú ìjì,
Nígbàgbogbo ni mo ń wá ní tòsí.
Mo wà láti fi ẹ̀tù sì ẹ̀rù àìnídi rẹ,
Nígbà náà, ẹ̀yin tí ń ṣe àárẹ̀, má fòyà.
Ègbè
Má fòyà, mo wà pẹ̀lú rẹ,
Má fòyà, mo wà pẹ̀lú rẹ
Má fòyà, mo wà pẹ̀lú rẹ
Mo wà pẹ̀lú rẹ títí dópin.
O lè má dabi ẹni wípé mo wà nítòsí
Bí ó ti lérò pé ó yẹ kí n wa;
Ṣùgbọ́n nínú ìdakẹ́rọ́rọ́ àti nínú ìjì,
Mo nri gbogbo ewu rẹ.
Ègbè
Má fòyà àti gbẹ́kẹ̀le ọwọ́ agbára mi;
O mú ìgbàlà sọkalẹ wa.
Mo jìyà 'pọ̀ láti fún ọ ní ẹ̀mí,
Láti fún ọ l'ádé
Ègbè
J.W. Howe, Ẹsẹ̀ 1–3
ÀDÚRÀ
BABA, Ní àárín ìjì ni ojú ìrètí mi yóò ma wò Ọ́. O n ja fún mi ò sì lágbára jù àwọn ọ̀tá mi lọ. Kọ́ sì ohun kan tó dojú kọ mi lónìí tí ó lágbára jù Ọ́ lọ. Ẹ̀yin ni àpáta tí mo dúró le. Mo dúpẹ́ fún bí Ẹ ti dojú kọ àwọn tó yí mi ká. Fún mi ní àlàáfíà ní ojú àwọn ọ̀tá mi, pelu ìmọ̀ pé Ẹ ń rí mi ẹ sì ń gbéjà mi nínú ìfẹ́ Yín. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgbà ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò tí à ń wà ní ìrètí àti ìmúrasílẹ̀. Dárápọ̀ mọ́ olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ̀wé Louie Giglio lórí ìrìnàjò Ìpadàbọ̀ yí láti ríi wípé dídúró kò jásí òfò ní àkókò tó bá jẹ́ Olúwa lò ń dúró dè. Ṣe àmúlò àǹfààní yí láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìrètí gbòòrò tí ìrìn-àjò Ìpadàbọ̀ ti ṣètò fún wa. Ní ọjọ́ méje tó ń bọ̀ yí, iwọ́ yíó rí àlàfíà àti ìgbani-níyànjú fún ẹ̀mí rẹ nítorí ìrètí a máa fani súnmọ́ ayẹ́yẹ́!
More