Dídúró Dè Ọ́ Níhìn-ín, Ìrìn-Àjò Ìrètí Ìpadàbọ̀Àpẹrẹ

Waiting Here for You, An Advent Journey of Hope

Ọjọ́ 5 nínú 7

WÀ NÍ ÌDÁKẸ́RỌ́RỌ́

Àkókò ìdákẹ́rọ́rọ́ bí a ti ń dúró de Olúwa pẹ̀lú ìrètí.

ÌWÒYÉ

Àwọn àkókò tí kò sí ariwo ò wọ́pọ̀, a sì má nira láti rí ìdákẹ́rọ́rọ́ nígbà míì, àmọ́ gbìyànjú lónì láti ronú nípa Olúwa fún ìṣẹ́jú péréte. Tíráká kí ìwé kíkà má yà ọ̀ l'ọkàn—ṣá wà ní ìdákẹ́rọ́rọ́ kí o sì máa ṣé àṣàrò lórí ẹni tí Jésù ńṣe àti gbogbo ǹkan tó ti ṣe fún ọ. Ronú nípa ìbíi Rẹ̀, ìgbà èwe Rẹ̀, àti bí ìmọ́lẹ̀ ti tàn s'órí ayé yí tó ṣ'ókùnkùn tó sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì. Ronú nípa ikú àti ìrúbọ Rẹ̀, àti ẹ̀bùn ìyè tó fi lọ̀ ẹ́. Ṣe àṣàrò nípa àjíǹde Rẹ̀, nípa agbára Rẹ̀ lórí òkùnkùn àti isà òkú. Pa òùngbẹ rẹ níwájú Rẹ̀ kí o sì ṣàwárí ojú Rẹ̀ nínú ìdákẹ́rọ́rọ́ náà.

ÀṢÀRÒ

Ṣá wà ní ìdákẹ́rọ́rọ́ níwájú Rẹ̀ fún ìṣẹ́jú méló kan. Ronú nípa Jésù kí o sì ní ìgboyà nínú Rẹ̀.

ÀDÚRÀ

Baba, mò ń dúró dè Ọ́ níhìn-ín yìí. Bá mi pàdé nínú ìdákẹ́rọ́rọ́ náà. Bá mi pàdé ní àkókò yí. Bá mi pàdé nínú àti nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ́ àti Ẹ̀mí Rẹ. Àmín.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Waiting Here for You, An Advent Journey of Hope

Ìgbà ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò tí à ń wà ní ìrètí àti ìmúrasílẹ̀. Dárápọ̀ mọ́ olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ̀wé Louie Giglio lórí ìrìnàjò Ìpadàbọ̀ yí láti ríi wípé dídúró kò jásí òfò ní àkókò tó bá jẹ́ Olúwa lò ń dúró dè. Ṣe àmúlò àǹfààní yí láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìrètí gbòòrò tí ìrìn-àjò Ìpadàbọ̀ ti ṣètò fún wa. Ní ọjọ́ méje tó ń bọ̀ yí, iwọ́ yíó rí àlàfíà àti ìgbani-níyànjú fún ẹ̀mí rẹ nítorí ìrètí a máa fani súnmọ́ ayẹ́yẹ́!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Louie Giglio, ẹni tó kọ Dídúró Níhìn Dè Ọ́ (Passion Publishing), fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.passionresources.com