Dídúró Dè Ọ́ Níhìn-ín, Ìrìn-Àjò Ìrètí Ìpadàbọ̀Àpẹrẹ
ÒGO LÓKÈ Ọ̀RUN
IWÒYÉ
Ọlọ́run kò ní ọgba. Kò ní orogún. Kò ní àbùkù. Kò ní àìní. Ó ti wà ṣáájú oún gbógbó, àti ní òpin ọjọ́, Òun ni yóò gbẹ̀yìn oún gbógbó. Ayé kún fún àwọn ọlọrun kéékèèké , ṣùgbọ́n Ọlọ́run wá ni Ó dá àwọn ọ̀run àti ayé. Kò sí ẹnì tí a lè fí wé E. Kò tí ẹ̀ sí ẹni tí ó sún Mọ́.
Nítorínáà, bí o ṣe ń dúró dèé lónìí, fi ìyìn Fún-un. Bóyá oun tí ò n là kọjá tilẹ̀ dàbí pé ó dorí kodò, ṣùgbọ́n ìtẹ́ Rẹ̀ dúró déédé láì sí àní-àní! Yìn ín lógo ní àkókò ìrètí. Gbé E ga nígbà àkókò ìlo sí ọ̀tún àti òsì. Nítorínáà, má béèrè oún púpọ̀ lónìí, ṣá má gbé Orúkọ tó ju gbógbó orúkọ ga. Jẹ́kí Orúkọ yìí fi ìdí ẹ̀mí rẹ múlẹ̀ pẹlú ìdákẹ́jẹ́ fún ọkàn rẹ. Jẹki ìyìn lógo rẹ borí gbógbó àwọn oún tí ó dojú ìjà kọ ìfọkànsìn ati ìfàsíni. Nígbàtí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, orín rẹ́ yíò gbé èrò ọkàn rẹ lọ́ sóke sí ibi tó ga jùlọ.
ÀṢÀRÒ
Ògo lókè ọrùn
Ìwọ ni àkọ́kọ́
Ìwọ lo ṣíwájú
Ìwọ lo kẹ́yìn
Olúwa, Ìwọ ni O tún lè ṣe lẹ́ẹ̀kan sí
Orúkọ Rẹ wà nínú ìmọ́lẹ̀ fún ènìyàn gbógbó láti ríran
Àwọn ogunlọ́gọ̀ ìràwọ kéde ògo Rẹ
Ògo lókè ọrùn
Ògo lókè ọrùn
Ògo lókè ọrùn
Lẹ́yìn Rẹ́ kò sí ọlọ́run míràn
Ìmọ́lẹ̀ ayé
Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ tó ń tàn
Orúkọ Rẹ yóò tàn fún ojú gbógbó láti rí
Ìwọ ni Ẹni náà
Ìwọ ni ògo mi
Kò sì tún sí ẹlòmíràn tó lè bá Ọ figa-gbá-ga
Sí Yín, Ọlọ́run
Gbógbó ayé lápapọ̀ hó . . .
Ògo lókè ọrùn . . . Sí Yín, Ọlọ́run
Gbógbó ayé yóò kọrin ìyìn Rẹ
Òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, oòrùn àti òjò
Gbógbó orílẹ̀-èdè yóò pólóngó
Wípé Ọlọ́run ni Ọ àti pé, O jọba
Ògo, ògo fún Ọ, Olúwa
Ògo, ògo hallelujah
Hallelujah
Chris Tomlin, Matt Redman, Jesse Reeves, Daniel Carson, Ed Cash
ÀDÚRÀ
Bàbá, kíni mba sọ fún yín? Ẹ ò ní ẹgbẹ́ tàbí orógún. Ọ̀rọ̀ mí àti èrò mí kéré jọjọ tí a bá gbé wọn sẹgbẹ́ Yín. Mo tí rí àwọn ìràwọ àsálé, wọn ò tó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ògo Rẹ. Mú kí ìgbàgbọ́ mi gbòòrò sí, sì fún mi ní ọ̀rọ̀ bí mo ṣe nlépà áti darapọ̀ láti kọ orin ìyìn Rẹ.
Gbogbo ìyìn ló jẹ́ tì Rẹ, láti ìsinsìnyí àti títí láíláí. Ń ó rìn nínú òtítọ́ yi lóní. Ń ó gbà eléyìí gbọ́. Má fí hù wà. Má fí gbàdúrà. Ma ṣe ìfi fún ni bí rẹ̀. Ma wá yìn bíi pé kò sí ẹlòmíràn bíi Rẹ́. Àmín!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgbà ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò tí à ń wà ní ìrètí àti ìmúrasílẹ̀. Dárápọ̀ mọ́ olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ̀wé Louie Giglio lórí ìrìnàjò Ìpadàbọ̀ yí láti ríi wípé dídúró kò jásí òfò ní àkókò tó bá jẹ́ Olúwa lò ń dúró dè. Ṣe àmúlò àǹfààní yí láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìrètí gbòòrò tí ìrìn-àjò Ìpadàbọ̀ ti ṣètò fún wa. Ní ọjọ́ méje tó ń bọ̀ yí, iwọ́ yíó rí àlàfíà àti ìgbani-níyànjú fún ẹ̀mí rẹ nítorí ìrètí a máa fani súnmọ́ ayẹ́yẹ́!
More