Dídúró Dè Ọ́ Níhìn-ín, Ìrìn-Àjò Ìrètí Ìpadàbọ̀Àpẹrẹ
ỌLỌ́RUN Ń ṢIṢẸ́ NÍGBÀTÍ À DÚRÓ NÍ ÌRÉTÍ
ÌWÒYÉ
Tí a bá máa sọ òtítọ́, gbogbo wa kórira ìdánidúró. Kódà, ní ọ̀pọ̀ ìgbà a má ń sọ àwọn nǹkan bíi, "Mi ò lérò pé yíò pẹ̀ tó báyìí!" Ó ńgba àkókò tí mi kò ní!" Ó rí bẹ́ẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ nínú wa ka ìdúró sí àkókò fífi ṣ'òfò. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run wa.
Ọlọ́run ńṣiṣẹ́ nígbàtí a wà nínù ìdádúró. Pẹ̀lú nígbàtí ìwọ kò rí ohun tí Ó nṣé. Ọlọ́run máa ńlo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀run àti ayé látí mú ìfẹ́ Rẹ̀ fún ayé rẹ́ ṣẹ́. Gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ̀ tí kìí kùnà - ìfẹ́ tí ó mú Ù láti rán Olùgbàlà lát'ọ́run wa láti rà ọ́ pádà àti láti gbà ọ́ là. Ìpinnu Ọlọ́run fún ayé rẹ kò ní sàì ṣẹ. Ṣé sùúrù, kí o sì mọ̀ wípé ìdádúró kìí ṣe àkókò tó ṣ'òfò nígbàtí à bá ńdúró de Ọlọ́run.
ÀṢÀRÒ
Wá Jésù tí a tí ńretí t'ípẹ́
Wá, Jésù tí a tí ńretí t'ípẹ́
Tí à bí láti tú àwọ́n ènìyàn Rẹ́ sílẹ̀;
Nínú àwọn ẹ̀rù àti ẹ̀sẹ̀ wa, tú wá sílẹ́
Jẹ́ kí á rí ìsinmi wa nínú Rẹ́
Agbára àti ìtùnú Ísráẹ́lì,
Ìwọ́ ní ìrètí gbógbó ayé;
Ìfẹ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tòótọ́,
Ayọ̀ gbógbó ọ́kàn tí ó ńpòngbẹ̀.
Abíi, látí ṣé ìdándé àwọ́n èèyàn Rẹ́,
Abíì bí ọmọ bẹ́ẹ̀ Ọ́bá ní,
Abíi láti j'ọba nínú wá títí láíláí,
Nísíyi Mú ìjọba oréọ̀fẹ́ Rẹ́ wá.
Pẹ̀lú Ẹ̀mí Rẹ tí ó wà láíláí
Má jọ́bà nínú ọkàn wá nìkan;
Pẹ̀lú ẹ̀tọ́ Rẹ tí ó péyé,
Gbé wa sí ìtẹ́ ológo Rẹ.
Charles Wesley, 1707–1788
ÀDÚRÀ
Bàbá, mò ń dúró de Ọ́ níbí. Ọ́kàn mi àti ọwọ́ mi ṣí sí ìfẹ́ àti ètò Rẹ fún ayé mi. Fún mi ní sùúrù tí mo nílò kí o sì tọ́ mi sí òná bí mò ṣe ńdúró. Bí érò ára mi kú díẹ́, mo nígbàgbọ́ pé Ò ń tẹ̀síwájú sí niṣẹ́jú yí, láti ṣe ídáàbò bò, olugbèjà, olùgbémidì, olùpèsè lórí témi. Fún mi ní oréọ̀fẹ́ láti máa gbẹ́kẹ̀le Ọ nínú íjì iyèméjì tí ó ńfẹ́ ní àyíká mi. Ṣe ìdákòrò ọkàn mi nínú Rẹ. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìgbà ìpadàbọ̀ jẹ́ àkókò tí à ń wà ní ìrètí àti ìmúrasílẹ̀. Dárápọ̀ mọ́ olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ̀wé Louie Giglio lórí ìrìnàjò Ìpadàbọ̀ yí láti ríi wípé dídúró kò jásí òfò ní àkókò tó bá jẹ́ Olúwa lò ń dúró dè. Ṣe àmúlò àǹfààní yí láti ṣe ìtúpalẹ̀ ìrètí gbòòrò tí ìrìn-àjò Ìpadàbọ̀ ti ṣètò fún wa. Ní ọjọ́ méje tó ń bọ̀ yí, iwọ́ yíó rí àlàfíà àti ìgbani-níyànjú fún ẹ̀mí rẹ nítorí ìrètí a máa fani súnmọ́ ayẹ́yẹ́!
More