Ọ̀nà Méje Pàtàkì sí Èrò Tí Ó Tọ́Àpẹrẹ

Seven Keys To Emotional Wholeness

Ọjọ́ 7 nínú 7

p>Kọ́kọ́rọ́ 7: Béèrè Ìrànlọ́wọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ

Ìwé mímọ wí fún wa wípé Olùtọ́sọ́na kàn ṣoṣo tíó tọ́ láti gbẹkẹlé ni Ẹ̀mi Mímọ̀. Òún ni o mọ ìtàn wa pátápátá, láti inú oyún títí dé ìsisìn yi, tí ó si mọ ọ̀la wa, láti òní títí ayérayé. O mọ èto àti ìpinnu Ọlọ́run fún wa lóni àti ojoojumọ́ ọjọ́ ayé wa. O si mọ ohún tí o tọ́ àti ohún tí o yẹ fún wa.

Léraléra ní Jésù tọka si Ẹ̀mi náà gẹ́gẹ́ bí “Ẹ̀mi otitọ.” Ṣàkíyèsí ohun tí Ó sọ nípa ìgbòkègbodò Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ: “Yíò ṣamọ̀nà rẹ́ sínú òtítọ́ gbogbo; nitoriti Òún kì yíò sọ̀rọ̀ ti on tikararẹ̀, ṣùgbọn ohunkóhun tí O bá gbọ́, yíò sọ; Òún yíò si sọ ohun ti mbọ̀ fun yin” (Johannu 16:13). Ẹ̀mí òtítọ́ nínú ìgbésí ayé wa dàbí kọ́ńpáàsì ti inú, nígbà gbogbo ní Ó ńtọ́ka wa sí ohun tí Jésù yíò jẹ̀, tí yíò sọ, tàbí ṣe ní ìṣẹ́jú kí ìṣẹ́jú.

Gbogbo ohún tí Jésù ṣe ní a fí hàn láti ọwọ Bàbá. Àwa, pàápàá, gbọ́dọ̀ béèrè lọwọ́ Ẹmi Mímọ kí O fí ìfẹ Bàbá han fún wa. Ènìyàn ti ó ní ìlera èrò-inú lé ni ìbínú, fún àpẹẹrẹ, ṣùgbọ́n nípa bibéèrè lọ́wọ́ Ẹ̀mi Mímọ fún ìtọ́sọ́nà lórí bí o ṣe le kọjú ìbínú yẹn sí ìhùwàsí réré, ènìyàn náà yíò ri ọnà fún ìbínú tí yíò yọrí sí ìbùkún, láì jẹ́ ìpalára. Ènìyàn tí o ní ìlera èrò-inú le ni ìbànújẹ tàbí ìrẹ̀wẹ̀si, ṣùgbọ́n nípa bibéèrè lọwọ́ Ẹ̀mi Mímọ fún ìtọ́sọ́nà, a lé rí ìtọ́sọ́nà sí àwọn àyè títún tí o ní ireti.

Ṣe ìrántí, Ẹ̀mí Mímọ́ ni a fi fún ọ nígbà tí o gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Kristi. Iṣẹ́-ìranṣẹ ti Ẹ̀mi Mímọ̀ ni láti fún ọ ni ìtọ́sọ́nà àti ìmọràn ojoojúmọ, láti ràn ọ lọwọ́ nínú ìrìn ìlànà Olúwa, àti láti ṣe àṣàyàn ọlọgbọn. Ṣe ìbéèrè fún ìrànlọ́wọ́ ti Ẹ̀mi Mímọ ní ojoojúmọ. Béèrè kí O dáàbòbo ọ lọ́wọ́ ibí àti láti tọ́ ọ si ọnà òdodo. Fún U ní ìṣàkóso lórí iṣèto rẹ, àwọn ìpinnu ìpàdé ojoojúmọ rẹ, àti àwọn ẹdun èrò ọkàn rẹ. Gbẹkẹlé láti bá ọ lépa ìlera èrò-inú àti agbára, mímú èrò rẹ wà ní ìlànà pẹlú ìgbésí ayé ẹ̀mi rẹ - odidi ayé tí a pìlẹ rẹ̀ nínú Jésù Krísti.

Ṣe àwárí àwọn èrò kíkà bíi èyí díẹ síi ní intouch.org/plans.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Seven Keys To Emotional Wholeness

Ó kéré jù àwọn ohun méje pàtàkì ló wà tí ó jé pípé nínú ọ̀nà láti wá ohun tí ó dára jùlọ ti Ọlọrun ní fún ìmọ̀lára ayé rẹ. O kò nílò láti tẹ́lẹ̀ àwọn wọ̀nyí ní ṣíṣe è tẹ́lẹ̀. Dara pọ̀ mọ́ Dókítà Charles Stanley bí ó ṣé ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti kọ́ àwọn ìṣesí pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti dàgbà sí púpọ̀ nínú ẹmí àti àwọn ìmọ̀lára rẹ. Ṣe àwàrí àwọn ẹ̀kọ́ kíkà diẹ sii bí èyí ní intouch.org/plans.

More

A fẹ́ dúpé l'ọ́wọ́ In Touch Ministries fún ìpésé ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, ṣe àbẹ̀wò: https://www.intouch.org/reading-plans