Ọ̀nà Méje Pàtàkì sí Èrò Tí Ó Tọ́Àpẹrẹ
Key 5: Ṣe Ìpín Ara Rẹ Pẹlú Àwọn Ẹlòmíràn
Apọ̀jù àyẹwò ara si ìṣòro àti àìlokun le fa ọ láti di ẹni tí ó ngbìnra sínú, aládaníkànṣe. Bí o bá ti fí igbàkiigba ni irun tí o hù sínú irun tàbí ìká ẹsẹ̀, o mọ́ bí nkán kékeré ti kò duró si ojú àmí ara ṣe lè fa ìrora. Ìlànà yìí kànnà wáyé sí ìmọ̀lára àti ẹ̀mí rẹ. O le yíra sínú kí àkókò sọ́ọ da òun ìbàjẹ́ nlá mọ́ ọ lára, bẹ́ẹ gẹ níṣe lo fẹ́ láti mọ ará rẹ àti láti ṣàtúnṣe àwọn ìṣòro rẹ.<\p>
Ìwòsàn tó dára jùlọ fún ọ̀pọlọpọ àwọn ìṣòro ẹdun ọkàn ní láti yíra sí ìta àti láti máà lawọ́ ọrẹ́ fún ẹlòmíràn. O le sọ wipe, "Ṣùgbọ́n èmi kò ni nkankan láti fún ní." Gbogbo ènìyàn ní ohún kàn láti fún ní, bí kò jù ẹrín, ọ̀rọ tútù, tàbí ká fọwọ́ bá ní lejìka ní àkókò àìní. Nígbà míràn, wíwàníhìn rẹ nìkan lè jẹ́ ẹ̀bùn fún ẹnì kàn, pàápà fún àwọn tí wọ́n dá wà, tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀, tàbí tí wọ́n ní àìsàn tí ó ti wà pẹ́ títí. Àwọn ènìyàn aláyọ jùlọ tí mo mọ̀ jẹ́ àwọn tí ọkàn wọn ṣí ti wọ́n sí lawọ́ ọrẹ lọ́pọlọ́pọ sí àwọn ẹlòmíràn. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wà nínu ààbò ìfẹ́ Ọlọ́run. Fífúnni l'ái retí ohunkóhun ní ipáda. Ọlọ́run yíò ri ọkàn rẹ̀ àti ohùn ti o nṣe... yíò si sàn a fún ọ ní ìbámu. Gbẹ́kẹ rẹ́ Lé láti tọjú rẹ.
Nípa fífúnni ní ọ̀fẹ àti lọ́pọlọ̀pọ, o ṣi araàrẹ sílẹ. Ìduro iṣipaya yìí níwájú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn míràn jẹ́ pàtàkì si ìlera ọkàn. Bí o bá ti nṣi ará rẹ nìkàn ní o máa lé kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe gbẹkẹlé, àti ṣe igbẹ́kẹle yìí jẹ́ pàtàkì láti gba idariji òún ìwòsàn Ọlọ́run, àti láti gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run yíò pèsè gbogbo àwọn àìní rẹ.
“Ṣe ìwòsàn aláìsàn, jí òkú dìde, wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, lọ́fẹ̀ ni kí ẹ fi fúnni” (Mátíù 10:8).
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ó kéré jù àwọn ohun méje pàtàkì ló wà tí ó jé pípé nínú ọ̀nà láti wá ohun tí ó dára jùlọ ti Ọlọrun ní fún ìmọ̀lára ayé rẹ. O kò nílò láti tẹ́lẹ̀ àwọn wọ̀nyí ní ṣíṣe è tẹ́lẹ̀. Dara pọ̀ mọ́ Dókítà Charles Stanley bí ó ṣé ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti kọ́ àwọn ìṣesí pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti dàgbà sí púpọ̀ nínú ẹmí àti àwọn ìmọ̀lára rẹ. Ṣe àwàrí àwọn ẹ̀kọ́ kíkà diẹ sii bí èyí ní intouch.org/plans.
More