Ọ̀nà Méje Pàtàkì sí Èrò Tí Ó Tọ́Àpẹrẹ
Ohun pàtàkì Kejì: Rẹ́ ara rẹ sínú Ìwé Mímọ́
Nígbàtí o ba gba ìdáríjì, o tí dì ẹdá titun níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò tó láti jẹ́ mímọ́. O gbọ́dọ̀ béèrè lọwọ Olúwa láti kọ òtítọ rẹ̀ sí órí ọkàn rẹ̀. O nílò lati ní ìwà rere Ọlọ́run sínú rẹ̀. O gba òtítọ Ọlọ́run nípa gbogbo ipò àti nípasẹ̀ kíkà ọrọ rẹ̀. O nílò láti rẹ́ ara rẹ̀ sínú èrò Ọlọ́run, àti ní àgbègbè ìlera tí ẹ̀mí, èyí túmọ̀ sí pé kí ó rẹ́ ara rẹ̀ sínú èrò Ọlọ́run nípa rẹ̀.
Nínú Ìwé Mímọ́, ìwọ yóò rí pé o jẹ́:
. Ọmọ Ọlọ́run.Gálátíà 3:26-27 sọ pé: “Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù. Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀.” Àti pé 1 Jòhánù 5:1 tún fi dá wa lójú pé "Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jésù ni Kristi, a bí I nípa tí Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ pẹ̀lú."
. Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wà pátápátá. Mímọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí o ṣe jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, tí O sí tẹ́wọ́ gbà ọ̀ pátápátá, ó jẹ́ kí ó ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ìṣe 10:34-35 kọ́ wa pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn, Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀”
. Ajogún Bàbá nípasẹ̀ Kristi Jésù. Níkẹyìn, mímọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé gẹ́gẹ́ bí a ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́ àrólé rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi mú kí ọkàn rẹ́ balẹ̀, ó sì mú ìgbésẹ̀ tí ó dájú sí ọ̀nà ìlera àti àlàáfíà rẹ́. Gálátíà 3:29 àti Títù 3:7 ṣèlérí pé bí a bá jẹ́ ti Kristi, a jẹ́ pé ìran Ábúrámù ni wá; ajogún gẹ́gẹ́ bí ìlérí; àti pé, a jẹ́ olódodo nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, a sọ dì ajogún gẹ́gẹ́ bí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.
Ọpọlọpọ àwọn àpèjúwe mìíràn ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí ó farahàn nínú ìwé mímọ́ ná wà. Máa ṣé àṣàrò lé orí ọ̀rọ̀ rẹ̀, béèrè kí ó tàn ìmọ́lẹ̀ èrò ìyanu rẹ̀ nípa rẹ́ sí ọ́. Ṣe àkójọ àwọn èrò nà tàbí yí wọ́n ká bí o ṣe n ká Bíbélì rẹ̀ lojoojúmọ́. Tí o ba tí dì atúnbí nípasẹ̀ Kristi Jésù, gbogbo àwọn àpèjúwe wọ̀nyí nípa àwọn ọmọ Ọlọ́run kan sí ọ́ … kà wọ́n gẹ́gẹ́bí àpèjúwe nípa rẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí
Ó kéré jù àwọn ohun méje pàtàkì ló wà tí ó jé pípé nínú ọ̀nà láti wá ohun tí ó dára jùlọ ti Ọlọrun ní fún ìmọ̀lára ayé rẹ. O kò nílò láti tẹ́lẹ̀ àwọn wọ̀nyí ní ṣíṣe è tẹ́lẹ̀. Dara pọ̀ mọ́ Dókítà Charles Stanley bí ó ṣé ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti kọ́ àwọn ìṣesí pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti dàgbà sí púpọ̀ nínú ẹmí àti àwọn ìmọ̀lára rẹ. Ṣe àwàrí àwọn ẹ̀kọ́ kíkà diẹ sii bí èyí ní intouch.org/plans.
More