Ọ̀nà Méje Pàtàkì sí Èrò Tí Ó Tọ́Àpẹrẹ

Seven Keys To Emotional Wholeness

Ọjọ́ 6 nínú 7

Kọ́kọ́rọ́ 6: Yé Dúró lórí Àwọn Ikùna Tí o tí Kọjá

Ìṣẹgun jẹ́ ifẹ Ọlọ́run fún ìgbésí ayé onígbàgbọ. Ṣùgbọ́n nígbà míràn a le rii ará wa wipé a ńṣubú lera sínú àwọn ẹ̀ṣẹ kànna. Nìdí èyí, ìgbésí ayé wa lé ni apá ìlérí àimúṣẹ láti fí òpin sí ìwà àìtọ́. A sọ fún Olúwa wípé a fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n ìfẹ́-ọkàn wa sábà máa ń dín kù nígbà tí ìwà òdodo kò bá rọrùn mọ́, tí kó ládùn mọ́, tí kó mére wá. Ni ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn onígbàgbọ bínú si Ọlọ́run fún ìdádúró ìṣẹgun, ṣùgbọ́n nígbàgbogbo ẹ̀ṣẹ jẹ́ òún tí a yàn - kìí ṣe tí Olúwa.

Nígbàtí a bá ṣe ìronú piwàda ẹ̀ṣẹ wa nítootọ, tí a béèrè idariji Olúwa, tí a si gbẹkẹlé Krísti alàaye láti fún wa ní agbára, a ṣẹ̀dá ipá àgbàrá ogún si sàtani àti àdánwò. A borí awọn Ikùna wa nígbà ti a ba ranti wípé Jésù Krísti ni orísun ti ìgbésí ayé wa, Ọlọ́run si da wa lójú wípé ìṣẹgun yíò jẹ́ tiwá nígbàtí a bá gbára wa Le.

Apá kàn làti gbà idariji Ọlọ́run àti gbé nínú ìṣẹgun ní láti dariji ará rẹ. Ní kété tí Ọlọ́run bá ti dáríjì ọ, iwọ kò ní ẹtọ́ sí àwọn ẹ̀ṣẹ rẹ ti o ti kọjá, Ikùna, tàbí àìlera rẹ. O jẹ ẹ̀da títún nínú Krísti Jésù (2Kọ 5:17). Nigbakigba tí iwọ bá ronú àwọn ikùna rẹ tí o ti kọjá, iwọ npa ọkàn rẹ de sí áwọn Ìbùkún tí Ọlọ́run ní nfipamọ fún ọ. Dípò bẹ́ẹ̀ ronú ọpọ́ àwọn ọna tí Bàbá tí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ tí o si ṣe ibukún fún ìgbésí ayé rẹ. Nígbakígba ti ọkàn bá fẹ́ ṣe àṣàrò àwọn ikùna tí o ti kọjá, ṣe ìrántí wípé Ọlọ́run tí gbà ọ lọwọ́ ẹ̀ṣẹ. Lẹhinna, yi ọkàn rẹ si àwọn ohun ọ̀tún ti O ti ṣe fún ọ, tí O ṣe sí ọ, àti nípasẹ rẹ. Bẹ̀rẹ̀ sí yín fún òòrè Rẹ̀, láì fí ọkàn sí ẹ̀ṣẹ tí o dè ọ ní ìdè.

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Seven Keys To Emotional Wholeness

Ó kéré jù àwọn ohun méje pàtàkì ló wà tí ó jé pípé nínú ọ̀nà láti wá ohun tí ó dára jùlọ ti Ọlọrun ní fún ìmọ̀lára ayé rẹ. O kò nílò láti tẹ́lẹ̀ àwọn wọ̀nyí ní ṣíṣe è tẹ́lẹ̀. Dara pọ̀ mọ́ Dókítà Charles Stanley bí ó ṣé ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti kọ́ àwọn ìṣesí pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti dàgbà sí púpọ̀ nínú ẹmí àti àwọn ìmọ̀lára rẹ. Ṣe àwàrí àwọn ẹ̀kọ́ kíkà diẹ sii bí èyí ní intouch.org/plans.

More

A fẹ́ dúpé l'ọ́wọ́ In Touch Ministries fún ìpésé ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, ṣe àbẹ̀wò: https://www.intouch.org/reading-plans