Ọ̀nà Méje Pàtàkì sí Èrò Tí Ó Tọ́Àpẹrẹ

Seven Keys To Emotional Wholeness

Ọjọ́ 1 nínú 7

Kọ́kọ́rọ́ èkíní: Jọ̀wọ́ Ọkàn Rẹ Fún Kristi

Ìràpadà ẹ̀mí ni kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́ làti mú ìdàgbàsókè bá ẹni rere tí a jẹ́ ní àwùjọ. Àwọn ènìyàn tí kò mọ Kristi lè fi ọwọ́ sọ̀yà pẹ̀lú èrò pé àwọn ní ayé tiwọn lọ̀tọ́ fúnra wọn, ṣùgbọ́n wọn kò ní lè fi ẹnu ọ̀rọ̀ náà jóná tí wọn ba jẹ́ olóòtọ́. Púpọ̀ nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn ti ní ànító fúnra wọn àti pé wọn kò nílò Kristi ni wọn yíò jẹ oníròbìnújẹ́ ènìyàn ní àsìkò tí rògbòdìyàn bá dé bá wọn. Wọ́n dà bíi èpò tí ó ní òdòdó tí ó rẹ́wa tí kò ní gbòngbò tí ó lè mú dúró gbọin-gbọin. Àwọn fúnra wọn kàn gbé ara lé agbára, okun, ìmóríyá, àti ojú ọ̀nà tí wọn ní. Àṣẹ̀yìnwá-àṣẹ̀yìnbọ̀, wọ́n rí òkodoro ara wọn bí wọ́n ṣe rí. Wọn kò ní Ẹ̀mí Mímọ́ nínú wọn láti sọ wọ́n di alágbára nínú Kristi ní ọ̀nà tí ó lè mú ìtura dé bá wọn tí ó sì dá lórí òtítọ́, pàápàá ní àkókò ìbáwí wọn.

Níní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jésù Kristi á máà yanjú ọ̀pọ̀ nnkan tí ó sọ ìlera pípé wa di aláìlera:

· Ìmọ̀lárá ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó wáyé ní ìgbà tí ẹ bá ní ẹ̀ṣẹ̀ tí a kò dárí rẹ jì yín. Ní ìgbà tí ẹ bá tọ́rọ́ ìdáríjì ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹ̀yin yíò sì rí ìdáríjì gbà. A sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ yín nù kúrò (Róòmù 8:1).

· Ìmọ̀lárá ẹni tí kò ní ìfẹ́. Ní ìgbà tí ẹ bá padà sì ọ̀dọ Kristi, ẹ gbọ́dọ̀ gbà pé Ọlọ́run fẹ́ràn yín àti wípé Ó fẹ́ láti ní ìbásepọ̀ ayérayé pẹ̀lú yin(Róòmù 8:38-39).

· Níní ẹ̀mí ìgbẹ̀san sí àwọn ẹlòmíràn Ní ìwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin bá ti gba ẹ̀bùn ìgbàlà Ọlọ́run ní ọ̀fẹ́, ó yẹ kí ó jẹ́ mímọ̀ fún yín pé Ọlọ́run fẹ́ láti dáríjì àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún yín, Ó nífẹ̀ẹ́ láti ṣe fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú, láì ká ohun tí ó ti ré kọjá ní ìgbé ayé wọn sí. (Kólósè. 3:13).

· Ìtiraka láti bá ojú rere Ọlọ́run pàdé. Ẹ̀bùn ìgbàlà Ọlọ́run jẹ́ ọ̀fẹ́ fún yín. Ẹ̀yin kò lè ṣiṣẹ́ fún-un, tàbí rà, tàbí ríi gbà nípa iṣẹ́ rere yín. Èyí kò tọ́ síi yín. Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di àtúnbí nínú ẹ̀mí, ẹ ní láti gbà wí pé ojú rere tí ẹ bá ní pẹ̀lú Ọlọ́run dá lórí ohun tí Kristi ti ṣe parí (Éfésù 2:8-9).

Tí ẹ bá fẹ́ ní ìmọ̀lára ìlera pípé ní ònìí, ẹ fi ayé yín fún Kristi. Ní kété tí ẹ bá ti gba Kristi Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà yín, dandan ni kí ẹ tèlé Ẹ gẹ́gẹ́ bíi Olúwa yín. Ọ̀nà láti tẹ̀lé Kristi yí ṣe àwọn àfikún bíi ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀mí yín ní ojoojúmọ́ tí ó ṣe pàtàkì fún ìlera ẹ̀mí yín gẹ́gẹ́ bíi ìwẹ̀ yín ní ojoojúmọ́ ṣe jẹ́ ìlera tí ara rẹ pẹ́lù. Kí ẹ̀yin kọ́kọ́ wá ìdáríjì ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún iṣẹ́da ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ́hìn náà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ dá bí ẹ ṣe ń télè Kristi.

Kí ẹ rántí wí pé, kò sí ẹni tí ó ní agbára láti tẹ̀lè Kristi ní pípé. Àṣìṣé kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ àti èyí tí a mọ̀ọ́mọ̀ àti èyí tí a kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe—nnkan tí àwọn ẹlòmíràn pè ní àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mú àṣẹ dání àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a rénà wọn. Irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí tí ó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ yí ni ẹ ní láti tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún. Àti ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe èyí, Baba olùfẹ́ yín tí Ó mbẹ ní ọ̀run ṣe ìlérí láti mú oore-ọ̀fẹ́ àti ojú àánú Rẹ̀ gbòòrò dé ọ̀dọ̀ yín. (Éfésù. 1:7).

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Seven Keys To Emotional Wholeness

Ó kéré jù àwọn ohun méje pàtàkì ló wà tí ó jé pípé nínú ọ̀nà láti wá ohun tí ó dára jùlọ ti Ọlọrun ní fún ìmọ̀lára ayé rẹ. O kò nílò láti tẹ́lẹ̀ àwọn wọ̀nyí ní ṣíṣe è tẹ́lẹ̀. Dara pọ̀ mọ́ Dókítà Charles Stanley bí ó ṣé ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti kọ́ àwọn ìṣesí pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti dàgbà sí púpọ̀ nínú ẹmí àti àwọn ìmọ̀lára rẹ. Ṣe àwàrí àwọn ẹ̀kọ́ kíkà diẹ sii bí èyí ní intouch.org/plans.

More

A fẹ́ dúpé l'ọ́wọ́ In Touch Ministries fún ìpésé ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, ṣe àbẹ̀wò: https://www.intouch.org/reading-plans