Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runÀpẹrẹ
Kàn Sọ Pé Bẹ́ẹ̀kọ́
Gẹ́gẹ́bí Mákù ti ṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́-ìránṣẹ́ Jesu, ó ṣe àfihàn Olùgbàlà lẹ́nu isẹ́ ìmúláradá, lílé àwọn ẹ̀mí eṣù jáde láti ọ̀dọ̀ ọ̀kùnrin kan nínú sínágọ́ọ̀gù àti ìwòsàn ìyá-ìyàwó Pétérù ní ilè rẹ̀ ní Kápánọ́mù. Nì ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kannáà, “àwọn ènìyàn kó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn aláìsàn àti àwọn tí ó ní ẹ̀mí eṣù tọ Jésù wà. Gbogbo ìlú pé jọpọ̀ ní ẹnu-ọ̀nà Jésù sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ l'áradá ”
Kò jẹ́ ìyàlẹ́nu, ní òwúrọ̀ ọjọ́ Kejì àwọn ọmọ-ẹ̀hìn náa sáré tọ Jésù wà, wọ́n sì sọ pé, “ Gbogbo ènìyàn ń wá Ọ!” Ní kedere, gbogbo ìlu ti rí agbára ìyanu ìmúláradá tí Jésù ṣe, wọ́n sì fẹ́ kí irú bẹ́ẹ̀ tún tẹ̀ síwájú ní ọjọ́ kejì. Ṣúgbọ́n Jésù sọ pé rárá. Nínú ohun tí o jọ kàyéfì fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn, Jésù sọ pé, “Jẹ́ kí á tẹ̀síwájú sí àwọn abúlé tí ó wà ní àyíká kí n'lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Fún ìdí èyí ni Mó ṣe wa.”
Èyí ni àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n kìí ṣe ìgbà ìkẹhìn tí Jésù yíò sọ wípé “rárá” nínú àwọn ìhìnrere. Kíni ìdí tí Jésù fí sọ "rárá"? Ó hàn gbangba pé Jésù ní agbára láti mú àwọn ènìyàn lára dá sí. Bẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ ní ó ní ìfẹ́ láti dín ìrora kù ní ìgbésí ayé àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n bí ó ti wú Jésù láti wò àwọn ènìyàn díẹ̀ sàn síí, Ó mọ̀ wípé Òun ní àkókò kékéré lori ilẹ̀ ayé láti mú ''ìdí tí Ó fí wá s'áyé" ṣẹ. Jésù kò wá sí ayé láti kàn mú ní lára dá àti láti ṣ'àfihàn ìdánimọ̀ Rẹ̀. Ó wá láti wàásù ìhìnrere ní ìgbáradì fún ìtara ìdojúkọ Rẹ̀ lórí àgbélèbú. Jésù ṣe àfihàn kédéré pàtàkì ìdí tí òhun fi wá sí ode ayé, èyi si tọ́kasí ìdí ti Ó fí sọ wípe rárá sí àwọn óhún tí ó dára kí Ó bàa lè rí àyè láti dojú kọ pàtàkì ohun tí Ó fí wá sí ayé.
Ní ìwọ̀n ìgbà tí Jésù kò sọ pé bẹ́ẹ̀ni fún ohunkóhun bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ àwa náà kò lè sọ bẹ́ẹ̀ni. Ìwọ àti èmi ní àkókò àti àwọn orísun tó kéré jọjọ. Láti lo àkókò kékeré tí ó kú fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ó ṣé dandan fún wa láti rí dájú pé á ṣe iṣẹ́ tí a gbàgbọ́ pé Ọlọ́run gbé lé wá lọ́wọ́ láti ṣe àti láti jẹ kí ó mọ́ wa lára láti yẹ̀ba fún àwọn ohun wọ́nnì tí ó dára gan-an, ṣùgbọ́n tí ó lè ṣe ìdíwọ́ fún isẹ́ tí a gbé lé wa lọ́wọ́.
Rántí wípé o wà láàyè fún ìdí kan! Mo gbàdúrà pé àwọn Ìwé-mímọ́ tí a ti ṣàwárí wọn ní ọjọ́ mẹ́fà sẹ́hìn yíò jẹ́ ìpèníjà fún wa láti jẹ́ ọlọgbọ́n nípa bí a ṣe ń lo àkókò ti ó kù fún wa lórí ilẹ̀ yìí, lílo àwọn wákàtí ìkẹ́hìn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, fẹ́ràn àwọn mìráàn, àti láti jèrè ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì nípasẹ̀ ìgbésí-ayé wa àti iṣẹ́ wa.
Tí o bá gbàdùn ètò kíkà yìí, ìwọ yíò nífẹ̀ sí ètò Bíbélì ìfọkànsìn ọlọ́sọ̀sẹ̀ mi, yíò sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti túnbọ̀ so ìhìnrere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ rẹ F'orúkọ-sílẹ̀ níbí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ṣé ó t'ojú sú ọ pé kò sí ju wákàtí mẹ́rinlélógún lọ nínú ọjọ́? Gbogbo ǹkan di ìkàyà fún ọ nítorí oye àwọn iṣẹ́-àkànṣe tó yẹ kí o ṣe? Ṣe ó sú ọ pé gbogbo ìgbà ni ó maá ń rẹ̀tí o kò sì ní àkókò tó láti lò nínú Ọrọ̀-Ọlọ́run àti pẹlú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ? Eléyìí lè jẹ́ ìdojúkọ tí ó wọ́pọ̀ jù l'áyé. Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé Bíbélì fún wa ní àwọn ìlànà tí a lè lò láti ṣ'èkáwọ́ àkókò wa dáadáa. Ètò-ẹ̀kọ́ yìí yíó fẹ àwọn Ìwé-mímọ́ wọ̀nyí l'ójú yíó sì fún ọ ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó wúlò fún bí wàá ṣe lo àwọn àsìkò tó kù l'áyé rẹ dáadáa!
More