Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runÀpẹrẹ
Gbá Àwọn Ìfarajì Rẹ Jọ
Jésù pàṣẹ pé kí “Bẹ́ẹ̀ni” wa jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ni,” ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti léraléra “Bẹ́ẹ̀ni” Krìstíẹ́nì túmọ̀ sí “Bẹ́ẹ̀kọ́.” Gbogbo ìgbà tì a bá kùnà láti mú ìfarajì wa ṣẹ, a pẹ́ẹ́ dé, a kò tètè parí iṣẹ́ l'ásìkò, tàbí a kùnà láti mú ọ̀rọ̀ tí a ká sílẹ̀ lórí ẹ̀rọ fóònù wa ṣẹ pé “màá pè ọ́ padà láìpẹ́,” à ń ṣe àìgbọnràn sí àṣẹ Jésù pé kí gbogbo “Bẹ́ẹ̀ni” wa jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ni.” Ní ìgbé-ayé mároṣẹ̀ tí à ń gbé, à ń sọ pé “Bẹ́ẹ̀ni” ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, nígbà tó jẹ́ pé léraléra ni à ń kùnà láti mú ọ̀rọ̀ wa ṣẹ. Pé irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí farasin nínú ìjọ̀ yẹ kó kọ́ wa l'óminú. Àwòrán Ọlọ́run ní wá, aṣojú Jésù Krístì fún ayé tó ti sọnù. Láti jẹ́ aṣojú Olùgbàlà wa nítòótọ́, a ní láti jẹ́ ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.
Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè mú èyí ṣe gan an? Ó bẹ̀rẹ̀ ní ibi kí a ní ètó tí a ó fi ṣe àkójọ gbogbo ìfarajì wa. Èyí lè jẹ́ ohun tí ó rọrùn bíi kí á lo tákàdá tàbí ohun to tún lọ́ jáí díẹ̀ bíi ẹ̀rọ́ abáni-mójútó-iṣẹ́ bíi OmniFocus. Irin-iṣẹ́ tí a lò kò ṣe pàtàkì bíi ìgbésẹ̀ náà. Bí a bá fẹ́ẹ́ tẹlé àṣẹ Jésù pé kí “Bẹ́ẹ̀ni” wa jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ni,” a ní láti ní ọ̀nà láti máa t'ọpa ohun gbogbo tí à ń sọ “Bẹ́ẹ̀ni” sí. Èyí jọ pé ó bá ọgbọ́n-orí mu, àbí? Bẹ́ẹ̀ ló rí! Ṣùgbọ́n ohun ìbànújẹ́ ni pé, ènìyàn péréte ni ó ń ṣe èyí dáadáa. Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni pé, ìṣòro tó rọrùn láti yanjú ni.
Ní àkókò kan lónìí, lo ọgbọ̀n ìṣéjú láti ṣe “àkódàálẹ̀-ọkàn” fún gbogbo ìfarajì tí o tí ṣe fún ara rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ọkọ tàbí ìyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn alájọṣiṣẹ́pọ̀ rẹ, àti bẹ́é bẹ́ẹ̀ lọ. Ní kété tí o bá ti parí àkọsílẹ̀ rẹ, wo àwọn ìfarajì tí o ní láti ṣe àtúnsọ wọn tàbí tí o ní láti múṣe ní kíá. Fún àpẹẹrẹ, bóyá o ṣ'èlérí fún ìyá-àgbà rẹ pé wàá kàn sí wọn l'ọ́sè tó kọjá tí o kò ì tíì ṣe bẹ́ẹ̀. Ló ìṣéjú márùn-ún kí o fi kàn sí ìyá-àgbà kí o sì mú ìlérí rẹ ṣẹ. Jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ni” rẹ jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ni” kódà nígbàtí ó bá pẹ́ ọ. Mo ṣ'èlérí pé, lọ́gán tí o bá ti gbé ìgbésẹ̀ yìí tí ó sì dá ọ lójú pé gbogbo rẹ lọ ti kó kúrò l'ọ́pọlọ, wàá ní ìbàlẹ̀-ọkàn tó ga jù àti àlááfíà.
Ìwé David Allen, Getting Things Done, ní ohun èlò tó dára jù tí mo ti rí tí ó ń ran ni lọ́wọ́ láti tọ ipaṣẹ̀ gbogbo ìfarajì ẹni. F'ọwọ́tọ́ ibí láti gba àkásílẹ̀ àkọtọ́ ṣókí ìwé náà áti àwọn ìtanilólobó lóríi bí a ṣe ńṣeé tí “Bẹ́ẹ̀ni” ẹni fií jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ni.” nígbà gbogbo
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ṣé ó t'ojú sú ọ pé kò sí ju wákàtí mẹ́rinlélógún lọ nínú ọjọ́? Gbogbo ǹkan di ìkàyà fún ọ nítorí oye àwọn iṣẹ́-àkànṣe tó yẹ kí o ṣe? Ṣe ó sú ọ pé gbogbo ìgbà ni ó maá ń rẹ̀tí o kò sì ní àkókò tó láti lò nínú Ọrọ̀-Ọlọ́run àti pẹlú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ? Eléyìí lè jẹ́ ìdojúkọ tí ó wọ́pọ̀ jù l'áyé. Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé Bíbélì fún wa ní àwọn ìlànà tí a lè lò láti ṣ'èkáwọ́ àkókò wa dáadáa. Ètò-ẹ̀kọ́ yìí yíó fẹ àwọn Ìwé-mímọ́ wọ̀nyí l'ójú yíó sì fún ọ ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó wúlò fún bí wàá ṣe lo àwọn àsìkò tó kù l'áyé rẹ dáadáa!
More