Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ṣe Ìfilọ́lẹ̀ Àwọn Ààlà Rẹ
Nínú gbogbo àwọn ìhìn rere, ti Mátíù, Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù ló ṣe àfihàn iye àkókò tí Jésù fi dá wà—kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn, èrò tó yí I ká, àti ìsáré sókè-sódò tó jẹmọ́ iṣẹ́-ìránṣẹ́ Rẹ̀. Iye ìgbà tí wọ́n mẹ́nuba ìhùwàsí yìí fihàn wípé Jésù pójú ìwọ̀n nípa pípa ààlà pẹ̀lú ṣíṣe àmúlò àkókò Rẹ̀. Bákan náà, tí a bá máa ṣe àmúlò àkókò wa bó ti yẹ àti láti ní ipa rere láyé, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn àlá tó nípọn sí àwọn ètò wa.
Bíi Jésù, a ní láti bẹ̀rẹ̀ èyí pẹ̀lú fífi àkókò sílẹ̀ fún àdúrà déédéé (Máàkù 1:35) àti aṣóró nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Púpọ̀ nínú wa ní sísan ìdá-mẹ́wàá owó kò ṣ'àjèjì sí. Àmọ́ ìdá-mẹ́wàá àkókò wa ńkọ́? Tí a bá dá gbogbo ètò wa lórí iṣẹ́ òjọ́ àti iṣẹ́-ilé tí a wá ń tiraka láti gbàdúrà tàbí ṣe àṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ti dẹ páńpẹ́ ìkùnà sílẹ̀ fún ara wa nìyẹn. Kí o tó tẹ̀síwájú nínú ètò kíkà yìí, ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣe ìpinnu iye ìdá-mẹ́wàá àkókò tí o máa ma lò fún àdúrà àti ẹ̀kọ́ Bíbélì lójojúmọ́.
Lẹ́yìn tí o bá ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ààlà yí sínú ètò ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí, ó máa ṣe àǹfààní láti gbé irú ìgbésẹ̀ yí fún àkókò rẹ ní ilé àti ibiṣẹ́. Èmi gẹ́gẹ́bí ẹnìkan, ààlálẹ̀ tí mò ń tẹ̀lé déédéé ràn mí lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ àti gb'áyé mi ní “ìwọ̀tún-wòsì.” Fún púpọ̀ nínú ọjọ́ inú ọ̀sẹ̀, mo máa lọsí ibiṣẹ́ ní ago mẹ́rin-àbọ̀ ní ìdájí mo sì máa padà s'ílé ní ago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́. Irúfẹ́ ètò yí, tí a lè ṣe àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, fún mi ní àwọn ààlà tó dájú fún ìpọkànpọ̀ ní ìdí iṣẹ́ mi. Ṣé mo máa ń parí iṣẹ́ mi ní gbogbo ìgbà bí? Rárá. Bákan náà ni yó sì rí tí mo bá ṣiṣẹ́ di agogo márùn-ún, mẹ́fà, tàbí mẹ́wàá ní àṣálẹ́. Kòsí ǹkan tó ń jẹ́ iṣẹ́ parí. Ṣíṣe ìfilọ́lẹ̀ ààlà nípa ìgbà tí iṣẹ́ òjọ́ parí fún mi ní àǹfààní láti lo àkókò pẹ̀lú aya, àwọn ọmọ, àti ìjọ Ọlọ́run.
Tí o kò bá múu bí ojúṣe láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ààlà fún ètò rẹ, ẹlòmíràn ma ṣeé fún ọ. Bí o kò bá tíì bẹ̀rẹ̀ títí di àkókò yí, tẹ̀lé ìdarí Jésù láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ààlà tó ní ìtumọ̀ tó máa dárí àmúlò àkókò rẹ. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nìyí fún ọ láti ní àkóso lórí kalenda àti àkókò rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣé ó t'ojú sú ọ pé kò sí ju wákàtí mẹ́rinlélógún lọ nínú ọjọ́? Gbogbo ǹkan di ìkàyà fún ọ nítorí oye àwọn iṣẹ́-àkànṣe tó yẹ kí o ṣe? Ṣe ó sú ọ pé gbogbo ìgbà ni ó maá ń rẹ̀tí o kò sì ní àkókò tó láti lò nínú Ọrọ̀-Ọlọ́run àti pẹlú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ? Eléyìí lè jẹ́ ìdojúkọ tí ó wọ́pọ̀ jù l'áyé. Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé Bíbélì fún wa ní àwọn ìlànà tí a lè lò láti ṣ'èkáwọ́ àkókò wa dáadáa. Ètò-ẹ̀kọ́ yìí yíó fẹ àwọn Ìwé-mímọ́ wọ̀nyí l'ójú yíó sì fún ọ ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó wúlò fún bí wàá ṣe lo àwọn àsìkò tó kù l'áyé rẹ dáadáa!
More