Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runÀpẹrẹ
Ìṣòro Ṣíṣe Àkóso Àkókò Wa
A máa ń bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ mi lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí bí a ṣe ń ṣàkóso àkókò ẹni. Kìí ṣe nítorí pé mo ní ìdáhùn gbòógì lóríi rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí pé mo ti ní oríṣiríṣi ìrírí tó lóòrìn nípa bí mo ṣe ń ṣàkóso onírúurú àwọn iṣẹ́ tó lérè tí mò ń dáwọ́lé. Yàtọ̀ sí pé mo jẹ́ aláṣẹ àgbà pátápátá fún ilé iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ láti máa fi owópaowó, mo jẹ́ olùkọ̀wé, mo sì tún ń tiraka láti ran àwọn ọmọlẹ́hìn Kristì bíi tèmi lọ́wọ́ láti so ìhìnrere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ wọn. Ní ilé, ọkọ ìyàwó ni mí mo sì jẹ́ bàbá fún àwọn ọmọdébìnrin méjì tó wuyì tí wọ́n kò tíì ká ọdún mẹ́ta lọ́jọ́ orí. Ìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ ni tí a bá sọ pé ayé ti dorí kodò lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Ṣùgbọ́n nípa oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkan, mò ń lè ṣàkoso gbogbo nnkan, mo sì tún ń lè sùn oorun wákàtí méje sí mẹ́jọ lálaalẹ́ bákan náà.
Ṣíṣàkóso àkókò mi lọ́nà tó dára ti jẹ mí lógún láti ọjọ́ tó pẹ́. Kínni ìdí? Nítorí pé Bíbélì rán wa létí lọ́pọ̀ ìgbà pé ọjọ́ ayé wa dàbí ìkùukùu, "tí ó wà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà tí kò ní sí mọ́ (Jakobu 4:14). Ó ní ìdí kan tí Ọlọ́run ṣe fi ìwọ àti èmi sinú ayé: kí á fẹ́ Ẹ, kí á fẹ́ ará yòókù, kí á sì máa jèrè ọmọ ẹ̀hìn fún Krístì. A ò kàn wà lásán. A kò dá wa láti kàn jókò kalẹ́ ká máa retí ayérayé. A pè wá láti kó ipa láyé, k'á fi àṣà lélẹ̀, k'á fi ayé wa àti iṣẹ́ ọwọ́ wa sin àwọn t'ó yí wa ká. Ní kúkúrú, Ọlọ́run pè wá láti darapọ̀ mọ́ Òun nínú iṣẹ́ àfojúsùn Rẹ̀ láti ra ayé padà.
Pẹ̀lú bí iṣẹ́ àfojúsùn yìí ṣe lóòrìn tó tí àkókò sì ń lọ́ pẹ̀lú, ó yẹ́ kí á jẹ́ ẹni tí ó fọkàn sí ìdí wa, kí á máa gbé bí ẹni pé àkókò kò pọ̀ mọ́, nígbà gbogbo kí á máa wá ọ̀nà láti lo àkókò tí a fún wa lọ́nà tó dára. Ìdí nìyí tí o fi ń ka È̩kọ́ Àṣàrò Bíbélì yìí! Fún ọjọ́ melò kan, a ó jọ máa tú inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ṣàwárí àwọn ìlànà bí a ṣe ń ṣàkóso àkókò gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti gbé e kalẹ̀. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ẹ pé ìlànà yìí kò rọrùn o. T'ó bá rọrùn ni, gbogbo wa ìbá ti má máa jìjàkadì pẹ̀lú rẹ̀ nígbà gbogbo. Lópin ohun gbogbo, àṣeyọrí nípa ṣíṣàkóso àkókò dá lórí àìṣèmẹ́lẹ́ àti ìjánu (Owe 21:5). Gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i, kíkóra ẹni nìjánu pẹ̀lú àkókò yóò fún wa ní ànfààní láti lọ́wọ́sí ohun t'ó ń lọ láyé ní ipò Olúwa àti Olùgbàlà wa. Ṣé o ti ṣetán láti lo ìwọ̀n àkókò tí Olúwa fi fún ọ lọ́nà tó dára?Jẹ́ k'á bẹ̀rẹ̀!
Nípa Ìpèsè yìí
Ṣé ó t'ojú sú ọ pé kò sí ju wákàtí mẹ́rinlélógún lọ nínú ọjọ́? Gbogbo ǹkan di ìkàyà fún ọ nítorí oye àwọn iṣẹ́-àkànṣe tó yẹ kí o ṣe? Ṣe ó sú ọ pé gbogbo ìgbà ni ó maá ń rẹ̀tí o kò sì ní àkókò tó láti lò nínú Ọrọ̀-Ọlọ́run àti pẹlú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ? Eléyìí lè jẹ́ ìdojúkọ tí ó wọ́pọ̀ jù l'áyé. Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé Bíbélì fún wa ní àwọn ìlànà tí a lè lò láti ṣ'èkáwọ́ àkókò wa dáadáa. Ètò-ẹ̀kọ́ yìí yíó fẹ àwọn Ìwé-mímọ́ wọ̀nyí l'ójú yíó sì fún ọ ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó wúlò fún bí wàá ṣe lo àwọn àsìkò tó kù l'áyé rẹ dáadáa!
More