Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runÀpẹrẹ
Pinnu Ohun Tó Ṣe Kókó
Màrtá kò f'ara 're lọ nínú ìwáásù wa lórí àyọkà yìí ní Lúùkù 10. Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé, gbogbo wa ni Màrtá láti ìgbà dé ìgbà, à ń tiraka láti mọ̀ ní pàtó àwọn iṣẹ́ wo ló ṣe kókó jù ní déédéé àkókò kan. Ó di dandan kí ẹnìkan d'áná alẹ́, ó sì dámi lójú gbangba pé Jésù mọ rírì ìkónimọ̀ra Màrtá. Kìí ṣe pé dídáná alẹ̀ kò ṣe pàtàkì. Jésù kàn sọọ́ di mímọ̀ pé kìí ṣe ohun ló ṣe kókó jùlọ nínú ohun tí Màrtá tàbì arábìnrin rẹ̀ Màrìà lè máa ṣe lọ́wọ́ nígbà yẹn. Ohun tó ṣe kókó jù nígbá yẹn ni pé kí á kọ́ wọn lábẹ́ ẹsẹ̀ Jésù.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ríi lánàá, gbígbá gbogbo ìfarajì, iṣẹ́, àti iṣe-àkànṣe jọ jẹ́ ìgbésẹ̀ tó ṣe kókó nínú ṣíṣe ìkáwọ́ àkókò ẹni. Ṣùgbọ́n lọ́gán tí o bá ti gbá gbogbo ìfarajì rẹ jọ, àsìkò tó láti pinnu èyí tó ṣe kókó jù nínú gbogbo àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rẹ. Ìlànà yìí pè fún níní òye kedere ohun tí o gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ń pè ọ́ sí ní àkókò yìí ní ìgbé-ayé àti iṣẹ́ rẹ. Pẹ̀lú gbogbo ìfojúsọ́nà ọjọ́ ọla àtì àlékè àṣeyọrí yìí l'ọ́kàn, bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ, “Kíni ohun kan náà tó jẹ́ pé tí ń bá mú ṣe tán, yíó jẹ́ kí gbogbo ǹkan yòókù nínú àkànṣe iṣẹ́ yìí rọrùn tí yíó sì s'èso 're?” Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ní ohun tó ṣe kókó jùlọ tí o ní láti gbájú mọ́. Dá gbogbo ohun yòókù dúró tí oó fi parí ohun kan yìí. Lẹyìn náà, tún àwọn ìgbésẹ̀ yìí gbé léraléra.
Nígbàtí mò ń kọ ìwé tí mo kọ kẹ́hìn, Called to Create, bí àwọn ohun tí mo ní láti ṣe kí ìwé náà tó dé orí igbá ṣè pọ̀ tó, da jìnnìjìnnì bo ọkàn mi. Mo ní láti gba agbaṣẹ́ṣe, ta atẹ̀wé, ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, kọ ọ̀rọ̀ bíi ọ̀kẹ́ méjì àbọ̀, wá ọ̀nà láti polongo ìwé náà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ̀n ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe náà, mo mọ̀ pé bí mi ò bá lè rí agbaṣẹ́ṣe tí yíó bá mi ṣé, kò sí ohun mìrán nínú iṣẹ́ náà tí yíó ní ìtumọ̀. Gbígba agbaṣẹ́ṣe ló ṣe kókó jù fún mi. Nítorí náà, mo dá gbogbo ohun yòókù nínú àkànṣe iṣẹ́ náà dúró títí mo fi rí agbaṣẹ́ṣe tí yíó bá mi ṣé.
Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ní ìgbàkúùgbà, àwọn ohun tàbí iṣẹ́ àkànṣe péréte ló ṣe kókó. Jẹ́ kí ó mọ́ ọ lára láti máa dá àwọn ohun tó ṣe kókó bíi méjì sí mẹ́ta mọ̀ yàtọ̀ láti gbájú mọ́ wọn títí wàá fi paríi wọn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ṣé ó t'ojú sú ọ pé kò sí ju wákàtí mẹ́rinlélógún lọ nínú ọjọ́? Gbogbo ǹkan di ìkàyà fún ọ nítorí oye àwọn iṣẹ́-àkànṣe tó yẹ kí o ṣe? Ṣe ó sú ọ pé gbogbo ìgbà ni ó maá ń rẹ̀tí o kò sì ní àkókò tó láti lò nínú Ọrọ̀-Ọlọ́run àti pẹlú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ? Eléyìí lè jẹ́ ìdojúkọ tí ó wọ́pọ̀ jù l'áyé. Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé Bíbélì fún wa ní àwọn ìlànà tí a lè lò láti ṣ'èkáwọ́ àkókò wa dáadáa. Ètò-ẹ̀kọ́ yìí yíó fẹ àwọn Ìwé-mímọ́ wọ̀nyí l'ójú yíó sì fún ọ ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó wúlò fún bí wàá ṣe lo àwọn àsìkò tó kù l'áyé rẹ dáadáa!
More