1 PeteruÀpẹrẹ

1 Peteru

Ọjọ́ 5 nínú 5

Peteru parí ìwé rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìgbaniníyànjú méjì. Àkọ́ka ní ti àwọn aṣaájú, tàbí àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ tí wan tàn ká ilẹ̀ Asia. Adarí ìjọ ni Peteru náà, ó sì ti jìyà púpọ̀fún un. Ṣùgbọ́n Peteru gba àwọn aṣaájú níyàjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí ó sọ fún àwọn ọmọ ìjọ wí pé ìpọ́njú ń yọrí sí ògo. Peteru ní kí àwọn asaájú yìí tọ́jú àgúntàn wọn pẹ̀lú ìfẹ́ láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere ìfara-ẹnjìn àti òdodo ìgbé ayé Jesu láìwo ohun tí yóó ná wọn. Jesu ti fi lélẹ̀ pé ìfẹ́ láti darí àti láti se nǹkan nínú ìpọ́njú jẹ́ ọ̀nà sí ògo

Ìpọ́njú àti ìwà àwọn asaájú ìjọ tí wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí i Olùṣọ́-àgùntàn ran Peteru lọ́wọ́ nínú ìrírí rẹ̀ pllú Jesu. Peteru kọ́kọ́ tako Jesu nígbà tí Jesu sọ pé o di dandan kí ó rí ìpọ́njú. Jesu sì pè e ní Sàtánì níto rí pé kíkọ ìpọ́njú jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yì ìgbà tí Peteru sẹ́ Jesu lẹ́ẹ̀mẹta, Jesu pè ésí ọ̀dọ̀ àwọn Olórí ìjọ láti tún ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ lẹ́ẹ̀mẹta,“Tọ́jú àgúntàn mi,”. Ọ̀rọ̀ ìyànjú Peteru sí àwọn Olóri ìjọ láti tọ́jú àgùntàn Ọlọ́run nínú ìjọ, àti ìfẹ́ láti jìyà wá láti inú ìkùnà rẹ̀ gẹ́gẹ́ọmọ ẹ̀yìn Jesu.

Àkóko yìí tún ń sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú Peteru fún àwọn ọ̀dọ́ inú ìjọ Ọlọ́run. Àìgbọràn Peteru nípa ìpọ́njú ni ó jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ̀ẹ́ sílẹ̀ lógán, ó ń fi èyí rán àwọn ọ̀dọ́ étí pé “Ọlọ́run kọ ìgbéraga ṣùgbọ́n ó fi ìbùkún fún onírẹ̀lẹ̀. Peteru wá ń fi yé àwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ láti di asaájú pé, nígbà ti òun tẹríba, tí òun sì jọ̀wọ́ ara òun pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ fún Jesu ni òun tó ní oore ọ̀fẹ́ sí ipò àṣẹ. Ìrẹ̀lẹ̀ àti ìpọ́njú kìí gbé. Ọwọ́ Ọlọ́run tí ó lágbára fa Jesu jáde láti inú iṣà òkú, ó dájú pé ọwọ́ náà yóó sàànú fún gbogbo onígbàgbọ́ tí ó wà nínú ìbẹ̀rù àti ìṣenúnibíni.

Peteru kìlọ̀ pé ìrẹ̀lẹ̀ kìí se ẹ̀gọ̀. Èsù ń fi inúnibíni àti irọ́ sọdẹ wọn, ó sí ń sọ fún wọ́n pé o se é se láti yẹra fún ìpọ́njú. Peteru kò sì fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ se irú àsìṣe yìí. Ijọ yìí gbọ́dọ̀ kọ ìwà búburúníwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti ní ìmọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú kò le má rí ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ògo ayérayé yóò wọn yóó dé láìpẹ́

Peteru pári ìwé rẹ̀ nígbà tí ó sọ pé òun ń kọ ìwé náà láti Babyloni. Babylon jẹ́ ìlú ìgbàanìnínú ìtàn Israel. Ní ìgbà ayé Peteru ni wọ́n pa ìlú náà run ṣùgbọ́n ó ti dí ìrúfẹ́ àwùjọ tí ń tako àwọn ènìyàn Ọlọ́run báyìí. Èyí jẹ́ ìránilétí ìkẹ́yin pé àwọn onígbàgba wọ̀nyí yóó máa jẹ́ ẹrú láìwo ipò wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú. Àjìjì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu máa ń sáábà jẹ́, wọ́n a sì máa kórira wọn gẹ́gẹ́ bí i àwọn àjìjì mìíràn.

Ìpọ́njú aláìleyẹ̀sílẹ̀ tí a ní nípa ìgbàgbọ wa nínú Jesu kò rọrùn láti gbà, èyí kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn adarí inù ìjọ gbà á. Ṣùgbọọ́n fúm ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu ní àgbáyé àti nípaṣẹ̀ ìtàn, a kò tí ì fún ọ̀kanka wọn ní láti má rí ìpọ́njú. Peteru kò rò pé ayé le wà láìsí ìpọ́njú.Ìpọ́njú nínú ayejẹ́ ìròyìn ayọ̀ torí ó túnmọ̀ sì ògo, ìbùkún iyì. Agbára náà sì tùn jẹ́ ohun tí ohun tí kò se é má ní. Peteru wí pé lẹ́yìn ìgbà tí a bá rí ìpọ́njú fun ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run gbogbo oore ọ̀fẹ́ yóó san-án, yóó fún ọ lágbára, yóó mú ọ dúró sinsin, yóó sì mú ọ wà nínú àgbára ayérayé rẹ̀.

Inúnibíni ìjọba, ti ìdílé, tí ọ̀rẹ́ le fa ìbínú, Ṣùgbọ́n Peteru fẹ́ kí ìdáhùn rẹ̀ jẹ́ èyí tó láyọ̀. Nígba tí wọ́n kojú Peteru, tí wọ́n nàá nítori ìwàásù ìyìnrere Jesu, Inú rẹ̀ dùn pé a ti ka òun yẹ fún ìjìyà orúkọ Jesu.Èyí kìí se nítorí pé Peteru láyà, tàbí pé nínà kò sì bàá lẹ́rẹ̀ (Ràntí pé, ó ṣẹ́ Jesu ) Peterule yọ̀ nítorí pé ìjìyà nítorí orúkọ nínú ẹ̀mí àti ní ojúkorojú so Peteru pọ̀ mọ́ Jesu àti àjíǹde rẹ̀ tó ń bọ̀.

Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí Mímọ́ yóó sí ojú rẹ láti rí Ọlọ́run tí ó jìyà, tí ó sì kú. Ìwọ yóó sì rí Jesu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o fi àjíǹdealáìleyẹ̀sílẹ̀we da wa lójú nígbà tí a bá jìyà pẹ̀lú rẹ̀.

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

1 Peteru

Nípa ìrètí rẹ̀ nínú lẹ́tá tí ó ko sí ìjọ àkọ́kọ́, Peteru gbà wá níyànjú kí a ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbọ́ràn. Ó ní kí á dúró sinsin nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni. Ó ní nítorí ẹ̀dá tí a jẹ́ nínú Jésù, a ní agbára láti gbé ìgbá ayé ìwà mímọ́, a ó sì le ní àfojúsùn ogún ayérayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/