1 PeteruÀpẹrẹ

1 Peteru

Ọjọ́ 2 nínú 5

Peteru bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀ pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀. Àwọn kèfèrí tí wọ́n jẹ́ olùgbọ́ rẹ̀, tí wọ́n kò sí lágbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ ní Ọlọ́run ti yàn báyìí. Àwọn àjèjì yìí ni a ti sọ dọmọ, a sì ti tún wọn bí sí agbo ẹbí Ọlọ́run.Ṣùgbọ́n ìgbàlà ti Jesu fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ yìí pẹ̀lú ìpọ́njú rẹ̀ kò tí ì dé pátápátá. Báyìí, àwọn ti Ọlọ́run yàn ní láti dúró ní oko ẹrú. Èyí ló mú Peteru sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọ́n múra sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Israeli se ń múra láti kúrò ní Egypti lọ sí Orílẹ̀ èdè wọn, wọ́n ní láti múra sílẹ̀ fún ìsòro àti ìpèníjà bí wọ́n bá se ń lọ sí Orílẹ̀ èdè wọn titun. Ní ìwòye Peteru, èyí túmọ̀ sí pé ìhùwà bákan àti dídìrọ̀ mọ́ Jesu gẹ́gẹ́ bí ìrètí. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi ifẹ́ wọn sí ìjọba àtija sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọ́n sì gbé ìwà mímọ́ tí ìjọba ọ̀run bèèrè fún wọ̀

Mímúra tán túmọ̀ sí péàwọn ènìyàn fi ìgbàgbọ́ wọn kíkún sínú gbogbo ìyìn rere tí Jesu yóò mú wá. Bì a ó se múra láti wọ ìjọba ọ̀run ni níní ìgbàgbọ́ nínú Jesu Ọba àti síṣe ìṣe ọmọ ìjọba ọ̀run.

Ṣùgbọ́n ìgbé ayé àjèjì jẹ́ ìgbè ayé ẹrù. Kìí ṣe ìbẹ̀rù ìṣe síṣe ibínibíni tàbí kí a yàtọ̀ (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òdodo ní èyí), ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù mímọ ohun tí yóó ná wa láti mọ̀ nípa ìjọba ọ̀run. Kì í ṣe nípaṣẹ̀ ohun tí kò ni láárí bí i góòlù tàbí wúrà ní a ó fi gba àwọn ènìyàn Ọlọ́run là, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu tí i ṣe iyebíye. Àwọn ará Israeli jáde kúrò ní Egypti nígbà tí wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí a fi ẹ̀jẹ̀ Jesu kùn. Ní ojú ọ̀nà wọn lọ síibùgbé titun, Àwọn ara Júù àti àwọn Farisí ní láti gba abẹ́ òjìji àgbélébùú tó kún fún ẹ̀jẹ̀. A pé àwọn ọmo ìjọba ọ̀run ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn bí i ti Olùgbàlà wọn, kí wọ́n sì kọ ìwà búburú tí ó kan Jesu mọ́ àgbélébùú. Gbogbo onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ kọ ìwà àtijọ́ wọn sílẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù pé ó le tàbùkù ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn, kí wọ́n sì máa wóye ìrètí mìíràn.

Ọlọ́run ti mọ̀ láti ìgbà pípẹ́ pé Òun yóò kù láti gba ènìyàn rẹ̀ là. Nínú Jesu ni a ti mọ̀ pé Ọlọ́run ti yẹ àkókò ayérayé, tí ó sì fi ara rẹ̀ rúbọ fún àǹfààní ènìyàn. Èyí ni ìrètí wa, ìdí nìyí tí a fi ń bẹ̀rù. Ìdí nìyí tí a fi gbọ́dọ̀ ṣe bí i ọmọ ìjọba ọ̀run ní bi a se ń retí bíbọ̀ rẹ̀.

Wíwà ní oko ẹrú gẹ́gẹ́ bí àjèjì kò rọrùn. Yíyani sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ìfara-ẹni-jìn fún Jesu àti jù bẹ́ ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n Peteru sọ síwájú sí i pé a ti di àtúnbí nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí kìí. Ó kà láti inú ìwé WòlíìIsaiah tí ó sọ báyìí pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóó tàn ká ju Orílẹ̀ èdè alágbára àkókò yí lọ, èyí tí i ṣe Babyloni. Ó sì ti rí bẹ́ẹ̀ nípaṣẹ̀ Jesu! Babylon tàbí Romu kó le dá Ọlọ́run dúró láti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Láti ìgbà láéláé ni Ọlọ́run ti gba ènìyàn là nípaṣẹ̀ yíyan ọmọ rẹ̀,ọ̀rọ̀ náà sọ ẹran ara di ọbathe Word made Flesh, as King.

Kò sí Orílẹ̀ èdè tó le dá Ọlọ́run dúró. Nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ọmọ rẹ̀, àwa tí di ohun àìdíbẹ̀jẹ́ tí kìí kú. Ìrètí pé a ó wà papọ̀ nínú ìjọba ayérayé yẹ kí ó fún wa ní ìwúrí láti hùwà bí ẹni pé ìjọba náà ti dé.

Peteru fi yé wa pé a gbọ́dọ̀ se bí ọmọ ọmú tí ó ń sàárò wàrà nínú ìyípadà nǹkan. Wàrá ni ohun tí ń mu ọmọ dàgbà. Peteru sí wí pé bí ọmọ Ọlọ́run se ń dàgbà gẹ́gẹ́ bi ọmọ ní nípa títẹ̀síwájù láti máa bèèrè fún ìròyìn ayọ̀ ohun tí Jesu se fún wa. Jesu dàbí iya tí ń fún ọmọ lọ́mú, ‘tí ń tẹ̀síwájú láti máa fi ara rẹ̀ fún ọmọ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọwọ́, a ń dágbà nígbà tí a bá ń fi gbogbo ìgbà lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó gbà wá, tí ó sì ń pèṣè fún wa

Gbogbo ìgbà ni a máa ń ro bí a se fi àwọn ìwà àtijọ́ wa sílẹ̀, tí a kọ ẹ̀ṣẹ̀, tí a sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde wa tó ń bọ̀ nípa fífún ojú pọ̀ àti ìgbìyànjú gidi. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé dídàgbà nínú Ọlọ́run jẹ́ ohun tí kò le rárá, ó dábi mímu omi, jíjẹun, kí a sí nígbàgbọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run ti se fún wa nínú Jesu.

Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sí yín lójú láti rí Ọlọ́run tí o yàn wà láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ìwọ yóó sì rí Jesu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó gbà wá là, tí ó sì sọ wá di mímọ́.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

1 Peteru

Nípa ìrètí rẹ̀ nínú lẹ́tá tí ó ko sí ìjọ àkọ́kọ́, Peteru gbà wá níyànjú kí a ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbọ́ràn. Ó ní kí á dúró sinsin nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni. Ó ní nítorí ẹ̀dá tí a jẹ́ nínú Jésù, a ní agbára láti gbé ìgbá ayé ìwà mímọ́, a ó sì le ní àfojúsùn ogún ayérayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/