1 PeteruÀpẹrẹ

1 Peteru

Ọjọ́ 3 nínú 5

Nínú ìwé ExoduỌlọ́run sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé bí wọ́n bá gbà á gbọ́, wọn yóó jẹ́ ohun ìsúra rẹ̀, bẹ́ ẹ̀ náà ni wọn yóò tún jẹ́ ìjọba àwọn àlùfáà tí a yà sọ́tọ̀ làti bù kún àgbáyé. Peteru dáhùn ìpè Ọlọ́run àtọjọ́pípẹ́, ó sì sàmúlò rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jesu, kìí se fún Israel nìkan. Peteru fi kún un pé a kìí ṣeìran tí a yàn àti olú àlùfáà nìkan, ṣùgbọ́n a jẹ́ òkuta ìyè tí a fi kọ́ tẹmpìlì titun. Ní Israeli, tẹmpìlìjẹ́ ibi tí àwọn ènìyàn ti ń rúbọ, tí wọ́n sì ti ń bá Ọlọ́run pàdé. Ṣùgbọ́n báyìí tẹmpìlì jẹ́ ibùdó nínú ẹ̀mí tí a yà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Israel, bí àwọn àlùfáà titun, láti jọ̀wọ́ ayé wa àti ìṣe wa fún ìbùkún àwọn mìíràn.

Tẹ́mpìlì àgbáyé tí ó ń gbilẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ láti ọwọ́ Jesu. Òun ni àpata ìpìlẹ̀. Láìsí ìfara ẹni sílẹ̀ àti àpẹẹrẹ, èrò titun Ọlọ́run láti bùkún àgbáyé nípaṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n fọ́nká. Peteru ní àpata ìyè tí ó ní àkóónú ibi ìpàdé títun pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó ń pèṣè ìbùkún nígbà tí a bá ń gbé ìgbé ayé ìwà mímọ̀

Ṣùgbọ́n tẹ́mpìlì ìyè tí à ń kọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run yìí jẹ́ ohun tí a ń kọ́ nípaṣẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀. Jesu ni Tẹ́mpìlì wa, Àlùfáà ti se ìrúbọ gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, wọ́n sì pa á. Gẹ́gẹ́ bí i ìran tí ayàn, àti olú àlùfáà Jesu, a ó rí ìpọ́njú nínú ẹ̀sìn yìí. Ṣùgbọ́n bí ènìyàn Ọlọ́run tó se iyebíye bá ti wà nínú ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn yóò kórira wa torí pé à ń sọ nípa rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn. Torí náà, láti jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run, èyí tumọ̀ sí jíjẹ́ ẹrú àti àjèjì. Láti jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí jíjẹ́ ẹni ẹ̀kọ̀ fún aráyé gẹ́gẹ́ bí àpata ìyè wá se jẹ́ ẹni ẹ̀kọ̀

Gẹ́gẹ́ bí ó se yẹ kó rí. Àwọn ọmo ìjọba ọ̀run kọ ìfẹ́ orílẹ̀ èdè ìgbàanì ti ayé yìí. Èyí yóò sì mú inúnibíni àti ikú wá, Jesu fi yé wa pé kí á gbé ìgbé ayé ọmọ ìjọba ọ̀run yóó mú ìyè wá fún wa látiinú ikú jú kí a gbé ìgbéayé tiwa.

Peteru wá fún wọn ní àpẹẹrẹ mẹ́ta lórí bí òdodo inú ẹ̀mí yìí se máa ń jẹyọ ní ojúkorojú. Àpẹẹrẹ tí ó lò ni tí Kristẹ́nì tí ó ní ìdojúkọ pẹ̀lú ìjọba Romu,ẹrú tí i se onígbàgbọ́ àti ọ̀gá rẹ̀ aláìgbàgbọ́ ní àṣálẹ́ àti ìyàwó rẹ̀ tí i se onígbàgbọ́ tó fi ọkọ rẹ̀ tí i se kèfèrí sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí i àlùfáà, ọmọ tẹ́mpìlììjọba ọ̀run, wọ́n jẹ́ ẹrú àti àjèjì ní Orílẹ̀ èdè wọn, ní ibiiṣẹ́ wọn àti nínú ìgbéyàwó wọn. Peteru mọ̀ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóó sẹ̀sín, yóó jẹ́ rora, wọn yóó sì yà wọ́n sọ́tọṢùgbọ́n Peteru ní ìgbàgbọ́ pé ìgbé aye ìfara-ẹnijìn àwọn àyànfẹ́ titun Ọlọ́run yóó bùkún àgbáyé.

Ìjìyà àti ìkọ̀sílẹ̀ Jesu yọrí sí àjíǹde àti ìgbàlà wa. Ìjìyà Jesu gẹ́gẹ́ bí i àlùfáà tẹ́mpìlì àti ọmọ Ọlọ́run tí i se iyebíyetúmọ̀ sí pé a bùkún gbogbo àgbáyé. Peteru mọ̀ pé ìgbéyàwó yóò jí dìde, àwọn olórí yóó ronúpìwàdà sí àwọn ẹrú wọn, ìjọba yóó wárí nígbà tí àwọn àyànfẹ́ tí a kólẹ́rú bá kọ̀ láti se bí i ọmọ ayé yìí dípò kí wọ́n tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jesu.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu gbé gẹ́gẹ́ bí i ìránṣẹ́ ní Romu, ó sì kú nípa ìfisùn àwọn Farisí, ó jí dìde nínú òkú torí pé ó gbọ́ran sí Ọlọ́run nínú ìgbé ayé rẹ̀, ó dín agbára àwọn ará Romu kù, ó sì mú àdínkù bá èké àwọn Farisi. Nígbà tí Jesu ń jìyà, tí wọ́n ń nàá bí i ẹrú, kò torí èyí kórira àwọn tí wọ́n ń se inúnibíni sí i, se ni ó tún dáríjìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí i àlùfáà. Nípa òdodo rẹ̀ ní a sọ àwọn ẹrú di mímọ́, tí a sì wò wọ́n sàn nínú àìléra wọ́n. Gẹ́gẹ́ bí Jesu se kú láti gbàlà, láti sọ àyànfẹ́ di mímọ́, àwọn aya tí ó gbàgbọ́ le jèrè ọkán ọkọ wọn nípa sùúrù àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.

Jesu ni àpẹẹrẹ wa. Jesu sọ wí pé nígbà tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run bá fínúfíndù hùwà bí àwọn ẹrú tí a yàn, ọmọ aládé, àwọn ènìyàn tí ó se iyebíye, a jẹ́ wí pé Ọlọ́run ti bùkún àgbáyé níyẹn, nígbà ti a ti ra àwọn aṣenínibíni padè, a ó dàgbà sókè láti inú ìrẹ̀sílẹ̀ wa

Kí Ẹ̀mí Mímọ́ si yín lójú láti rí Ọlọ́run tí ó se wá ní tẹ́mpìlì ìyè rẹ̀. Ìwọ yóó sì rí ìrora Jesu, ẹ ó sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí i ìrètí tí a ní, àwa àti àwọn tí ó wà ní àyíká wa yóó sì le yípadá.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

1 Peteru

Nípa ìrètí rẹ̀ nínú lẹ́tá tí ó ko sí ìjọ àkọ́kọ́, Peteru gbà wá níyànjú kí a ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbọ́ràn. Ó ní kí á dúró sinsin nínú ìgbàgbọ́ nígbà tí a bá ń kojú àdánwò àti inúnibíni. Ó ní nítorí ẹ̀dá tí a jẹ́ nínú Jésù, a ní agbára láti gbé ìgbá ayé ìwà mímọ́, a ó sì le ní àfojúsùn ogún ayérayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/